Nínú fọ́nrán kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni a ti rí arábìnrin òyìnbó kan níbi tí ó ti ń ṣe àlàyé wípé ọ̀nà kan gbòógì láti leè mú àwọn ẹ̀yà tí ó ní òye lórí, tí ó sì lágbára jù ní àgbáyé, láti lè tẹrí wọn ba, ni láti yàwọ́n kúrò nínú ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ara wọn, láti fún wọn ní ìwòye míràn yàtọ̀ sí irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an gan.
Fi tipá mú wọn wọ’nú ètò tí yíò máa kọ́ wọn wípé kò dára kí ènìyàn wà gẹ́gẹ́bí ìṣẹ̀dá tirẹ̀, ṣùgbọ́n pé ó ní láti dàbí àwọn ìyókù.
Èyí yóò mú kí wọ́n máa yí ara wọn padà sí bí Olódùmarè kò ṣe dá wọn, wọ́n yóò sì lérò wípé nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò fún wọn ní ìdùnnú.
Ní ìgbékalẹ̀ tí yóò mú kí wọ́n máa fojú sí àwọn ọ̀rọ̀ àti àlàyé tí a ti gbé lé wọn lọ́wọ́ yí. Jẹ́ kí wọ́n máa tẹ̀lé ìgbékalẹ̀ yí láti ọmọ ọdún márùn-ún titi tí wọn yóò fi dàgbà.
Ṣe àyẹ̀wò fún wọn nípa ẹ̀kọ́ irọ́ tí a ń kọ́ wọn yí lóòrè kóòrè, títí tí yóò fi dàbí òtítọ́ lójú wọn. Máa ṣe àlàyé ohun gbogbo fún wọn láti leè má jẹ́ kí wọ́n rí ààyè láti ní ìrònú tiwọn.
Bá wọn wí, kí o sì halẹ̀ mọ́ wọn tí wọ́n bá dábàá ohunkóhun láti tako àwọn aláṣẹ wọn. Máa sọ fún wọn pé àwọn babańlá wọn ṣe ìkà sí ara wọn, kí wọ́n leè máa gbé nínú ìbẹ̀rù kí wọ́n sì máa ro ibi sí ẹlòmíràn.
Sọ fún wọ́n pé ìran wọn kò yàtọ̀ sí ẹranko ìgbẹ́, kí wọ́n má bàá leè ṣe ìwádìí ètò irọ́ tí a ti fi wọ́n sí. Gbé àwọn kan dìde fún wọn gẹ́gẹ́bí àwòkọ́ṣe ẹwà, tí ó sì jẹ́ pé ẹwà pánda, àt’ọwọ́dá ẹwà ni.
Fi àwọn yẹn ṣe àpẹẹrẹ ẹwà tó jẹ́ pípé fún wọn, kí wọ́n má baà ní ìtẹ́lọ́rùn bí Olódùmarè ṣe dá wọn.
Ẹ pèsè ètò lórí ẹ̀rọ ayélujára tí yóò máa jẹ́ kí wọ́n rí ara wọn bí ẹni pàtàkì nípasẹ̀ iye àwọn tó ń tẹ̀lé wọn.
Jẹ́ kí owó jẹ́ àfojúsùn wọn kí wọ́n leè máa tiraka nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n kí ó máṣe rọrùn fún wọn láti rí owó ọ̀ún.
Mú kí àwọn oúnjẹ wọn ó dùn púpọ̀ jù pẹ̀lú ṣúgá àti èròjà olóró, ṣùgbọ́n kí wọ́n ri rà ní owó péréte. Ṣe ìpolongo irú onjẹ bẹ́ẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí ó pọ̀ yanturu kí wọn má baà dẹ́kun àti máa jẹ wọ́n.
Nígbà tí àwọn oúnjẹ wọnyí bá fa àárẹ̀ fún wọn, fún wọn ní oògùn tí yóò mú àmì àìsàn náà pamọ́ lásán, ṣùgbọ́n tí á tún padà wá, kí wọ́n lè máa lo òògùn náà nígbà gbogbo.
Béèrè owó tó pọ̀ lọ́wọ́ wọn ní ilé ìwòsàn.
Ẹ kọ ẹ̀yìn wọn sí ara wọn ní gbogbo ọ̀nà. Bí wọ́n bá tilẹ̀ sopọ̀ ní ọ̀nà kan, kí wọ́n tún pínyà ní ọ̀nà míràn.
Ha! Ọmọ Yorùbá, ẹ wo ibi tí àwọn ìkà ènìyàn yí bá wa dé, ṣùgbọ́n a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè nítorí pé ìran Yorùbá ti bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.
Ṣùgbọ́n àwa ọmọ Indigenous Yorùbá People (IYP) ti Democratic Republic of the Yorùbá (DRY), ẹ jẹ́ kí a kíyèsára gidigidi.