Ní àkókò kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíbá àwọn ọmọdébìnrin bí ọdún mọ́kànlá sí méjìlá ní ọjọ́ orí lòpọ̀, ti ṣẹlẹ̀, tí ọ̀gá ọlọ́pa ní agbègbè náà kò dẹ̀ rí ọ̀rọ̀ sọ nígbà tí àwọn aṣòfin bérè bí àwọn ọlọ́pa ṣe fi àwọn ọ̀daràn náà sílẹ̀.
Dípò ọ̀daran, wọ́n mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọdé náà, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n tún mú àwọn bàbá bíi mélo kan tí wọ́n fé lọ mú àwọn ọmọ wọn kúrò ní àwọn ibi tí wọ́n ti mbá wọn lòpọ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó máa nrò pé kò sí ìwà ìbàjẹ́ ní ìlú òyìnbó; ṣùgbọ́n irúfẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ báwọ̀nyí jẹ́ kí á mọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà-ìbàjẹ́, rìbá-gbígbà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ló wà ní ìlú àwọn òyìnbó wọ̀nyí.
A ò fi kẹ́gàn wọn, òtítọ́ ni – ìwà-ìbàjẹ́ wo ló tilẹ̀ burú ju èyí tí wọ́n ṣe ní orí-ilẹ̀ aláwọ̀dúdú? Ṣùgbọ́n ohun tí a fẹ́ kí á mọ̀, ni pé, a ò gbọ́dọ̀ máa wo òyìnbó kankan lókè-lókè bí àwòkọ́ṣe; àwọn fúnra wọn mọ̀ pé aláwọ̀dúdú ní ìwà ọmọlúàbí ju àwọn lọ; ní pàtàkì, àwa ìran Yorùbá; ṣùgbọ́n wọ́n pinnu láti purọ́ fún wa; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi ọgbọ́n àrékérekè gba tọwọ́ wa, wọ́n fún wa ní tiwọn tí kò dára tó tiwa!
Paríparì rẹ̀, wọ́n wá njí àlùmọ́nì ilẹ̀ wa, wọ́n fi ntún ìlú tiwọn ṣe; àwa wá rò pé ọ̀gá ni wọ́n ní àgbáyé: kò rí bẹ́ẹ̀ o!
A tún wá fi àsìkò yí pe àwọn ojúlówó Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), tó wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, pé, irú ìròhìn báwọ̀nyí,a fẹ́ kí ó ṣí wa lójú sí Ìdí tí a níláti ṣọ́ra gidi ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kí á máṣe bọ́ sí wàhálà kankan!
Ẹ máa ránti nígbà gbogbo pé òyìnbó kìí ṣe Ọlọ́run! Ìwà ìbàjẹ́ kún ọwọ́ wọn: a ò fi bà wọ́n jẹ́; ṣùgbọ́n kí á lè kíyèsára.