Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbáa (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ti di orílẹ̀ èdè, gbogbo àgbáyé ló sì ti mọ̀, àti pé orílẹ̀ èdè aṣàkóso-ara-ẹni ni orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá, D.R.Y. 

Oríṣiríṣi àǹfààní ló wà fún àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) nípasẹ̀ àlàkalẹ̀ ètò tí

Olódùmarè gbé fún Màmá wa, Modupẹọla Onitiri-Abiọla (Olóyè Ìyá-Ààfin)

Iṣẹ́ yóò pọ̀ yanturu fún gbogbo àwọn tó ń wá iṣẹ́, àti pé kò ní sí ìrẹ́jẹ, ojúsàájú tàbí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y. A ò nílò láti mọ ẹnikẹ́ni kí a tó rí iṣẹ́ nítorí pé lórí òtítọ́ àti òdodo ni a gbé ìpìlẹ̀ wa lé.

Ní orílẹ̀-èdè D.R.Y àparò kan kò ga jù kan lọ.

Gẹ́gẹ́bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ wípé, a máa fò ni, a ò ní rìn, a ò sí ní sáré. 

Àkókò tí àwọn ọ̀dọ́ wa yóò rí ògo wọn lò nìyí, ògo wọn yóò sì búyọ. Olódùmarè ti ṣẹ́gun fún wa.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Lẹ́hìn òkùnkùn biribiri, ìmọ́lẹ̀ á tàn