Ìròyìn kan tí ó jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára ni ọjọ́ kẹẹ́dógún oṣù Ògún tí a wà nínú rẹ̀ yìí, ni a ti rí àwòrán Ọ̀gbẹ́ni Dapo Abiodun, tí ó jẹ́ aṣojú ìlú Nàìjíríà, tí ó ń jẹ gàba lórí ilẹ̀ Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ati olórí àwọn jagunjagun orí omi, Emmanuel Ogalla, tí wọ́n bọ ara wọn lọ́wọ́ níbi tí Ọgbẹni Dapọ Abiodun tí ń fún ọ̀gágun náà ní ìwé mo yọǹda.
Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ sí’gbà náà ni àkọlé gbàgàdà míràn bá tún jáde tí ó ń kéde pé, òun Dapo Abiodun fi ìwé mo yọǹda ọgọ́rùn-ún saarè ilẹ̀ fún ilé iṣẹ́ ológun ojú omi kí wọn fi kọ́ ibùdó fún ilé iṣẹ́ wọn sì àgbègbè Abigi, èyí tí yóò le mú ìdàgbàsókè bá àgbègbè náà, a tún wá ríi kà níbẹ̀ pé Ọ̀gbẹ́ni Dapọ Abiodun ti fi iwe tí ó fi bèrè fún sísan bílíọ̀nù méje àti àbọ̀ naira lọ́wọ̀ àwọn ọmọ ológun ojú omí náà ránṣẹ́ sí wọn, ó ní kí wọ́n fi owo náà ránṣẹ́ kí òun tó yọǹda ìwé ẹ̀rí “ẹ̀yin ni ẹ ni’lẹ̀”.
Ẹ jọ̀wọ́ ẹ má dà wà lórí rú, èwo gan-an ni kí a gbàgbọ́ nínú gbogbo rẹ̀ bayi? Ati ti alábòjútó Bello Matawalle, tí a ríkà pé ó kọ̀wé ìdúpẹ́ sí Dapo Abiodun lori oore àtinúwá ẹ̀bùn ilẹ̀ oní saarè ọgọ́rùn-ún tí ó wà ni àgbègbè Olokola Free Trade Zone, tí ó sì tún ń wi pé kí àwọn aṣojú yókù lórí Ìpínlẹ̀ wọn náà le ṣe bẹ́ẹ̀.
He! He!! He!!! Tani ẹni tí ó láṣẹ lórí ilẹ̀ tí kìí ṣe tiwọn? Àwa ọmọ òǹ ni’lẹ̀ ti ń gbé ìkìlọ̀ jáde láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe, ẹgbàá-ọdún-o-lè-mẹ́rìnlélógún tí a wà nínú rẹ̀ yí, pé àwa ni Indigenous Yorùbá People (I.Y.P.) tí a ni ilẹ̀ Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y.), níbi tí ẹ̀yin àjèjì, ajẹgàba tí ń fi agídí pàṣẹ, lẹ́yìn tí ó yẹ kí ẹ ti kúrò lórí ilẹ̀ wa.
Ohun gbogbo tí ẹ bá ti ṣe lórí ilẹ̀ Ìpínlẹ̀ méjèèje tí Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa tí Yorùbá ni ẹ máa ṣírò tí ẹ sì máa dá padà o, àwa I.Y.P. kò bá tì’jà wá o.