Ẹni tí ó bá sọ pé báwo ni ti Ìran-Yorùbá ṣe jẹ́, kí ẹni náà ó lọ tún inú ara rẹ̀ rò!

Ẹ̀fẹ̀ kọ́ ni a nṣe, àwàdà sì kọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kì nṣe àpárá tàbí ìgbéraga, nígbàtí a bá sọ pé YORÙBÁ NI ÌMỌ́LẸ̀ ÒGO ADÚLÁWỌ̀.

Ṣébí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ pé, ní ọ́jọ́ kéjì, oṣù èrèlé, òjìlé-l’ẹgbẹ̀sán-ọdún ó dín márun, ní amúnisìn ọmọ Gẹ̀ẹ́sì tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ LORD MACAULAY fi ẹnu ara rẹ̀ sọ níwájú àwọn Igbìmọ̀ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, pé àwa aláwọ̀dúdú, àwa ọmọ ilẹ̀ Áfríkà jẹ́ ẹni iyì, ẹni ẹ̀yẹ, tí ó ní ètò-ẹ̀kọ́ tí ó ga ju ti àwọn òyìnbó lọ, àti pé a jẹ́ ènìyàn jànkàn, ẹni-ológo, tí a sì ní ọrọ̀

irúfẹ́ èyí tí òun kò rí rí; bẹ́ẹ̀ náà ni ó sọ pé a jẹ́ ẹni-ẹ̀mí, tí àṣà-àjogúnbá wa sì jẹ́ èyí tí ó lógo ju ohunkóhun tí òun ti rírí. Ó sọ nígbà náà, pàápàá, pé a jẹ́ ẹni tí ó ní ìdánilójú-ara-ẹni, tí a mọ bí a ṣe jẹ́, tí a sì nrìn nínú ògo wa.

Ọ̀RỌ̀ YÍ NI Ó SỌ ní igba ọdún ó dín mọ́kànlá sẹ́yìn báyi. Ọjọ́ ti pẹ́ tí wọ́n ti mọ ọmọ Áfríkà ní ẹni ológo.

Ọgọ́ta-ọdún lẹ́yìn tí ọkùnrin yí sọ̀rọ̀ yí, ni ẹ̀rí tún wà, tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́, pé ìwé-ìròyin kan tí àwọn amúnisìn ntẹ̀ síta lórí bóṣenlọ ní àwọn ibí tí wọ́n tí nṣe iṣẹ́ ìkónilẹ́rú kiri, àti ní Índíà nàà (“THE COLONIES AND INDIA”), èyíinì ní ọ̀rìn-lé-lẹ́gbẹ̀sán ọdún ó lé marún-dín-lógún, èyí tí ó jẹ́ ọ̀kan-dín-l’aádóje ọdún sẹ́yìn báyi, tí ìwé-ìròyìn náà wá kúkú sọ nípa àwa YORÙBA gan-an gan-gan.

Ìwé ìròyìn náa sọ pé tí a bá nsọ̀rọ̀ nípa Áfríkà o, ìran-Yorùbá jẹ́ èyí tí ìṣẹ̀dá-wọn jẹ́ èyí ti ó ga jùlọ ní Áfríkà.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates

Ìròyìn náà sọ pé àwọn arìnrìn-àjò wá sí ilẹ̀ Áfríkà, àti àwọn amí-amúnisìn tí wọ́n nwá nkan tí kìí ṣe tiwọn kiri ní Áfríkà (“explorers”) ni wọ́n sọ ọ̀rọ̀ yí o! ẸNU ARA WỌN NI WỌ́N FI SỌ́!\

Ẹ jẹ́ kí á wá gbé ọ̀rọ̀ méjèèjì yí sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn, kí á lè mọ bí àwa Yorùbá ṣe jẹ́: ọ̀rọ̀ yí kò rújú rárá:

ÀKỌ́KỌ́, wọ́n ní àwa Áfríkà ni a ní ọrọ̀, ògo, ìyì, ìwà-ọmọlúàbí, ìdára-ẹni lójú, àsà-ajogúnbá, ìjẹ́-ẹni-ẹ̀mí, àti èèyàn-jànkàn jùlọ tí òyìnbó-amúnisìn kòì tí rí irúfẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ wa rí, tí ètò-ẹ̀kọ́ àbáláyé wa tún wá lé kenkà, tí ó ju ohunkóhun tí àwọn òyìnbó ní! Macaulay ló sọ eléyí o! Kíní ìtúmọ̀ eléyí? Ìtúmọ̀ rẹ̀ ni pé kò sí ẹlẹ́gbẹ́ ọmọ-Áfríkà ní àgbáyé!

Ìròyìn kéjì tún wá sọ pé, láarín Áfríkà o, ọmọ-Yorùbá kò ní ẹgbẹ́!

Ẹ jọ̀wọ́, kíni gbogbo eléyí túmọ̀ sí o? Ó túmọ̀ sí pé ní gbogbo àgbáyé, k’á máse purọ́, ká sì mú t’ẹ̀gàn kúrò, Ìṣẹ̀dá ọmọ Yorùbá ló ga jù!

Ṣebí Màmá wa, ÌRÁNṢẸ́ OLÓDÙMARÈ sí Ìran Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣì sọ́ fún wa ní àìpẹ́ yí pé, ẹni tí ó bá mọ ìran kankan tí àṣà, èdè àti ògo rẹ̀ dára ju ti ìran Yorùbá, kí ẹni náa ó gbe síta!

Òun ni a ti gbọ́ yẹn o! Ìwé-ìròyìn náà sọ pé ìṣẹ̀dá-ọmọ-Yorùbá ni ó ga jùlọ ní Áfríkà, tí Macaulay náà sì sọ pé òun ò rí ìṣẹ̀dá tí ó ní ògo to bíi ti Áfríkà rí.

Tí àwọn amúnìsìn fúnra wọn bá f’ìdí ẹ mulẹ̀ pé àwọn ò rí irú ògo àti ìṣẹ̀dá iyì, ẹ̀yẹ àti ọrọ̀ tí àwọn rí ní Áfríkà, pé àwọn ò rí irúfẹ́ rẹ̀ rí; tí àwọn amúnisìn yí bákan-náà tún sọ pé láarín Áfríkà o, ìṣẹ̀dá ìran Yorùbá kò ní ẹgbẹ́, ó yẹ kí ó ti yé wa, irúfẹ́ Ìran tí Olódùmarè dá wa, àti ipò tí a wà ní gbogbo àgbáyé.

Ìwé-Ìròyìn náa wá tẹ̀síwájú ní ijọ́ náà lọ́hun, pé, àwa Yorùbá ni a nfún’ra wa hun aṣọ wa, àwa fún’ra wa ni a ngbé irin jáde láti inú irin-rọ̀bì, àwa fún’ra wa ni a nṣe àgbéjáde ọgbọ́n-àtinúdá tí a fi nṣe àwọn oríṣiríṣi ohun tí a nlò, bẹ́ẹ̀ ni àwa fún’ra wa ní àṣà tiwa tí kìí ṣe láti ibòmíràn ni a ti ri!

Paríparì rẹ̀, ó ní àwa Yorùbá jẹ́ ẹni iyì àti ológo nínú ìhùwàsí wa, tí kò fẹ́ ohun ìdọ̀tí, tí kò sí fẹ́ ìgbé-ayé tí kò ní ògo.

Àwa ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ẹ jẹ́ kí á mọ irúfẹ́ ìṣẹ̀dá tí Olódùmarè dá wa, kí á yéé gbé ara wa fún ìdọ̀tí àti ìyà-jíjẹ mọ́; kí á tẹ̀lé Àlàkalẹ̀ tí OLÓDÙMARÈ gbé fún wa, nípasẹ̀ ìyá wa, ìyá ÌRAN YORÙBÁ, Màmá, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal