Bill Gates la rí nínú fọ́nrán kan lórí ayélujára  tó ń sọ nípa ètò Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé láti ẹgbàá ọdún títí dé ẹgbàá ọdún ó lé márùndínlógún lórí ìgbésẹ̀ láti mú àdínkù bá ikú awọn ọmọ wẹ́wẹ́ ní àgbáyé.

Wọ́n tún tẹ̀síwájú pẹ̀lù ètò kannáà fún ẹgbàá ọdún ó lé márùndínlógún títí dé ẹgbàá ọdún lé ọ́gbọ̀n, èyí tí Bill Gates sọ pé òun ṣiṣẹ́ ribiribi nínú àwọn ètò naa fún àṣeyọrí rẹ̀, ṣùgbọ̀n a ríi pé kò sí òtítọ́ nínú ọ̀rọ̀ Bill Gates rárá.

Lótìtọ́, èròngbà rẹ̀ pẹ̀lú àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ ni láti ṣe ikú pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ èniyàn ní àgbáyé pàápàá jùlọ ní Áfríkà. Lára àwọn ìgbésẹ rẹ̀ ni àrùn Covid àti oríṣiríṣi abẹ́rẹ́ àjẹsára tíwọ́n gbé wá sílẹ̀ adúláwọ̀ látí pa àwa aláwọ̀ dúdú run.

Òun kannáà la bá pẹ̀lú irúgbìn G.M.O, tí àwọn aláwọ̀ funfun gbé wá nípasẹ̀ ọkùnrin oníṣẹ́ ibi Bill Gate láti dín àwọn ènìyàn Áfríkà kù. Ète yí ni àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà gbà wọlé nítorí owó àti ìwà ọ̀kánjúà wọn láì jẹ́ kí ará ìlú mọ ewu tó wà nínú  irúgbìn GMO.

Àìmọye ènìyàn ni Bill Gates àti àwọn aláwọ̀ funfun ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ wọ̀nyí ti rán lọ s’ọ́run láìpé ọjọ́ láti ìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ búburú yìí. Kò wá sí ààbò mọ́ lórí irúgbìn àtí oúnjẹ.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, Youngest country in the World 2024

Iṣẹ́ ibi kannáà ló kúkú wà lọ́wọ́ wọn àti àwọn agbésùnmọ̀mí nàìjíríà, àwọn agbésùnmọ̀mí yìí gan-an ni ó tún máa ń ṣe onígbọ̀wọ́ fún àwọn òníṣẹ́ ibi náà nítorí kò sí ètò ààbò kankan fún  oúnjẹ àwọn ará ìlú.

Àwa ọmọ Yorùbá wa fi dá ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà  lójú ní àkókò yí pé, yálà ó fẹ́ tàbí ó kọ̀, ó máa kúrò lórí ilẹ̀ wa, nítorí pé orí àga tí ẹ jókòó sí kìí ṣe àyè yín, ti àwa ọmọ Yorùbá ni. Ẹ kó ara yín lọ sí ìlú agbèsùnmọ̀mí nàìjíríà yín, ẹ jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ wa rí ògo lò, ìran Yorùbá ni ẹyin lójú Olódùmarè.

Nítorí náà, gbogbo àwa ọmọ Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ẹ jẹ́ kí a túbọ̀ ní sùúrù, àkókò díẹ̀ lókù, nítorí pé ìsèjọba Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) kò ní gba ìwà ibi láàyè lórí ilẹ̀ wa.