Ṣebí ìjẹgàba ìjọba agbésùnmọ̀mí nàìjíríà, lórí ilẹ̀ Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ló fa ìwà ọmọ-ìta tí  oníṣègun òyìnbó kan hù ní ilé-ìwòsàn ìjọba, ní Ijaye, ìlú Abẹ́òkúta, Ìpínlẹ̀ Ògùn orílẹ̀-èdè D.R.Y. Ṣe ni àgbà dókítà ọ̀hún, ẹni tó jẹ́ Abánidámọ̀ràn nínú iṣẹ́ eegun-títò,bu ìfọ́’tí lu akẹ́ẹ̀kọ́ nọ́ọ̀sì kan ní ibi tí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́-abẹ.

Ìyẹn ló mú kí ẹgbẹ́ àwọn nọ́ọ̀sì  kọ ìwé sí àwọn ọ̀gá ilé-ìwòsàn láti fi ẹjọ́ sùn, ṣùgbọ́n tí wọn ò rí ìgbésẹ̀ kankan nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Èyí ló mú kí wọ́n  ṣe ìfẹ̀hónú-hàn tí kò ní ìjà tàbí ìwà ìpáǹle nínú, gẹ́gẹ́bí ìròyìn náà ti sọ. 

Gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P), kí oníkálùkù  ṣọ́ra! Ṣebí ìjẹgàba Nàìjíríà lórí ilẹ̀ wa ló fàá tí irú ìwà báyìí fi wáyé.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates