Nínú ọ̀rọ̀ màmá wa Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá Ààfin) tí wọ́n bá àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá sọ láìpẹ́ yí, màmá wípé, ojúṣe gbogbo I.Y.P ti D.R.Y ni làti ríi dájú pé ìpìlẹ̀ kẹta yí dúró.
I.Y.P ní láti ṣe iṣẹ́ gidi. Kí ó má ṣe sí I.Y.P tí wọ́n máa fi ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn, ìdájọ́ tó máa gbà yóò ga ju àjòjì lọ. Ìdí ni wípé, Gbogbo I.Y.P ni aṣojú ìran wa, ṣé ó wá dára kí a máa ṣe ohun tó lè ta ẹrẹ̀ bá ìran Yorùbá?
Ẹni tí a bá fún ní púpọ̀, púpọ̀ náà ni a ń retí lọ́dọ̀ rẹ̀, tí a bá ń sọ pé èyí I.Y.P, ìyẹn I.Y.P nítorí pé a fẹ́ kí a máa ṣe dáadáa ni, a fẹ́ kí a jẹ́ àwòkọ́ọ̀ṣe rere ni, nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi s’ọ́kàn pé àwa I.Y.P gan-an ni a ní iṣẹ́ láti ṣe láti ríi dájú pé ìpìlẹ̀ kẹta yí dúró títí láé, kò gbọ́dọ̀ mì, kò sì gbọ́dọ̀ wó.
Kò sí ẹni tó máa bá wa ṣé, àwa náà ni a máa ṣe fúnra wa. Àwa ni a ní láti dáàbò bo ohun tí Ọlọ́run ṣe fún wa, a nílò láti ṣọ́ra gidi, kí a máa rántí àwọn ohun tó bi ìpìlẹ̀ ìkíni àti ìkejì wó, kí a ríi dájú pé a ò gbà ìgbàkugbà láàyè rárá.
Nítorí náà, tí I.Y.P bá ti fi sọ̀kan pé, ohun tó wà lọ́wọ́ òun yí, òun gbọ́dọ̀ dáàbò bó gidi, kí ó lè fi lé àwọn ọmọ tó ń bọ̀ lọ́wọ́, tí àwọn tó ń bọ̀ náà á tún lè jẹ àǹfààní rẹ̀ ní ìrọ̀rùn, bí yóò ṣe máa tẹ̀síwájú nìyẹn,tí kò ní sí ìnira fún ẹnikẹ́ni.
Fún ìdí èyí, tí a bá jẹ́ I.Y.P kí a ti mọ̀ pé aṣojú ìran wa ni a jẹ́, tí a bá ń gbà àwọn àǹfààní tó pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y), kí a ti mọ̀ pé àwa náà ní ojúṣe púpọ̀ láti ṣe fún ìgbéga àti ìtẹ̀síwájú orílẹ̀ èdè wa.