Àwa òbí ẹ jẹ́ kí a máa ṣe àbójútó àwọn ọmọ wa dáadáa, nítorí pé àwọn tí wọ́n pe’ra wọn ní alágbára ayé yìí wọ́n fẹ́ dojú ayé bolẹ̀ lòdì sí bí Olódùmarè ṣe dáa ni.
Fọ́nrán kan ni a rí lórí ẹ̀rọ ayélujára tí arábìnrin kan ń ṣe àlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí nípa ẹ̀kọ́ òdì tí wọ́n ń kọ́ ọmọ rẹ̀ tí ó wà ní ipele karùn-ún ni ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀.
Ó wípé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nígbà tí òun rí wípé wọ́n ti ń kọ́ ọmọ kékeré náà ní ọ̀nà tí ọkùnrin tàbí obìnrin leè gbà tu ara rẹ̀ lára nípasẹ̀ fífi nǹkan ọmọkùnrin tàbí ti ọmọbìnrin rẹ̀ ṣeré fúnra rẹ̀.
Àti pé wọ́n tún lè yí ẹ̀dá tí Ọlọ́run dá wọn padà, gẹ́ẹ́gẹ́ bí wípé ẹni tí Ọlọ́run dá ní ọkùnrin ó lè sọpé òun di obìnrin kó sì máa mú’ra tàbí wọ aṣọ bí obìnrin, bákannáà ẹni tí Ọlọ́run dá ní obìnrin ó lè sọpé òun di ọkùnrin, kó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bí ọkùnrin, nítorí pé ohun tí ènìyàn bá pe ara rẹ̀ ló ṣe pàtàkì jùlọ.
Ohun ìbànújẹ́ ni eléyìí, nítorí náà, ẹ̀yin òbí ẹ jẹ́ kí a máa kíyèsí ìwà àti ìṣe àwọn ọmọ wa dáadáa èyí kò ní ṣe pẹ̀lú ọjọ́ orí rárá, Olódùmarè tó dá ènìyàn ní takọtabo kò ṣe àṣìṣe ṣùgbọ́n àwọn ẹlẹ́mìí àṣètáánì yí ló fẹ́ d’orí ayé k’odò.
Ara àwọn èròǹgbà wọn láti dín iye àwọn ènìyàn tí ó wà ní àgbáyé kù ni, tí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ láti rí ìgbéyàwó bí ohun tí kò ṣe pàtàkì, báwo ni wọn yóò ṣe bí ọmọ?
Ṣùgbọ́n àwa ìran Yorùbá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Olódùmarè tó wípé ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yí ni ká padà sílè tó sì gbé ẹni bí ọkàn rẹ̀ dìde màmá wa Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ìran Yorùbá mọ̀ọ́ lóore ò.