Ṣé kò kúkú sí nkan tó kàn wá pẹ̀lú ìjọba mùjẹ̀mùjẹ̀, ìjọba Agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, tí kìí bá ńṣe ìwà jíjẹgàba tí wọ́n ń ṣe lórí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), èyí tí Olódùmarè dẹ̀ máa ràn wá lọ́wọ́ láti lé wọn kúrò ní orí-ilẹ̀ wa ní àìpẹ́ àti àìjìnnà.

Jíjẹgàba yí ni a fi fẹ́ sọ fún wa láti máṣe gbàgbé pé àjèjì, agbésùnmọ̀mí, apanilára àti ajẹgàba ni wọ́n jẹ́ ní orí ilẹ̀ wa o! – kí a má ṣe sun àsùnpara tí yóò mú kí a gbàgbé pé a ò sí lábẹ́ Nàìjíríà mọ́; a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé rárá! Ìdí nìyí tí ìkìlọ kan lórí ẹ̀rọ ayélujára ṣe rán wa létí pé, kí a máṣe gba ohun tí ó bá ńti ọ̀dọ̀ ìjọba Nàìjíríà jáde ò! àwọn kọ́ ni ìjọba D.R.Y; kí á má sì ṣe gbàgbé pé Ìránṣẹ́ Bill Gates ni Nàìjíríà o!Ìránṣẹ́ Ikú sì ni Bill Gates jẹ́; nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a kíyèsára!