Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ní Ètò fún iná mọ̀nàmọ́ná tí kò ṣẹ́’jú káàkiri ilẹ̀ Yorùbá. Bẹ́ẹ̀ náà ni D.R.Y kò gba ìgbàkugbà l’orí ọ̀rọ̀ ohun àmúṣ’agbára, gẹ́gẹ́bí epo rọ̀bì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Lọ́kan-ò-jọ̀kan ni àwọn àǹfààní tí yóò wà ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) nítorí pé màmá wa Ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla tí Olódùmarè lò láti gba ìran Yorùbá lóko ẹrú fẹ́ràn ìran wọn tọkàntọkàn tí wọ́n kò sì fẹ́ kí ìyà jẹ ọmọ Yorùbá kankan, àlàkalẹ̀ ètò ìsèjọba tí Olódùmarè sì gbé lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí màmá wa MOA ṣe máa ń sọ fún wa wípé kò sí irú rẹ̀ ní àgbáyé, lára àwọn ohun am’áyédẹrùn tí a óò jẹ ìgbádùn rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè D.R.Y náà ni iná mọ̀nà-mọ́ná.
Láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún tí a ti ṣe ìbúra wọlé fún olórí adelé wá bàbá wa Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ náà ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tí gbogbo rẹ̀ sì ń lọ létò-letò nítorí pé pàtàkì ni iná mọ̀nà-mọ́ná láwùjọ, gbogbo àwọn onílé iṣẹ́ ńlá-ńlá àti olóko òwò kéékèèké yóò máa rí iná lò lóòrè-kóòrè láti ṣe iṣẹ́ wọn, bẹ́ẹ̀ sì ní gbogbo ìlú àti ìgbèríko káàkiri ilẹ̀ Yorùbá ni iná mọ̀nà-mọ́ná yóò wà tí kò ní sí ààyè fún àwọn amòkùns’èkà láti fi ojú pamọ́ sí.
Nítorí náà gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) ìgbé ayé ìrọ̀rùn ti dé fún wa, ẹ jẹ́ kí a máa jó ká sì máa yọ̀.
Orílẹ̀-Èdè Tiwantiwa ti Yorùbá jẹ Orílè-èdè Tuntun Olómìnira lati ọjọ Jimọ, ọjọ Kejìlá ti Oṣu Kẹrin (Ìgbé) ọdún 2024. Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá jẹ́ 17th ní Iwọ-oòrùn Áfíríkà, Orílẹ̀-èdè 55th ní Áfíríkà, ati Orílẹ̀-èdè Tuntun ni Àgbáyé. D.R.Y jáde kúrò, o sí farahàn ni àlàáfíà nipasẹ ìwé àdéhùn Àjọ Àgbáyé (UN) lorí ẹtọ ọmọ ènìyàn, àwọn ẹtọ ìpinnu-lọkan ara ẹnì fún idà dúró gẹgẹ bi orílè-èdè.
© Copyright 2024 Nípasẹ̀ Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá