Tí kò bá jẹ́ pé Olódùmarè ní ìfẹ́ àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ní, kínni à bá máa wí lónìí, tàbí ibo ni à bá sá gbà fún àwọn ọ̀daràn ọ̀bàyéjẹ́ àgbà òpònú gbogbo tí a kó mọ́’ra nínú ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà yìí? tí wọn ń fi tipátipá jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, tí ó fi wá jẹ́ pé, ṣe ni a kó ẹran pọ̀ mọ́ èrò báyìí.
Ìbá jẹ́ pé, a lè dá wọn mọ̀ ni, ń ṣe ní à bá lọ da àwọn ọ̀dájú ìkà àgbà ìyà náà sínú òkun, kí àwọn ẹja fi wọ́n ṣe ìjẹ, tàbí àjẹ́ ké lánàá ọmọ kú lónìí, tani kò mọ̀ pé ajẹ́ tí ó ké lánàá ló pa ọmọ tí ó kú lónìí jẹ ni bí? Ẹ bèèrè pé kínni ó mú gbogbo àsamọ̀ ọ̀rọ̀ yí wá?
A rí fọ́nrán kan ní orí ẹ̀rọ ayélujára tí ó gbé ọ̀rọ̀ ìwé ìpeni sí àlàyé ti àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Èkó kọ si Sanwó olú tí ó jẹ́ aṣojú àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí wọn ń fi tipátipá jẹ́ gàba ní orílẹ̀ àwa ọmọ Olómìnira ní ìlú Èkó, pé kí ó wá ṣe àlàyé bí owó ọgọ́run milionu owó dọ́là tí ìjọba àná ní ìlú Èkó gbà lọ́wọ́ Dangote fún ilẹ̀ ilé-iṣẹ́ ìfọ epo bentiróólù tí ó rà ṣe jẹ́.
Ìdí òwe tí mo pa mà nìyẹn o, à fi bí a ṣe gbọ́ pé, Prince Adelani tí ó bu ọwọ́ lu ìwé náà mà tí gba èkuru jẹ ní ọwọ́ ẹbọra o ní ọjọ́ kejì oṣù Ògún tí a wà nínú rẹ̀ yìí.
Hun un! kàyéfì ńlá mà ni èyí jẹ́ o. Ṣé ó dìgbà tí ẹ bá pa gbogbo àwọn ológo tán ni ẹ máa tó fi ayé sí’lẹ̀ ni? àbí kí ló dé tí ìrìn ẹsẹ̀ yín kò yí padà a?
Ohun tí ẹ mọ̀ kò ju kí ẹ máa fi irọ́ yí irọ́ lọ, ta gan an ni a wá ṣẹ̀ báyìí náà?
Ṣùgbọ́n ohun tí ó dá wa lójú ni pé, àṣírí ẹyin ọ̀bàyéjẹ́ wọ̀nyí kò lè bò lọ títí.
Èrè Olọ́run ń bẹ, láti san án fún oníkálukú gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ṣe rí. Ẹ máa ṣé lọ, ẹ máa bá Ọlọ́run pàdé ní ẹsẹ kògb’èjì.
Ẹyin ọ̀dọ́ Indigenous Yorùbá People (I.Y.P.), etí yín mélòó? ẹ tètè fà etí yín, kí ẹ fi eré gé e kúrò níbi tí àwọn apànìyàn wọ̀nyí ti ń lò yín ṣe iṣẹ́ ibi wọn, kí ẹ kọjá síbi tí ayé yín ti máa gba àtúnṣe tí ẹ sì máa rí ògo yín lò, nítorí òjò tí ó rọ̀ ló kó ẹyẹlé pọ̀ m’ádìyẹ.
Àyè irú ìwà ìkà báyìí kò lè wá’yé ní orílè-èdè Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y.), nítorí gbogbo ìdáwọ́lé wa ní o ma máa wà ní àkọsílẹ̀ láì ní máa fi igbá kan bọ ọ̀kan nínú.
Kí a dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyá wa, Modupeola Onitiri-Abiola, (MOA) fún àgbéka’lẹ̀ tí ó dára tí màmá gbé wá fún wa.