Àbá ní ńdi òtítọ́; ojo ni kì í jẹ́ ká da
Ìyá wa, Olóyè ìyá ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí àwa ìran Yorùbá ti sọ fún àwa Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y) pé kí á fi ọkàn balẹ, kò sí aburú kankan tí ó le ṣẹlẹ̀ sí àwọn lágbára Èdùmàrè.
Wọ́n ní àwọn gbọ́ pé àwọn kan ngbé ọ̀rọ̀ kan kiri pé, àwọn aríremáṣe nàìjíríà gbé owó fún àwọn kan tí ó sún mọ́ Màmá wa láti ṣe aburú. Màmá ní kò sí ǹkan tó jọ-ọ́, àti pé Olódùmarè fún’Ra rẹ̀ ní ó pe àwọn tí ó nbá àwọn ṣiṣẹ́, tí Ó sì yàn wọ́n. Wọ́n ní kò tilẹ̀ sí I.Y.P ti D.R.Y tó lè gba àbọ̀dé fún àwọn.
Màmá wá sọ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ohunkóhun, tí wọ́n sì fẹ́ gbe wá síwájú ọmọ Yorùbá, kí wọ́n kíyèsára nípa bí wọ́n ti máà gbé ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀! Wọ́n wa sọ pé kò sí òtítọ́ kankan nínú pé àwọn tó súnmọ́ àwọn gba owó kankan.
Màmá sọ pé àwọn máa rí àrọ́mọd’ọmọ Ìran Yorùbá, torí pé ojú àwọn ni àwọn máa fi rí ìmúṣẹ gbogbo Àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé fún Ọmọ Yorùbá. Wọ́n wá sọ pé kí á mú ìjayà àti ìbẹ̀rù kúrò ní ọkàn wa, wọ́n ní, gbogbo ohun tí Olódùmarè fi àṣẹ dá, ẹ̀yìn MOA ni wọ́n wà!