Ẹni tí kò bá mọ̀ tẹ́lẹ̀, kí ó yára mọ̀ báyi – àwọn òyìnbó amúnisìn fẹ́ pa áfríkà run ni, kí àwọn lè wá jóko sí orí-ilẹ̀ wa, nítorí ilẹ̀ wa ni oríṣiríṣi ohun-àmúṣọrọ̀ wà (resources). Òyìnbò ò kì nṣe ọ̀rẹ́ aláwọ̀dúdú, ìyẹn ni kí a jẹ́ kí ó yé wa, dáradára.
Nítorí náà, ẹ máṣe jẹ́ kí ó yà wá lẹ́nu, àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), nígbàtí a bá nsọ nípa oríṣiríṣi ète abúrú tí àwọn òyìnbó amúnisìn ní lórí Áfríkà.
Ìròyìn kan tí ó tẹ̀wá lọ́wọ́ báyi, sọ pẹ́ orílẹ̀-èdè Russia tú àṣírí kan pé ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti npeléke si, nínú ète wọn láti fi ohun ẹlẹ́mi (biological weapons) gbé ogun ti ilẹ̀ áfríkà!
Igbá-kéjì-akọ̀wé Àjọ-Ààbò ilú Russia, tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Alexey Shevtsov, ló fọhùn síta o, pé, gbogbo nkan wọ̀nyí, tí wọ́n pè ní oríṣiríṣi orúkọ, bíi pé wọ́n ò kì nṣe ohun aburú, ó ní nṣe ni Amẹ́ríkà fi nṣe ìdàgbàsókè ohun-ìjà-ẹlẹ́mi (biological weapons), tí lára ohun-ìjà wọ̀nyí sì jẹ́ èyí tí wọ́n fẹ́ fi ṣe ìpalára fún àwọn ìran kọ̀ọ̀kan ní áfríkà tí wọ́n ti fi ojú sí lára pé wọ́n máa ṣewọ́n-l’ọṣẹ́!
Orílẹ̀-Èdè Russia ni ó tú àṣírí yí o, tí a sì nwo àwòrán Ààrẹ Russia, èyíinì, Putin, tí a nwo àwòrán rẹ̀ níbẹ̀, nínú ìròyìn náà tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́, tí wọ́n nkígbe fatafata pé Amẹ́ríkà nṣe iṣẹ́ láti fi ohun-ìjà ẹlẹ́mi (biological weapons) pa aláwọ̀dúdú run, wọ́n sì ní àwọn ìran kan, pàápàá lọ́kàn, láti pa wọ́n run. Ẹ jẹ́ kí á fura o. Orílẹ̀-Èdè Russia ni ó gbé àṣírí yí síta o!
Kí a máṣe fi ara sílẹ̀ o, gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y); ó ti dójú ẹ̀ báyi o! Ojú ni alákàn fi nṣọ́ orí.
Tí a bá rí ohunkóhun ní àyíká wa, níbikíbi ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), tí ó mú ìfurasí dání, kí á tètè fi tó adelé wa létí. Ṣé a ti gbọ́ o! A kò gbọ́dọ̀ jáfara rárá!
Nàìjíríà kò kàn wá o! Democatic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ló kàn wá o. Gbogbo I.Y.P ti D.R.Y, ẹ jẹ́ kí á kún fún ìfura.
Gbogbo àwọn-ológun, tí wọ́n jẹ́ ọmọ-Yorùbá àtàtà (I.Y.P), ẹ fi ojú yín sílẹ̀ dáadáa. Àti ọmọ Yorùbá tí ó wà nínú iṣẹ́ ológun, pẹ̀lú gbogbo ọmọ Yorùbá tí kò sí ní iṣẹ́ ológun, gbogbo wa, pátá, ni ọ̀rọ̀ yí kàn o!
Kí gbogbo I.Y.P máa fojú sílẹ̀; tí a bá ti rí àwọn irú nkan bẹ́ẹ̀-yẹn, kí á tètè pariwo síta.
Putin, ààrẹ russia, ló tún tú àṣírí àwọn wọ̀nyí o! Ó di ẹlẹ́ẹ̀kéjì tí wọ́n máa tú àṣírí àwọn ẹni-ibí wọ̀nyí, tí wọ́n fẹ́ fi ohun-ìjà-ẹlẹ́mi (biological weapons) pa àwọn ìran kan run.
Inkan tí Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin), máa nsọ nìyẹn o, pé àwọ́n ẹni-ibi wọ̀nyí, àwọn amúnisìn wọ̀nyí, sọ pé àwọn máa pa àwọn ìran kan run, ṣùgbọ́n àwọn ìran tí wọ́n fẹ́ parun ni àwọn ò mọ̀.
Gbogbo ọmọ yorùbá, àti I.Y.P tí ó wà nínú ológun àti èyí tí kò sí nínú iṣẹ́ ológun, ẹ jẹ́ kí á jọ pa ọwọ́ pọ̀, ká jọ ṣiṣẹ́ papọ̀, kí Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ó wà bí ó ṣe yẹ kó wà.
Àṣírí ló ti ntú yí o – ó pẹ́ tí màmá wa, MOA, ti nsọọ́, pé, àwọn amúnisìn wọ̀nyí, wọ́n fẹ́ pa àwọn ìran run, kí wọ́n lè gba ilẹ̀ wọn!
Ọmọ Yorùbá (I.Y.P) ti D.R.Y, ibikíbi tí a bá ti rí àwọn ilé ìwádi imọ̀-ìjìnlẹ̀ (èyí tí a mọ̀ sí Lab; tí àpèjá ẹ̀ njẹ́ laboratory), ibikíbií tí a bá ti rí wọn ní ilẹ̀ Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), gbogbo wa ẹ jẹ́ kí á pariwo ẹ̀, ká tú àṣírí wọn.
Torí àwọn amúnisìn wọ̀nyí, ohun tí wọ́n máa nṣe ni láti sọ pé àwọn nṣe iṣẹ́-ìwádi-ìjìnlẹ̀ kan, wọ́n á wá gbé àwọn oríṣiríṣi nkan kalẹ̀ – medical centre, research centre, laboratory, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, láti fi ṣe bojú-bojú fún àwọn iṣẹ́-ibi wọn.
Iṣẹ́ gbogbo wa nìyí o – àti ọmọ yorùbá (i.y.p ti d.r.y), tí ó wà ní iṣẹ́ ológun àti ẹni tí kò sí nínú iṣẹ́ ológun, ẹ jẹ́ kí á tú àṣírí irú nkan bẹ́ẹ̀, kí á fi tó etí ìṣàkóso-adelé wa, ìṣàkóso-adelé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y), ní adelé
Ẹyẹ tó fi ara rẹ̀ wé igún, ẹ̀yìn ààrò ló máa sùn