ỌMỌ ÌBÍLẸ̀ YORÙBÁ (Indigenous Youba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ẹ jẹ́ kí á ṣe ìfiyèsí pàtàkì yí: àwọn kan wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṢUN, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), tí wọ́n pe orúkọ ara wọn ní SEGILỌLA RESOURCES OPERATING LIMITED (SROL), wọ́n nwa àlùmọ́nì wa, wọ́n nwa GÓÒLÙ wa, ní ìpínlẹ̀ wa, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).
Màmá wa, Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí ìran-Yorùbá, Modúpẹ́ Onítìrí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin ) ti sọ ọ̀rọ̀ síta, nípa nkan tí SEGILỌLA RESOURCES OPERATING LIMITED tí ó nwa góòlù ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, D.R.Y nṣe.
MOA sọ pé a gbọ́ pé ilé-iṣẹ́ SEGILỌLA yí nfún ẹ̀yin tí ẹ wà ní àyíká rẹ̀ ní owó, pé kí ẹ fi ilé yín sìlẹ̀, pé àwọn ra ilé ní ọwọ́ yín. Màmá wa MOA sọ pé, gbogbo ẹ̀yin tí wọ́n ti ra ilé ní ọwọ́ yín, tó bá jẹ́ I.Y.P ni yín, Ẹ PADÀ SÍ ILÉ YÍN! Màmá wá sọ-ọ́, ní pàtó, wọ́n ní, Ilẹ̀ yẹn, Ilẹ̀ ỌMỌ-ÌBÍLẸ̀ NI! Nítorí náà, gbogbo I.Y.P, ẹ padà sí ilé yín.
Màmá wá sọ pé gbogbo irúfẹ́-ìwà báyẹn, kí wọ́n máa gba ilẹ̀ INDIGENOUS PEOPLE (ỌMỌ ÌBÍLẸ̀), èyí tí ó máa nṣẹlẹ̀ ní ìkópọ̀-amúnisìn tí wọ́n npè ní nàìjíríà, kò ní ṣẹlẹ̀, láyé, ní D.R.Y.
Màmá wa MOA sọ pé D.R.Y máa kàn sí ilé-iṣẹ́ Segilọla yẹn ní kíákíá! Bákan-náà, D.R.Y máa kàn sí olú-ilé-iṣé wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni D.R.Y máa kàn sí ÀJỌ ÀGBÁYÉ lórí ọ̀rọ̀ náà.
MOA sọ pé D.R.Y máa fún ilé-iṣẹ́ Segilọla ní ìwé-ìfitóniléti, pé, LỌ́GÁN, kí wọ́n dáwọ́ ohun tí wọ́n nṣe ní ilẹ̀ D.R.Y dúró – títí di ìgbà tí Segilọla bá kàn sí ìṣàkóso D.R.Y.
Nítorí náà, MOA sọ pé gbogbo ẹ̀yin tí ẹ bá jẹ́ I.Y.P, tí wọ́n ti fún lówó pé kí ẹ fi ilé yín sílẹ̀, Ẹ PADÀ SÍ ILÉ YÍN.