Nínú àwọn àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso orílẹ̀ èdè D.R.Y tí Olódùmarè jogún fún Màmá wa ìyá ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá nípa ọ̀nà tí ìdàgbàsókè máa ṣe débá orílẹ̀ èdè wa, ni àwọn oríṣìríṣì orílẹ̀ èdè míràn ti ńwo àwòkọ́ṣe rere àwọn àlàkalẹ̀ yìí.

Lára àwọn àlàkalẹ̀ ìṣàkóso tó wà ní ilẹ̀ wa ni èdè wa, èdè Yorùbá ni aó ma sọ ni D.R.Y, bẹ́ẹ̀ ni èètò ààbò tó péye yíò wà láàrin ìlú àti ìgbèríko D.R.Y. 

Nínú èètò ọ̀rọ̀ ajé orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa Ti Yorùbá akò ní ta ohun rọ̀bì n’ilẹ̀ wa. Ṣùgbọ́n, àwọn ohun tí ati sọ di owó nìkan ni ao ma tà sílẹ̀ òkèèrè. Gẹ́gẹ́ bí Màmá wa, ìyá ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá ṣe ma nsọ wípé, Lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè Yorùbá ni àkọ́kọ́ nínú àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè gbé lé wọn lọ́wọ́. 

Ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye tí Olódùmarè jogún fún àwa ojúlówó ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) jẹ́ àfihàn nínú àwọn àlàkalẹ̀ èètò ìṣàkóso tí D.R.Y gbékalẹ̀ tó sì tún jẹ́ àwòkọ́ṣe rere fún gbogbo ilẹ̀ adúláwọ̀ lápapọ̀.

Ọpẹ́ lóyẹ kí gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá máa dá lọ́wọ́ Olódùmarè tó dá èdè àwa ọmọ Yorùbá padà láti oko ẹrú àwọn amúnisìn.

Ògo àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Yorùbá a bú yọ nínú àwọn àlàkalẹ̀ ti Olódùmarè gbé fún Màmá wa MOA láti tú Áfríkà sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ àwọn aninilára.

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.