Ṣébí ní àìpẹ́ yi ni a rí bí àwọn ọ̀dọ́ ìlú Gẹ̀ẹ́si ṣe sọ pé àwọn nfẹ́ ìlú wọn padà, àtí pé àwọn àjèjì ti gba ìlú àwọn mọ́ wọn lọ́wọ́.
Ọ̀rọ̀ ré o, àwa Ọmọ Yorùbá; ṣebí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìgbà ni Màmá wa, Ìránṣẹ́ Olódùmarè, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí Abíọ́lá, ti máa nsọ fún wa pé, àwa tí a wà ní Okè-Òkun, kí á má ṣe gb’ara lé pé a ní ìwé ìgbélú dání; wọ́n ti máa nsọọ́ pé a ò ṣáà lè sọ pé aò mọ àwọ wa: ìgbàkúgbà ni àwọn oní’lú l’okè òkun lè sọ pé ká kẹ́rù wa kúrò ní ìlú àwọn: òun ló délẹ̀ yí o! A ti wá ri báyi o! Wọ́n ti njúwe ọ̀nà ilé wa fún wa.
Ìjọba-Adelé Orílẹ̀-Èdè wa ti ké gbàjarì báyi, wọ́n ní kí àwa ọmọ Yorùbá tó wà ní okè-òkun máa bọ̀ nílé o, àwọn oní’lú òkè-òkun ti bẹ̀rẹ̀ sí pàrokò ká máa lọ sílé wa; Yorùbá ti jẹ́ orílẹ̀-èdè láti ìṣẹ̀dálẹ̀ wá; nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa bọ̀ nlé!
Àgàgà, a ti wá gba ìjẹ́-Orílẹ̀-Èdè wa padà báyi – láti ogúnjọ́ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún; bẹ́ẹ̀ náà ni a ti bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba-ara-ẹni tiwa láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, tí a wà nínú rẹ̀ yí.
Ó tó àsìkò kí a padà sílé, báyi, ó tó àsìkò kí á wá ṣe iṣẹ́ ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè wa – Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá. Ìjọba-Adelé D.R.Y ló fi ọ̀rọ̀ yí ránṣẹ́ sí gbogbo àwa ọmọ Yorùbá tí a wà lókè òkun àti lẹ́hìn odi o, káàkiri àgbáyé.
A ti ní Àlàkalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, fún ìgbélékè orílẹ̀-èdè wa – Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá. Àlàkalẹ̀ yí ni ó jẹ́ ÌPÌLẸ̀, ìpìlẹ̀ TUNTUN, fún orílẹ̀-èdè wa. Láyé, a kìí ṣe ẹrú mọ́.
Ìjọba-Adelé wa sọ pé ohun tí ó nṣẹlẹ̀ ní ìlú Gẹ̀ẹ́sì yí, Ẹ̀RÍ nlá ni o, kí á le mọ̀ pé ìgbàkúgbà ní wọ́n le lé wa kúrò ní Ìlú wọn!
Nítorí èyí, Ìjọba D.R.Y sọ pé kí á padà sílé o, kí á padà sí Ilẹ̀ Yorùba – Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá.
Nítorí náà, wọ́n sọ pé gbogbo ọmọ Yorùbá tó wà ní òkè-òkun ṣùgbọ́n tí wọn ò fi ara sí ọ̀rọ̀ dídádúró tí orílẹ̀-èdè wa, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) ti dádúró, ẹ tún-un ro o!
Ẹ̀yin náà ti rí báyi – ẹ w’ẹnu ilẹ̀, ẹ w’ẹnu ọkọ́. Ṣùgbọ́n kìí ṣe àwọn ọ̀dàlẹ̀, tí wọ́n ti fi’ra wọn hàn tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́bí ọ̀dàlẹ̀ l’a nsọ o! A ò pe àwọn yẹn o, kí wọ́n máṣe rò pé àwọn le rápálá sí àárin wa.
Wọ́n tún ní kí á sọ fún gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y), káàkiri ibi tí a wà, Olóri Ìjọba-Adelé wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́, ti kọ Ìwé ránṣẹ́ sí Olórí-Ìlú Gẹ̀ẹ́sì (UK), pé kí ó ri pé ohun aburú kankan kò ṣẹlẹ̀ sí Ọmọ Yorùbá ní ìlú Gẹ̀ẹ́sì, àti pé ọmọlúàbí ni àwa ọmọ Yorùbá o, nítorí náà, kí ó máṣe ṣe ọmọ Yorùbá kankan bí ọ̀daràn o!
Olórí Adelé tún wá fi ohùn ránṣẹ́ sí àwa ọmọ Yorùbá: wọ́n ní ojú lalákàn fi nṣọ́ri, kí á ríi dájú pé a ṣọ́ bí a ṣe nṣe; bẹ́ẹ̀ ni kí á dẹ̀ máa pe ara wa lóòrèkóòrè, kí á dẹ̀ ri pé a ò pẹ́ ní’ta l’alẹ́.