Màmá Ìran Yorùbá, Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, jẹ́ kó yé àwa ojúlówó Ọmọ-Ìbílẹ̀-Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) wípé a ní láti rọ òjò èpè àti ègún lé gbogbo àwọn àjèjì tí ó wà káàkiri ilẹ̀ Yorùbá, tí wọ́n ti nja’lè ilẹ̀ Yorùbá, tí ojú olè wọn ti wọ àwọn ohun àlùmọ́nì ilẹ̀ tí Olódùmarè fi fún ọmọ-Yorùbá, tí wọ́n npète-pèrò láti jí ọrọ̀ tí Ọlọ́run fún wa, tàbí tí wọ́n ti ńjí látẹ̀yìn wá, tàbí wọ́n ńjí lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi!

Ibikíbi tí ó wù kí àwọn àjèjì wọ̀nyí ti wá láti orígun-mẹ́rẹ̀rin àgbáyé, tí wọ́n sì wà káàkiri orígun mẹ́rẹ̀rin ilẹ̀ Yorùbá báyi – ìbáà ṣe àjèjì èèyàn, àjèjì ẹbọra, iwin àbí ànjọ̀ọ̀nú, ó wà nínú omi ni, nínú igi ni, nínú àpáta ni, nínú ilẹ̀ ni, nínú ènìyàn ni, ní ibi ibòji-àwọn-òkú, ibikíbi tó wù kó wà, kí Ọlọ́run bínú sí wọn.

Àkọ́kọ́, gbogbo àwọn àjèjì tó ngbàá lérò, àbí ó nsa iṣẹ́, pé ohun tí Olódùmarè fún Ọmọ Yorùbá, pé òun fẹ́ gbàá, òun máa gbàá, òun fẹ́ ji; òun fẹ́ kó di ti òun; Àjòjì tó ní pé ohun ìní, àmúṣọrọ̀, àti àwọn Àlùmọ́nì tí Olódùmarè fún Ọmọ-Yorùbá lórí ilẹ̀ wa, Nínú ilẹ̀ wa, omi wa, àyíká àti Agbègbè-wa, àjèjì tí ó npète, tí ó nsa iṣẹ́ pé òun fẹ́ gba Dúkìá Ìran YORÙBÁ, káàkiri níbikíbi ní ilẹ̀ Yorùbá; tí ó fẹ́ gba ǹkan-ìní, ohun-ìní Ọmọ-Yorùbá; ǹkan ÀJOGÚNBÁ ÀWA-ỌMỌ-YORÙBÁ, wípé irúfẹ́ àjèjì bẹ́ẹ̀ KÍ WỌ́N PARUN LÓJIJÌ.

Màmá ní kí a ṣẹ́ Èpè kí á dẹ̀ gé Ègún sí orí àwọn Àjèjì wọ̀nyí.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal