Nínú ọ̀rọ̀ Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) sí àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.YP) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ní àìpẹ́ yí, Màmá wa MOA ṣe ìkí-ni pàtàkì fún àwọn I.Y.P ti D.R.Y, tí wọ́n fi etí sílẹ̀, tí wọ́n sì ní etí ìgbọràn.
Ìkíni tí Màmá wa MOA ṣe yí, wọ́n fi ránṣẹ́ sí, Èkíní, àwọn I.Y.P ti D.R.Y tí wọ́n ti mú àwọn ọmọ wọn kúrò ní ilé-ìwé. MOA, kí wọn lọ́pọ̀lọ́pọ̀
Tí a ò bá gbàgbé, ní ọjọ́ kẹ́ta, oṣù bélú, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, Màmá wa MOA fi ọ̀rọ̀ léde pé kí gbogbo I.Y.P ti D.R.Y, mú gbogbo àwọn ọmọ wa kúrò ní àwọn ilé-ìwé ní ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), èyí tí ó jẹ́ pé, lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà – èyí tí kìí ṣe ìlú, tí kìí ṣe orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n ètò àwọn amúnisìn lásán-làsàn ni, tí wọ́n jẹgàba sí, ṣùgbọ́n tí Olódùmarè máa parí iṣẹ́ lílé wọn kúrò níbẹ̀ ní àìpẹ́ yí..
Ètò-amúnisìn tí ó njẹ́ nàìjíríà yí, kò ní ẹ̀tọ́ kankan láti jẹgàba sorí ilẹ̀ wa, débi tí wọ́n wọn ó ma jẹgàba sí àwọn ilé-ìwé ní ilẹ̀ wa.
Gbogbo wa ni a rántí pé, Bàbá wa, Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọ́kọrẹ́ – olórí ìṣàkóso Adelé – ti sọ, nínú ọ̀rọ̀ wọn, tẹ́lẹ̀, ní ọjọ́ kéjìlá, oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rinlélógún, pé kí gbogbo ilé-ìwé ní D.R.Y ó ṣì wà ní títì pa ná, ṣùgbọ́n àwọn agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà fi ipá dúró sórí ilẹ̀ wa, wọ́n sì nṣiṣẹ́ ilé-ìwé lọ.
Ṣùgbọ́n, gbogbo èyí tí wọ́n nṣe yí ni wọ́n máa san. Ìyẹn bẹ́ẹ̀, nítorí ẹnikẹ́ni kò lè fí ọwọ́ pa idà D.R.Y lójú, nígbàtí Olórí-Adelé ti sọ̀rọ̀ sí’ta.
Màmá wá MOA sọ, ní ọjọ́ tí wọ́n bá àwa I.Y.P ti D.R.Y sọ̀rọ̀, pé kí á mú àwọn ọmọ wa kúrò ní àwọn ilé-ìwé wa gbogbo, ní orílẹ̀-èdè wa, D.R.Y, àti pé I.Y.P tí kò ṣe èyí, ó nsan owó tí kò yẹ kó san, irú I.Y.P bẹ́ẹ̀ kò ní ní ànfààní ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ fún ọmọ náà tí ó ṣì wà ní ilé-ìwé báyi, nígbàti D.R.Y bá kéde ṣíṣí àwọn ilé-ìwé wa padà.
Ní àìpẹ́ yí, Màmá wá kí gbogbo I.Y.P tí wọ́n ṣe ìgbọràn, tí wọ́n ti mú àwọn ọmọ wọn kúrò ní ilé-ìwé.
Èkejì, Màmá wa MOA fí ìkíni ránṣẹ́ sí gbogbo I.Y.P ti D.R.Y, tí wọ́n ní etí-ìgbọràn, tí wọn kò gba abẹ́rẹ́-àjẹsára tí agbésùnmọ̀mí, ajẹgàba nàìjíríà, tí wọ́n ngbé kiri ní orí ilẹ̀ wa, D.R.Y.
Nígbàtí ìṣàkóso adelé wa bá wọlé sí àwọn oríkò ilé-iṣẹ́ ìṣàkóso wa gbogbo, I.Y.P tí ó bá wá sí ilé-ìwòsàn, tí àyẹ̀wo-ara rẹ̀ sì fihàn pé àìsàn tí ó wà ní agọ́-ara rẹ̀ jẹ́ àbọ̀ abẹ́rẹ́ àjẹsára lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ àṣẹ ti jáde pé kí a máṣe ní nkankan ṣe pẹ̀lú abẹ́rẹ́ àjẹsára, irúfẹ́ I.Y.P ti D.R.Y bẹ́ẹ̀ kò ní ní ànfààní ìwòsàn ọ̀fẹ́; ó máa fún’ra rẹ̀ san owó ìtọ́jú ara rẹ̀.
Gbogbo wa ni a rántí bí MOA ti ṣe ìkìlọ̀ láti máṣe gba abẹ́rẹ́-àjẹsara tí wọ́n ngbé kiri, nítorí lára ètò àwọn tí wọ́n fẹ́
dín ọmọ-ènìyàn kù ni, tí wọ́n sì fẹ́ pa aláwọ̀dúdú run. MOA kí gbogbo I.Y.P ti D.R.Y tí wọ́n gbọ́ràn.
Ẹkẹ́ta, Màmá wa, MOA, fi ìkíni ránṣẹ́ sí gbogbo I.Y.P ti D.R.Y tí wọn kò ní nkankan ṣe pẹ̀lú irúgbìn àti onjẹ tí ó jẹ́ ayédèru, GMO.
A mọ bí ìkìlọ̀ ṣe njáde fún wa pé, kí a máṣe gba irúgbìn GMO lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, kí a má sì ṣe jẹ onjẹ kankan tí ó jẹ́ GMO.
Màmá wá kí gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) tí wọ́n ṣe ìgbọràn, tí wọn ò ní nkankan ṣe pẹ̀lú GMO.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè tí Ó rán MOA, ìyá rere, sí wa.