Nínú ìròyìn kan tí ó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni a ti gbọ́ wípé àwọn ọnímọ̀-ẹ̀rọ bíi mẹ́tàlélógún láti orílẹ̀ èdè Russia ni wọ́n ti gúnlẹ̀ bàgẹ̀ báyìí o sí ilé iṣẹ́ Àjàòkúta, níbi tí agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà npè ní ìpínlẹ̀ Kogi, ṣùgbọ́n tí apá kan rẹ̀ jẹ́ ti Orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y), tí Àjàòkúta tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí pàápàá sì jẹ́ ti D.R.Y
Àwọn òyìnbó yí ni a gbọ́ pé wọ́n wá fún àyẹ̀wò àti láti ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó ti bàjẹ́ ní ilé iṣẹ́ náà.
Nítorí náà , a fẹ́ fi àkókò yí sọ fún ẹ̀yin ìjọba Orílẹ̀ èdè Russia pé, Orílẹ̀ Èdè Yorùbá kò sí lára Nàìjíríà mọ́ láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, tí a sì ti ṣe ìbúra-wọlé fún olórí Ìjọba-Adelé wa, Bàbá wa, Mobọlaji Ọlawale Akinọla Ọmọkọrẹ, láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún; ṣùgbọ́n nítorí àwọn ọ̀kánjúwà, Nàìjíríà, tó ń jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa ni kò tíì jẹ́ kí ìjọba wa wọlé sí oríkò ilé iṣẹ́ ìjọba wa láti máa ṣiṣẹ́ lọ, tí ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀.
Ìbá sàn kí ẹ tètè padà síbi tí ẹ ti wá, nítorí pé orílẹ̀ èdè Yorùbá lóni ilé iṣẹ́ Àjàòkúta, ìjọba wa kò sì mọ ohunkóhun nípa ìrìn-àjò yín lọ síbẹ̀ rárá.
Ṣé ẹ wá rí ẹ̀yin ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà, ẹ túbọ̀ máa ṣe ẹ̀sín yín tẹ̀síwájú. Ṣé ilé ayé yìí kọ́ ni ẹ wà láti àìmọye ọdún tí ilé iṣẹ́ Àjàòkúta ti dẹnukọlẹ̀ mọ́ọyín lórí, tí ẹ kò gbé ìgbésẹ̀ kankan, ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ ti wá mọ̀ wípé orílẹ̀ èdè Yorùbá ti lọ, tí ẹ sì ti mọ̀ pé ó ti tán fún yín, ṣèbí ọ̀nà míràn láti tún kó owó jẹ náà ni ẹ nwá.
Ohunkóhun yòówù tí ẹ ò báà ṣe níbẹ̀, kò kàn wá, nítorí pé a ò rán-an yín nísẹ́. Ohunkóhun tí ẹ bá sì ṣe pẹ̀lú àwọn ọnímọ̀-ẹ̀rọ tí ẹ kó wá láti orílẹ̀ èdè Russia kí ẹ lọ máa yanjú ara yín ní Nàìjíríà, kò kàn wá. Láìpẹ́ àti láìjìnnà, ojú yín máa tó ríi.
Gbogbo ẹ̀yin ọmọ Yorùbá tí ó dúró ṣinṣin, ẹ jẹ́ kí a túbọ̀ tẹ̀síwájú nítorí àsìkò kékeré díẹ̀ báyìí náà lókù. Ṣé ẹ rí gbogbo èyí tí wọ́n ń ṣe yìí, láti leè máa fa ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìṣiyèméjì ni fún àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kò tíì yé dáadáa. Àwọn náà mọ̀ pé orílẹ̀ èdè Yorùbá ti dúró.
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a f’ọwọ́so’wọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ìjọba-Adelé wa, kí á lè gbé orílẹ̀ èdè wa gòkè àgbà. Olódùmarè ti ṣẹ́gun fún wa.