Gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) tó dúró déédé lóri òtítọ́ àti òdodo ni màmá wa, Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá (Olóye Ìyá Ààfin) gbà ní ìyànjú pé àsìkò yí ṣe pàtàkì fún Ọlọ́run, nítorínáà ka má gba ìrẹ̀wẹ̀sì láàyè rárá.
Ádùrá ngbà àti pé àsìkò tó yẹ ní Ọlọ́run ma ń ṣe ohun gbogbo.
Màmá wa MOA tẹ̀síwájú pé Ọlọ́run kìí pẹ́ nínú iṣẹ́ Rẹ̀, àkókò tó yẹ ni ìdáhùn máa ń farahàn sí àdúrà ènìyàn.
Tí a bá ṣe àkíyèsí dáradára, ní gbogbo ìgbà tí a bá ń kánjú, tó dàbí pé ó pẹ́ lójú tiwa, àṣepé oore ni Ọlọ́run ńṣe fún àwa ọmọ Aládé. Òun ló ń ṣàánú wa láti mọ ọ̀nà tí a máa gbà, tó sì ń dáhùn ádùrá wa.
Nípa ìdáhùn ádùrá ni àṣírí àwọn ìkà àti òní’pàdé ọ̀tẹ̀ fi ń tú, nítorí ìdí èyí, wọ́n ní kí a máa gbàdúrà láì ṣe ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn.
Ọ̀rọ̀ náà tún kàn àwọn òdọ́ wa láti ẹnu ìyá wa, màmá òmìnira Yorùbá, MOA, pé kí gbogbo ọ̀dọ́ I.Y.P tó dúró, gbìyànjú kí wọ́n má yẹ’ sẹ̀, nítorípé ní àsìkò yí Ọ̀lọ́run ti ṣetán láti ṣe oore fún àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá, ní pàtàkì jùlọ àwọn ọ̀dọ́ I.Y.P.
Màmá ni kí ẹ̀yin ọ̀dọ́ wa má jé kí àwọn tí ayé wọn ti bàjẹ́ tán ba ti yín jẹ́ o. Ọ̀dọ́ tó bá pinnu láti yẹsẹ̀ tó tẹ̀lé àwọn ọ̀bàyéjẹ́ ti ṣubú ó sì ti pàdánù ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y).
Lóòótọ́ oníkálùkú ló ní ẹ̀tọ́ láti yan ohun tí ó fẹ́, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ ìyá wa. Ti yíyàn rẹ ò bá ti ní ìpalára fún ẹlòmíràn, kò sí wàhálà. Ìwọ nìkan lo ni àbájáde rẹ̀. Ṣùgbọ́n tí nkan tó yàn bá pa ẹlòmíràn lára, ó tí di ọ̀ràn sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́rùn nìyẹn.
Nítorínáà kí gbogbo àwa ọmọ Aládé, ní pàtàkì jùlọ, ọ̀dọ́ I.Y.P, kíyèsára ní àkókò kúkúrú tó kù fún àwọn Alákòóso wa láti wọ oríkò ilé ìṣàkóso, kí a má sì fi àyè gba ìrẹ̀wẹ̀sì.