Oríṣiríṣi ń kan la máa ngbọ́ tí àwọn òyìnbó máa nsọ. Kí á má sọ pé ó ṣe jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ òyínbó ni gbogbo ń kan tí a ń sọ wá ndálé? Ẹbi wá kọ́ọ, ìrònú-ẹrú tí wọ́n ti kó sí orí ọ̀pọ̀lọpọ̀ aláwọ̀dúdú ló ń jẹ́ kí á pe àkíyèsí wa sí àwọn nǹkan kan wọ̀nyí, nítorí ẹlòmíràn ti rò pé òtítọ́ ni ohunkóhun tí òyìnbó bá sọ, èyí kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá.
Kí a máṣe gbàgbé pé àwọn kan wà ní ayé yí tó jẹ́ pé, kí ayé ṣáà ti f’orí sísàlẹ̀ ni wọ́n ń wá kiri – kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lò pọ̀, kí obìnrin máa bá obìnrin lòpọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Èyí tí a tún wá gbọ́ báyìí ni pé, wọ́n ní kí á fojú àánú wo àwọn tó jẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí’sàlẹ̀ ni wọ́n ní’fẹ́ láti máa bá lòpọ̀, kí á gbà pé ìyẹn náà dára tí ó bá ti jẹ́ ń kan tí wọ́n fẹ́ nìyẹn.
Kí ó tó di pé àwọn kan máa bẹ̀rẹ̀ sí dába bíbá ọmọdé lòpọ̀ ni a ṣe ń sọ èyi: torí ìròyìn tí a rí fọ́nrán rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára sọ pé àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ òyìnbó kan ló sọ bẹ́ẹ̀.
Ẹ jọ̀wọ́, tí a bá ní ọmọbìrin tó jẹ́ ìpẹ́ẹ̀rẹ̀, tí wèrè ọkunrin kan wá sọ pé òun máa ba lòpọ̀, ṣé ọmọ ọdún mẹ́ta mọ nkan tó yẹ kóun ó sọ ni? Tí kò bá sì wá mọ̀, ṣé ọkùnrin ọ̀ún á wá fi tipá mu ni. Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè wà lẹnu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òyìnbó tí wọ́n pera wọn ní onímọ̀-ìjìnlẹ̀ wọ̀nyí.
Abájọ tí Ọlọ́run Olódùmarè sọ pé kí àwa Ọmọ Aládé ó padà sí orísun wa, ní déédé ìgbà yí, àti ní déédé àsìkò yìí, kí a má ṣe gbé ọpọlọ wa fún amúnisìn tàbí ẹnikẹ́ni láti dàárú. Kí ògo Ọlọ́run kí ó máa búyọ ní ayé wa, gẹ́gẹ́bí àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè ti gbé lé màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla lọ́wọ́, kí ààbò Ẹlẹ́da kí ó wà lórí wọn títí láí.