Arákùnrin kan ni ó fi fọ́nrán kan sórí ẹ̀rọ ayélujára níbi tí ó ti sàfihàn bàbá àgbà kan tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìlú Ọ̀yọ́ Ilé, bàbá àgbà yìí ṣe àlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ wípé, ní ìgbàtí àwọn àjèjì dé, ọ̀dọ̀ Basọ̀run ìgbà náà ni wọ́n lọ tààrà, kí ó tó di wípé Basọ̀run yìí mú wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Aláàfin ìgbà náà nítorí wípé àwọn Aláàfin ìgbà náà kò ṣeé kù gìrì lọ rí, ó lè tó nǹkan bíi oṣù mẹ́ta kí àwọn ọba míràn tó lè rí Aláàfin ìgbà náà tí wọn bá fẹ́ ríi.
Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on XArákùnrin kan ni ó fi fọ́nrán kan sórí ẹ̀rọ ayélujára níbi tí ó ti sàfihàn bàbá àgbà kan tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìlú Ọ̀yọ́ Ilé, bàbá àgbà yìí ṣe àlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ wípé, ní ìgbàtí àwọn àjèjì dé, ọ̀dọ̀ Basọ̀run ìgbà náà ni wọ́n lọ tààrà, kí ó tó di wípé Basọ̀run yìí mú wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Aláàfin ìgbà náà nítorí wípé àwọn Aláàfin ìgbà náà kò ṣeé kù gìrì lọ rí, ó lè tó nǹkan bíi oṣù mẹ́ta kí àwọn ọba míràn tó lè rí Aláàfin ìgbà náà tí wọn bá fẹ́ ríi.
Aláàfin yí sí gba àwọn atọ̀húnrìnwá yí tọwọ́-tẹsẹ̀ wípé àwọn fẹ́ kí ìlú kún nítorí náà, àwọn kò le lé wọn lọ.
Kẹ̀rẹ̀-kẹ̀rẹ̀, àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun náà wọlé. Nígbà tó yá wọ́n mú ọ̀làjú dé. Kòpẹ́kòjìnnà wọ́n mú páànù ìkanlé dé, rédíò, omi ẹ̀rọ àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀ lọ.
Bàbá àgbà yí ṣeé láàyè síwájú síi nínú ọ̀rọ̀ rẹẹ̀ wípé, ọ̀làjú tí àwọn òyìnbó yí mú wá ti ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan jẹ gidigidi, bí àpẹẹrẹ, kò sí ibọ̀wọ̀fún àwọn ọba mọ bíi ti ayé ọjọ́hun, ọ̀làjú yìí náà ni ó gba agbára lọ́wọ́ àwọn ọba tí wọ́n sì gbé agbára fún àwọn olóṣèlú lónìí, nítorí wípé ìjọ àwọn ọba ni wọ́n sọ di ìjọba, tí ó sì wá dí wípé ọba míràn kò le pa àṣẹ lorí ìtẹ́ rẹ̀ débi pé yóò pàṣẹ ìlú.
Bàbá àgbà náà sọ̀rọ̀ débi wípé tí Aláàfin bá sọ̀rọ̀ nígbà náà olúkúlùkù yóò máa gbọ̀n lórí ìdúró ní. Kò dà bíi ayé òde òní tó jẹ́ wípé Aláàfin gan-an á tí dúró sí ẹnu ọ̀nà de àlejò tí ó ń bọ̀, ohun tí ọ̀làjú ṣe ní dáradára kò tó èyí tí ó bàjẹ́.
Nǹkan tí ó wá kọnilóminú nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí bàbá àgbà yìí sọ ni wípé, àwọn Fúlàní ni wọ́n lé Aláàfin ìgbà náà àti gbogbo ará ìlú Ọ̀yọ́ Ilé kúrò ní ìlú yìí nígbà tí wọ́n ránsẹ́ sí àwọn ará ìlú náà wípé àwọn ńkó ogún bọ̀ tí ìlú náà sì ti di ìbùgbé àwọn Fúlàní agbébọn báyìí.
Ṣùgbọ́n ó wá ṣeni láàánú wípé, bàbá àgbà yí ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà láti wá rànwọ́n lọ́wọ́ láti gba àwọn ẹ̀sọ́ aláàbò sí àyíká ibẹ̀ nítorí wípé àwọn Fúlàní agbébọn ti gba gbogbo inú igbó níbẹ̀ tí ó sì jẹ wípé kosi ẹnikẹ́ni tí ó leè lọ sí àgbègbè yí rárá.
Àbí ẹ ò ri wípé, bàbá àgbàlagbà yí náà wà lára àwọn tí wọn kò mọ̀ wípé àwọn ìjọba agbésùnmọ̀mí tí ìlú Nàìjíríà kò ní àṣẹ kankan bó tiíwù ó mọ mọ́ ní ilẹ̀ Yorùbá tí ó tún sì ń pe àwọn olè yí láti wá kó àwọn ẹ̀sọ́ aláàbò sí àgbègbè náà.
Gẹ́gẹ́ bí àwa Indigenous Yorùbá People (I.Y.P) se mọ̀ pé kò sí ọba mọ́ nílẹ̀ Yorùbá nítorí wípé àwọn òyìnbó yí tí rọ ọba lóyè tipẹ́tipẹ́. Láìpẹ́ láìjìnà gbogbo ilẹ̀ àwa ọmọ Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) tí Nàìjíríà fi ọgbọ́n àrékérekè tà fún àjòjì ni a ó gbà padà.