Ṣébí Yorùbá ló sọ pé ibi tí a bá ti pè ní Orí, a kìí fi ibẹ̀ tẹ’lẹ̀; ṣùgbọ́n, báyi, ó wá ṣe’ni láanú o, pé, àwọn kan ní ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n ti di ẹni àbùkù, pátápátá, látàrí pé, bí Ọmọ Yorùbá ṣe gbé wọn gẹ-gẹ-gẹ, wọ́n fún’ra wọn sọ ara wọn di ẹni àbùkù, ẹni erùpẹ̀, ẹni orí-ààtàn, pátápátá.
Nígbàtí wọ́n sì ti sọ ara wọn di ẹni orí-ààtàn; tí ọmọ Yorùbá sì ti gbìyànjú, títíítí, pé kí á fọ̀wọ́n mọ́, kí á dá wọn padà sí ipò ẹ̀yẹ, ṣùgbọ́n tí wọ́n sọ pé orí-àwọn kọ ẹ̀yẹ àti iyì, àti pé ẹrọ̀fọ̀ oko-amúnisín ti òyìnbó, àti ti àwọn wèrè Fulani, ọkọ-màlúù, ni àwọn yọ̀nda gbogbo ayé àwọn fún, níbẹ̀ ni àwa ọmọ-íbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ti padà lẹ́yìn wọn o, tí a sì ti sọ pé kò sí nkan-kan, láyé, tó njẹ “ỌBA” ní ilẹ̀ Yorùbá! Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn tó pe’ra wọn ní “ọba” ni a nsọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
Àwọn tó pera wọn ní ọba yí, láti ìgbà tó ti pẹ́, ni wọ́n ṣe okùnfà ìkónilẹ́rú tí àjèjì fi rí ọmọ Yorùbá kó lẹ́rú, torí pé àwọn ọba náà, fúnra wọn, nkó àwọn ènìyàn wọn ní ẹrú, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ta àwọn ènìyàn wọn s’oko ẹrú òyìnbó pàápàá.
Tí a bá sọ pé ayé àtijọ́ nìwọ̀nyẹn, t’òde-òní, kí ó tó di pé ọmọ-ìbílẹ̀-Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) kúrò nínú Nàìjíríà, kò yàtọ̀ náa-. A tún kúrò nínú Nàìjíríà tán, àwọn aṣiwèrè tó perawọn l’Ọba yíì náà ni wọ́n tún nṣoríburukú, tí wọn ò gbárùkù ti òminira wa, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé kìkìdá àbọ̀dè ni wọ́n ngbà fún ọmọ-Yorùbá. Gẹ́gẹ́bí Ìyá-Ìran Yorùbá, Ìránṣẹ́ Olódùmarè, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣe sọ, nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá àwa ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá sọ ní àìpẹ́ yí, a gbọ́ pé ẹbọ àti ètùtù ni ẹ tún nfi oríburúkú yín ṣe kiri, torí pé ẹ ò fẹ́ kí ọmọ Yorùbá ó rí ògo wa lò. Ìyá wa ti fi ohùn ránṣẹ́ sí yín o, ẹ̀yin olófo tí ẹ npe’ra yín ní ọba wọ̀nyí: gbogbo ẹbọ àti ètùtù yín, ó di iná tó máa jó yín run, pátápátá. Olódùmarè ti kọ ẹ̀yìn sí yín; ṣé ẹ ò rína láti mọ èyí ni?
Ó dàbí ẹni pé rárárárá ni ẹ ò tilẹ̀ ní ojú: torí, tí ẹ bá ní ojú ni, tí ẹ sì ní ọpọlọ, ó yẹ kó ti hàn sí yín kedere, pé, àsìkò ti tó, láti ṣe “ó dàbọ̀” sí àwọn ibi tí ẹ jóko sí wọ̀nyẹn, torí, gẹ́gẹ́bí Ìyá-Ìran-Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣe sọ, ẹ ò fi òtítọ́ jóko sí’bẹ̀.
Ṣé ojú kò tì yín ni? Àbí ẹ-ẹ̀ kì nṣe Yorùbá? Tí ojú kò bá tì yín, ojú ti àwa ọmọ Yorùbá òdodo; kí ó wá jẹ́ pé, láti ìgbà ayé àwọn baba yín tí wọ́n ta ọmọ Yorùbá sí oko-ẹrú, ẹ̀yin náà ti wá bá tiyín dé bi pé, fún’ra’ra yín ni ẹ gbé’ra yín fún màlúù-Fulani lọ́wọ́! Ẹ di ìyàwó-Fulani, àbí? Ibi tí àwọn ọkọ yín, Fulani, bá ti ní kí ẹ yà sí fún òun, ni ẹ máa nyà sí?! Bẹ́ẹ̀ ni Fulani mpè yín rán-ní’ṣẹ́; bẹ́ẹ̀ náà ni daran-daran Fulani, pàápàá, nyan-fanda, jáde-wọlé, ní ibi tí ẹ̀yin pè ní Ààfin àwọn babanlá-baba yín! Háà! Ẹ ṣe tán, ẹ́ tún nfi àwọn Fulani sórí oyè ní Ilẹ̀ Yorùbá! Ó mà ṣe ò!
Gbogbo bí ẹ ṣe nṣe ní ẹnu ọjọ́ mẹ́ta yí, fihàn gbangba pé ẹ̀yin wọ̀nyí, olórí-burúkú, gbáà, ni yín: ẹni wọ́n nsọ lókuta pa niyín! Lójú wèrè yín, wọ́n sọ ọmọ Yorùbá di ẹrú, ẹ̀yin nkó agbádá òṣì yín bo’lẹ̀ kiri, ẹ ní ẹ̀yin ni Ọba! Ẹ̀yin ni ọba l’óotọ́?! Àwọn ọba àwọn ọ̀bọ.
Tí àwọn wèrè yín, àwọn bàbá yín tó ndarí yín ní ìlú Nàìjíríà, èyí tí Yorùbá, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ti kúrò nínú rẹ̀ báyi, tí wọ́n bá ti pè yín (torí ẹ̀yin náà kúkú ni ajá wọn ní ilẹ̀ Yorùbá), tí wọ́n bá ti pè yín, láti tún rán-an yín ní iṣẹ́-ikú sí ìpalára ọmọ-Yorùbá, ṣe bí nṣe ni ẹ máa nkáwọ́ yín pọ̀n lẹ́yìn yín láti lọ jẹ́ ìpè wọn ni? Ẹ̀yìn ọ̀dẹ̀, wèrè, akótilétà, t’ó npera rẹ̀ l’Ọba?! Ẹ jẹ́ kí ó yé yín o! Kí ẹ gbọ dáradára, ẹ ò sì rí nkan ṣe si o, ifá ò ní fọ’re fún yín, kó sì ní dá yín l’ohùn, torí ẹ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní àfojú-fò ní ilẹ̀ Yorùbá – ẹ ti da’lẹ̀ Yorùbá, ẹ ti ṣe ohun tí aláì-ní’tìjú nṣe, sí ìran tí ẹ pè ní ti’yín; ìdájọ́-ìgbẹ̀yìn ló dé, báyi, fún yín o! Kò wá sí nkan-kan tó njẹ́ Ọba ní Ilẹ̀ Yorúbá mọ́! Ó tán po!
Ṣé ẹ̀yin ò kúkú mọ̀ pé ó máa lẹ́yìn, nígbàti ẹ fi nṣe oríṣiríṣi ìwà ìtìjú tí ẹ nṣe! Ẹ̀yin jẹ gàba lórí ọmọ Yorùbá, ẹ pera yín l’Ọba! ṣùgbọ́n ọba yín wà fún láti ṣe aṣojú fún apànìyàn Fulani; ẹ̀yin ni wọ́n á rán sí wa: háà! ẹ sọ ara yín di olórí-ẹrú; ṣùgbọ́n, báyi, ẹ ti tẹ́ o! Ẹ kúrò lórí ìtànjẹ tí ẹ dúró sí! Orilẹ̀-Èdè Democratic Republic of the Yoruba ti dúró! A ti di Orílẹ̀-Èdè Aṣèjọba-Ara-Ẹni láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún tí a wà nínú rẹ̀ yí! Ẹ ẹ̀ kúkú bá wa dá si, ní gbogbo ìgbà tí a fi ngbé àwọn ìgbésẹ̀, ó ti lé ní ọdún méjì báyi, àfi kí ẹ máa tadí’nà, ṣùgbọ́n ẹ ò rí ìtadí’nà ṣe mọ́ báyi o! Ó ti ta fún yín, àṣé ẹ̀yin ni ẹ máa jẹ́ ọba ìkẹyìn ní Ìtàn Ìran Yorùbá! Olódùmarè ti kọ̀ yín; òpin ti dé fún yín; kò s’ohun t’ó njẹ́ Ọba mọ́ o, ní ìran Yorùbá.
Ẹ dúró ná?! kí ló kọ lù yín tẹ́lẹ̀-tẹ́lẹ̀, tí ẹ fi nṣe òṣì kiri? Owó tí wọ́n nfún yín ló dí yín lójú, àbí? Ìwà fà-nlétè-ntutọ́ tí ẹ nṣe kiri yẹn ti dùn mọ́ yín, àbí? Ẹ ti tan ara yín jẹ, pé, ẹ̀yin ni ẹ wà ní ipò Olódùmarè ní ilẹ̀ Yorùbá, àbí? Ẹ ṣìí o! Tó bá jẹ́ pé ẹ gbọ́n ni, ẹ̀ bá ti mọ̀, ẹ̀ bá sì ti rán ara yín léti, pé, ní Ilẹ̀ Yorùbá, ará-ìlú máa nsọ fún Ọba k’ó “ṣí’gbá,” nígbàtí ó bá d’ojú ẹ̀! Ẹ̀yin ti gbàgbé ni-ì, ìbá ṣe pé ẹ rántí ni, ẹ bá ti gba ara yín ní àmọ̀ràn, pé kí ẹ máṣe kọjá àyè yín! Ṣùgbọ́n ẹ ti gbà pé Nàìjíríà tí ẹ̀yin ntẹ́ríba fún yẹn, pé ó ga ju Olódùmarè lọ; wọ́n tàn’yín jẹ, ẹ̀yin náà tan ara yín jẹ, ẹ gbàgbé ìṣẹ̀dálẹ̀; ẹ gbàgbé pé nínú òmìnira-ara-wa ni Yorùbá wà kí amúnisìn ó tó dé; bí ẹ tilẹ̀ rántí, ohun tí wọ́n nfún yín jẹ, kí ẹ lè máa da Ìran yín, kò jẹ́ kí ẹ kọ’bi-ara-si! Ẹ gbà pé kò sí nkan tó njẹ́ ìṣẹ̀dálẹ̀ mọ́, àbí bẹ́ẹ̀kọ́? bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ ti rò pé “ayé-ti-dayé-òyìnbó,” àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Tí kìí bá nṣe ìgbéraga yín, ṣé ibi tí ẹ jóko sí kò rán yín létí pé ọmọ-Yorùbá ló yẹ kí ẹ wà fún, kìí ṣe fún Òyìnbó? Ó mà ṣe ò; inkan tó ndààmú yín ọ̀hún ṣe yín títí-tí, nígbàtí ẹ forí-balẹ̀ fún Òyìnbó tán, ẹ tún bẹ̀rẹ̀ sí forí-balẹ̀ fún Fulani! L’óba wá tán fún yín po, tí ayé gbogbo yín bàjẹ́, kalẹ̀.
A ò ṣe àánú yín o! Ti’yín ló bá yín, nínú ìgbéraga àti Àìbìkítà yín; kẹ́-ẹ fọ́l’ojú dé’bi pé ẹ ò mọ̀ pé ẹ̀tọ́ yín ni gẹ́gẹ́bí ọmọ Yorùbá, pé ìyà kò jẹ Yorùbá kankan. Ṣùgbọ́n, kò tilẹ̀ yà wá lẹ́nu, ṣèbí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ yín, iṣẹ́ tí wọ́n fi yín síbẹ̀ fún, tí wọ́n tìtorí ẹ̀ fi’yín sí’bẹ̀, òun náà ni ẹ ti ṣe yẹn! Ó ti wá parí o! Ṣùgbọ́n, èrè gbogbo ibi tí ẹ ti ṣe, ó mbọ̀ lórí yín pátá. Ah! ọmọ Yorùbá kò ṣe-é yàn jẹ-ẹ̀; ọmọ Yorùbá kò sì ṣe-é ṣe ìwà-ìkà sí! Ìkà ni yín; bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀dájú pátápátá gbáà sì niyín. Aláìmòye ni yín, dàdàndatọ́ t’ó nṣe gọ̀ṣú-gọ̀ṣú kiri lẹ́yìn Fulani! Kí lẹ fi wá yàtọ̀ sí màlúù o? ẹ sọ fún wa. Ẹ̀yin kan yíì náà ni àwọn Fulani máà nfà mọ́ra, tí wọ́n bá ti fẹ́ máa da ẹran wọ inú ìgbèríko wa gbogbo, ẹ̀yin náà ni ẹ máa sọ ṣé wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti lọ síbẹ̀, tí ẹ máa sọ pé ṣèbí ọmọ Nàìjíríà ni wọ́n? – à! ayé yín kò níí dáa! Tí ó bá ti nyẹyín tẹ́lẹ̀, kò tún yẹ yín mọ́! Ọmọ-Àlè gidi ni ẹ jẹ́! Ọlọ́run ló bá wa rẹ́yìn yín-ì; òun ló sọ pé a máa bọ lọ́wọ́ ìgbèkun-Ọba ní ilẹ̀ Yorùbá, a sì ti bọ́.
Ẹ wá gbọ́ o, gbogbo ọ̀ràn tí ẹ ti dá ní ilẹ̀ Yorùbá, ó máa lẹ́yìn o! Gbogbo ibi tí ẹ ti jẹ Ọmọ Yorùbá máyé, tí ẹ tún pe àwọn Ọ̀gá yín Fulani láti wá jẹ ní’bẹ̀, gbogbo ẹ̀, pátá, ni ẹ máa rí ààbọ̀ ẹ̀ o! Gbogbo ẹ̀ pátá.