A tún ntẹ̀ síwájú, l’oní, nípa sís’ọ̀rọ̀ nípa àwọn orúkọ ìlẹ̀ Yorùbá.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Yàtọ̀ sí orúkọ àmút’ọ̀runwá, a lè sọ ọmọ wa ní oríṣiríṣi orúkọ tí ó bá wù wá.

Orúkọ tí a bá fún ọmọ wa, yàtọ̀ sí orúkọ àmút’ọ̀runwá; òun ni a mpè ní ORÚKỌ ÀBÍSỌ.

Kì nṣe gbogbo ọmọ ni ó ní orúkọ àmút’ọ̀runwá.

Yoruba names and their meanings - the democratic republic of the yoruba

Iye orùkọ tí ó bá wú wá ni a lè sọ ọmọ wa, yálà ọmọ náà tíẹ̀ ni orúkọ àmút’ọ̀runwá ni, tàbí kò ní.

Ní ìlẹ̀ Yorùbá, bàbá á fún ọmọ rẹ̀ ní orúkọ. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ìsọ’mọl’orúkọ yí; bẹ́ẹ̀ náà ni bàbá àgbà (bàbá tí ó bí bàbá ọmọ náà), ìyá àgbà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀, sábà máa nfún ọmọ náà l’orúkọ pàápàá.

Tí ẹni tí ó fún ọmọ yí ní orúkọ tí ó wùú bá ti’lẹ̀ rí ọmọ náà ní’jọ iwájú, tàbí tí ó fẹ́ bérè nípa ọmọ náà l’ọwọ́ àwọn òbí rẹ̀, ó lè béèrè rẹ̀, tàbí kí ó ki, pẹ̀lú orúkọ tí òun tìkárarẹ̀ sọ ọmọ náà ní ọjọ́ ìsọ’mọl’orúkọ.

Àwọn orúkọ tí ó ngbé àwọn akọni Yorùbá l’arugẹ, tàbí àṣà Yorùbá – gẹ́gẹ́bí ìdílé tí a bí ọmọ náà sí bá ṣe jẹ́ pẹ̀lú àwọn akọni wọ̀nyí tàbí àṣà wọ̀nyí:

1. ṢÀNGÓ: Orúkọ bíi, Sàngódina, Sàngóbíyi, Sàngóbùnmi,  Sàngótọ́lá, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

2. ỌYA: Orúkọ bíi, Ọyadìran, Oyagbèmí, Ọyaníran, Oyajinmi, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

3. ÒGÚN: Orúkọ bíi, Ògúndélé, Ògúndèjì, Ògúnbọ̀wálé, Ògúnṣẹ̀yẹ, Ògúntọ́lá, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

4. ÈṢÙ: Àwọn orúkọ bíi, Èṣùbíyi, Èṣùgbọlá, Èṣùyalé, Èṣùtóki, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.

5. IFÁ: Orúkọ bíi, Ifágbèmí, Fámúyiwá, Fálétí, Onífádé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

6. ORÒ: Orúkọ bíi, Oròbíyi, Oloròdé, Oròtọ́lá, Abíórò, ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

7. EGÚNGÚN: Àwọn orúkọ bíi, Eégúnjọbí, Eégúnlétí, Abegúndé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

8. Ọ̀ṢUN: Bíi, Ọ̀ṣunbùnmi, Ọ̀ṣunfúnmikẹ́, Ọ̀ṣunyẹmí, …

Ka Iroyin: Ilẹ̀ Yorùbá, Agbára Ọ̀dọ́

Bẹ́ẹ̀ náà ni a ní àwọn orúkọ abísọ tí ó nfi irúfẹ́ bí ìdílé náà ṣe rí:

Gẹ́gẹ́bí àpẹẹrẹ, Adéyẹmọ, Adéyínká, Adéyẹmí, Adébímpé, Adédùntán, Adéwùsì, Moradékẹ́, Moradéyọ̀, Bámigbadé, Adékànmbí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Bẹ́ẹ̀ náà ni Oyèdélé, Abísoyè, Oyèlẹyẹ, Oyèlékè, Oyèyẹmí, Oyèbámijí, …

Bẹ́ẹ̀ náà ni a ní àwọn orúkọ ní ìdílé tí a mọ̀ fún ọlá:

Ọlákúnlé, Ọlálẹyẹ, Ọláwùmí, Ọláníyan, Ọládipọ̀, (èyí tí ìdílé míràn lè pè ní) Ọládipúpọ̀; bẹ́ẹ̀ náà ni  a ní Ọládàpọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ka Ìròyìn: Ìjọba Agbésùnmọ̀mí Nka Yorùbá Mọ́ Naìjíría! Hábà!

Àwọn orúkọ àbísọ kan tún wà tí ó nfi irúfẹ́ iṣẹ́ tí a mọ àwọn babanlá ìdílé yẹn sí:

1. IṢẸ́ ỌDẸ: Ọdẹwálé, Ọdẹdínà, Ọdẹtọ́lá, Ọdẹtóyìnbó, Ọlaọdẹ, Ọdẹjàyí,..

2. IṢẸ́ ÌLÙ: Àyàngalu, Alayàndé, Àyàngbèmí, Àyàngbọlá, Àyànwálé, Àyàndélé, abbl

3. IṢẸ́ ALAGBẸ̀DẸ: Àgbẹ̀dẹjọbí, Ọláògún, Ògúnbánkẹ́, Ògúnníyì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Àwọn àgbẹ̀dẹ jẹ́ ẹni tí iṣẹ́ wọn jẹ mọ́ irin; nítorí náà, Ògún, gẹ́gẹ́bí akọni Yorùbá, jẹ́ akọni tí àwọn ìdílé alagbẹ̀dẹ mọ̀ nípa rẹ̀ l’ọpọ̀l’ọpọ̀; nítorí èyí, ‘Ògún’ sábà máa nwáyé nínú orúkọ àwọn ìdílé alagbẹ̀dẹ).

4. IṢẸ́ ỌNÀ (GBẸ́NÀGBẸ́NÀ): Ní ìdílé tí ó bá nṣ’iṣẹ́ ọnà, àwọn irúfẹ́ orúkọ wọ̀nyí á sábà máa wá’yé – Ọnàbánjọ, Ọlọ́nàdé, Ọnàjídé,  Ọnàyẹmí, Ọnàkúnlé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀.

5. IṢẸ́ ÀGBẸ̀: Àgbẹ̀sanmí, Àgbẹ̀lerè, Olokodáná, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

6. IṢẸ́ OGUN: Àwọn orúkọ bíi, Arogundádé, Arogunyọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀, sábà máa nwáyé nínú ìdílé bẹ́ẹ̀.

Ìyàtọ̀ wà l’aárín “Àrẹogun” àti Àrẹògún. “Àrẹogun” jẹ́ akọni nínú ogun. Nígbà míràn, orúkọ ènìyàn lè jẹ́ “Àrẹogun” ṣùgbọ́n kí àwọn ènìyàn máa ṣi orúkọ náà pè, wọ́n á sì máa pèé ni Àrẹògún. Ó ṣe pàtàkì kí o jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ pípè orúkọ tìrẹ, nítorí orúkọ ní Ìtú’mọ̀.

Ka Ìròyìn: Orúkọ Àmútọ̀runwá Nílẹ̀ Yorùbá

Àwọn tí ó njẹ́ “Akin”

“Akin” lè jẹ́ akọni nínú ogun; ó sì lè jẹ́ akin ní ọ̀nà míràn.

Àwọn orúkọ bíi Akínsànyà, Akínsanmí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Bẹ́ẹ̀ náà ni ìyàtọ̀ wà l’aárin “Akinọlá” àti Akínnọ́lá. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ bí a ṣe npe orúkọ tìrẹ àti bí a ṣe nkọọ́ sí’lẹ̀.

Àwọn orúkọ àbísọ míràn dúró l’orí irú ipò, tàbí àyè, tàbí ìṣẹlẹ̀ tí ó wá’yé tàbí tí ìdílé náà nlà kọjá ní ìgbà tí a bí ọmọ náà:

Àwọn orúkọ bíi, Fìjàbí, Moṣebọ́látán, Ọmọkówajọ, Ìbídapọ̀, Onípẹ́dé, Kúmolú, Bámidélé, Abídèmí, Kọ́láwọlé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. 

Orúkọ Yorùbá ní ìtú’mọ̀ l’ọpọ̀l’ọpọ̀, a dẹ ní l’ati jẹ́ kí ìrònú nípa ìtú’mọ̀ wọ̀nyí kí ó da’rí wa sí rere.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal