Oríṣiríṣi ń kan la máa ngbọ́ tí àwọn òyìnbó máa nsọ. Kí á má sọ pé ó ṣe jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ òyínbó ni gbogbo ń kan tí a ń sọ wá ndálé? Ẹbi wá kọ́ọ, ìrònú-ẹrú tí wọ́n ti kó sí orí ọ̀pọ̀lọpọ̀ aláwọ̀dúdú ló ń jẹ́ kí á pe àkíyèsí wa sí àwọn nǹkan kan wọ̀nyí, nítorí ẹlòmíràn ti rò pé òtítọ́ ni ohunkóhun tí òyìnbó bá sọ, èyí kò sì rí bẹ́ẹ̀ rárá.

Kí a máṣe gbàgbé pé àwọn kan wà ní ayé yí tó jẹ́ pé, kí ayé ṣáà ti f’orí sísàlẹ̀ ni wọ́n ń wá kiri – kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lò pọ̀, kí obìnrin máa bá obìnrin lòpọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Èyí tí a tún wá gbọ́ báyìí ni pé, wọ́n ní kí á fojú àánú wo àwọn tó jẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí’sàlẹ̀ ni wọ́n ní’fẹ́ láti máa bá lòpọ̀, kí á gbà pé ìyẹn náà dára tí ó bá ti jẹ́ ń kan tí wọ́n fẹ́ nìyẹn.

Kí ó tó di pé àwọn kan máa bẹ̀rẹ̀ sí dába bíbá ọmọdé lòpọ̀ ni a ṣe ń sọ èyi: torí ìròyìn tí a rí fọ́nrán rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára sọ pé àwọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ òyìnbó kan ló sọ bẹ́ẹ̀. 

Ẹ jọ̀wọ́, tí a bá ní ọmọbìrin  tó jẹ́ ìpẹ́ẹ̀rẹ̀, tí wèrè ọkunrin kan wá sọ pé òun máa ba lòpọ̀, ṣé ọmọ ọdún mẹ́ta mọ nkan tó yẹ kóun ó sọ ni? Tí kò bá sì wá mọ̀, ṣé ọkùnrin ọ̀ún á wá fi tipá mu ni. Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè wà lẹnu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òyìnbó tí wọ́n pera wọn ní onímọ̀-ìjìnlẹ̀ wọ̀nyí.

Abájọ tí Ọlọ́run Olódùmarè sọ pé kí àwa Ọmọ Aládé ó padà sí orísun wa, ní déédé ìgbà yí, àti ní déédé àsìkò yìí, kí a má ṣe gbé ọpọlọ wa fún amúnisìn tàbí ẹnikẹ́ni láti dàárú. Kí ògo Ọlọ́run kí ó máa búyọ ní ayé wa, gẹ́gẹ́bí àlàkalẹ̀ tí Olódùmarè ti gbé lé màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla lọ́wọ́, kí ààbò Ẹlẹ́da kí ó wà lórí wọn títí láí.

The Democratic Republic of the Yoruba also known in the Yoruba history as Yoruba Nation, Yoruba Kingdom, Yoruba Land and Yoruba Country is the newest nation in the world. The 55th nation in Africa and 17th in Western Africa as of 12th April 2024. Yoruba is know a sovereign nation and its no longer part of Nigeria.
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!