Látètèkọ́ṣe ti àwọn amúnisìn bẹ̀rẹ̀ láti ma wá s’órílẹ̀ Yorùbá láti bá àwọn Baba nla wa ṣ’edókówò ni àwọn ọmọ Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ sí nbọ́ sínú oko ẹrú lọ́lọ́kan òjọ̀kan. Látì ìgbà yí wá ni wọn mọ̀ dájú wípé ilẹ̀ Yorùbá wà ní ìpele ìjọba kan síkejì tí àwọn amúnisìn si ri dájú pé, àṣẹ àwọn Ọba ti pọ̀jù lórí àwọn ènìyàn wọn. Ti wọn ṣìri bi ohun èlò láti gba ìṣèjọba ara ẹni lọ́wọ́ wọn.
Èyí ló ṣe okùnfà iwà ìjẹgàba tí àwọn aláwọ̀-funfun fi gbabẹ̀ wọlé sí àwọn Ọba aládé lára, wọn sì tún ri wípé ọmọ Yorùbá fẹ́ran àpọ́nlé àti àyẹ́sí, látàrí èyí ni àwọn aláwọ̀ funfun ṣe ri àwọn Ọba yìí mu.
Àwọn amúnisìn yìí rí dájú pé ìwà ìjẹgàba yí náà ni wọn gbìn sínú gbogbo àwọn Ọba aládé wa àti ọ̀jọ̀gbọ́n, èyí lóṣe okùnfà bí wọn ṣe ta àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá l’ẹ́rú fún àwọn òyìnbó amúnisìn yí, nítorí ìwà ìkà inú wọn, láì mọ̀pé, óle ṣokùnfà bí wọn ṣe pàdánù ipò wọn láwùjọ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá.
Lẹ́yìn ìgbà yí ni àwọn òyìnbó ri dájú pé àwọn Ọba aládé sọ ipò àti agbára wọn nù sọ́wọ́ àwọn amúnisìn yi, tósì tún ṣokùnfà bí wọn ṣe wà lábẹ́ ìṣàkóso ̣àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n to nṣe aṣojú fún àwọn òyìnbó yìí tí wọn á sì mà darí àwọn Ọba yi ríborìbo, lẹ́yìn tí wọ́n ti sọ adé, ipò àti agbára wọn nù ní ìpele ìjọba ọmọ Yorùbá.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni, àwọn amúnisìn ntẹ̀síwájú láti ma lo àwọn Ọba nípasẹ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n yìí láti máa jẹ gàba lórí ọmọ Yorùbá lórí ilẹ̀ wa, nipa bí wọn ṣe nkó ohun àlùmọ́nì ilẹ̀ wa fún àwọn amúnisìn àti àjèjì láì bìkítà bọ́yá ebi npa ẹnìkọ́ọ̀kan.
Àwọn amúnisìn ti rọ ọba lóyè ní ilẹ̀ Yorùbá láti ìgbàtí ilẹ̀ Yorùbá ṣì wà lára Nàìjíríà, ṣùgbọ́n tí a ti wá jáde kúrò báyi láti ogúnjọ́ oṣù bélú ẹgbàá-ọdún ó lé méjìlélógún, a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba tiwa láti ọjọ́ kéjìlá oṣù igbe ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún.
Gẹ́gẹ́bí Màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, ṣe máa nsọ, kò sí agbára ọba ní ibi tí ó bá jẹ́ Republic. Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) kò ní ọba.Ọpẹ́ lóyẹ kí gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá I.Y.P máa dá lọ́wọ́ Olódùmarè, bí ó ṣe lo Màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla láti gba ìṣèjọba ara ẹni fún àwa I.Y.P tí ọmọ Yorùbá kankan kòní ti inú oko ẹrú kan bọ́sí òmíràn mọ́ láí.
Gbogbo ọmọ Yorùbá n’ílé lóko la má rí ògo wa lò, nípasẹ̀ ìṣèjọba ara ẹni. Àparò kan òní ga jù kan lọ, níbití àwọn olówó á ma lówó si tí àwọn tálákà ání lọ́pọ̀ yanturu, ogo ọmọ Yorùbá yóò sì bú yọ.