Lára ànfààní orílẹ̀-èdè wa, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, èyí tí a tún mọ̀ sí Yoruba Kingdom, Yoruba Nation, Yoruba Land, àti Yoruba Country; ni Ètò Amúludùn, pàtàkì ní ti Orin Kíkọ.
Orin Kíkọ jẹ́ ohun àtayébáyé ní ilẹ̀ Yorùbá; gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá dẹ̀ ṣe sọ, a máa gbé ọ̀rọ̀ orin-kíkọ lárugẹ; ṣùgbọ́n tí ó wà nínú rẹ̀ ni pé, ètò tàbí àgbékalẹ̀ tàbí ayẹyẹ Orin-Kíkọ èyí tí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá lè ṣe alábaṣiṣẹ́ pẹ̀lú irúfẹ́ ètò náà, ní láti jẹ́ orin ní èdè Yorùbá, tí ó sì máa ní ìgbéga ògo ilẹ̀ Yorùbá, Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ní kókó rẹ̀.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. pín sórí àgbàgbé ti X (Twitter)Ṣé ó kúkú ti pẹ́ tí Màmá ti máa nsọ fún wa pé jíjí ohun ìṣẹ̀dálẹ̀ àti àṣà pẹ̀lú ìṣe Yorùbá dìde, jẹ́ pàtàkì nínú ìṣèjọba Orílẹ̀-Èdè Yorùbá.
Yorùbá ló ni orín; ọ̀tọ̀tọ̀ ni oríṣi orin pín sí ní ilẹ̀ Yorùbá. Ó ní orin tí ó jẹ́ ti Àwọn Ọdẹ, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Orin-Àríyá tún ṣe pàtàkì fún Ìran Yorùbá. Àwa kúkú ni Ìran tí Ó máa nlo gbogbo ànfààní tí a bá ní, láti yin Olódùmarè; bẹ́ẹ̀ náà ni a máa nyẹ́’ni sí lọ́pọ̀lọ́pọ̀ – nígbà ìkómọ, ìṣílé, àti bẹ́ẹ̀ lọ; gbogbo ìgbà ni ọkàn wa ngbé ohùn ọpẹ́ sí Olódùmarè, tí a dẹ̀ tún máa nyẹ́ aláyẹyẹ náà sí; èyí dẹ̀ máa nní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlù lílù, orin kíkọ àti ijó-jíjó tí a fí nṣe ayẹyẹ wọ̀nyí.
Bẹ́ẹ̀ ní a gbádùn kí á jóko sábẹ́ igi tàbí sí ọ̀ọ̀dẹ̀ wa lọ́wọ́ alẹ́, kí àwọn òṣèré olórin ládugbò ó máa dárà pẹ̀lú orin àti ìlù.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbajúgbajà olórin tí àgbáyé mọ̀, tí wọ́n nkọ orin ní èdè Yorùbá, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó m’ọgbọ́n lórí, ẹ̀bun oríṣiríṣi ní ìlù àti ohun-èlò-orin míràn ni ó ti wà ní ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n tí ó dà bí ẹni pé ìlú tó le kí Olódùmarè ó tó kó wa yọ kò jẹ́ kí ẹlòmíràn rónú ọ̀rọ̀ gidi tí ó máa di orin alárinrin, tí ó ṣeé jó ijó Yorùbá, àti bẹ́ẹ̀ lọ.
Bí Màmá wa ṣe máa nsọ, Olódùmarè ṣe wá ní Ẹ̀yà ọ̀tọ̀, Ó sì fi Èdè pín wa yàtọ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ó fi Ijó pín wa, Ó fi oríṣiríṣi nkan pín wa.
Ní kété tí Ìjọba wa bá ti wọ oríkò Ilé-Iṣẹ́ Ìjọba káàkiri Orílẹ̀-Èdè Yorùbá wa yí, ilẹ̀kùn ayọ̀ ati gbé ètò orin lárugẹ ti wà níwájú wa lọ́wọ́lọ́wọ́ nìyẹn, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀ báyi o!