A kò tíì kó’fá nílé ifa ti ńṣẹ. Ní ìtọ̀kasí ètò ìṣèjọba ti màmá wa Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla ṣètò fún orílẹ̀-èdè Democratic Republic of the Yorùbá, àwọn orílẹ-èdè àgbáyé ti ń mú lò lára kékeré ti wọ́n sọ jáde ninu ohun gbogbo tí Ọlọ́run fí rán wọn sí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá.

Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti ara rẹ̀. Gbogbo ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀-èdè Nigerí àti àwọn gómìnà Nigeria, tí wọ́n ngbé l’orílẹ̀-èdè Yorùbá, gbogbo ẹ̀ pátápátá l’a nkójọ pọ̀ gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí. Share on X

Àpẹẹrẹ èyí farahàn nínú àwọn ọmọ ilé aṣòfin tuntun tí orílẹ-èdè Gẹẹsi (UK) ṣẹ̀ṣẹ̀ búra wọle fún, ọ̀dọ́ ni gbogbo wọn jẹ́. Ẹnití ọjọ́ orí rẹ̀ ga jù nínú gbogbo wọn ní ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n.

Orúkọ àti ọjò orí ẹni kọ̀ọ̀kan wọn rèé fún ìdánilójú:

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

1. San Carling, ọmọ ọdún mẹ́tàdínọ́gbọ̀n

2. Josh Dean ọmọ ọdún mẹ̀rìnlélógún

3. Luke Charters ọmọ ọdún méjìdinlọ̀gbọ̀n

4. Euan Stainbank ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógúnn

5. Lloyd Hatton ọmọ ọdún méjídínlọ́gbọ̀n

6. Jacob Collier ọmọ ọdún ḿẹ̀tàdínlọ́gbọ̀n

7. Keir Mather ọmọ ọdún mẹ́rìndìnlọ́gbọ̀n

8. Rosie Writhing ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n

9. Nadia Whittome ọmọ ọdún métàdínlọ́gbọ̀n

10. Joshua Reynolds ọmọ ọdún márǔndínlọ́gbọ̀n.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

Gbogbo àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n búra wọlé fún sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin yí kò sí èyí tí ọjọ́ orí rẹ̀ wọ ọgbọ̀n ọdún nínú wọn tí ó túmọ sí pé àwọn pàápàá tí ńfí ayé gba àwọn ọ̀dọ́ láti ṣe ìjọba gégébí ohun tí màmá wa Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla ṣètò fún orílẹ̀-èdè Democratic Republic of the Yorùbá

Àwọn àgbàyà olóṣèlú Naijiria tí kò fẹ́ ire fún àwọn ọ̀dọ́ tiwọn, egbòogi olóró ní wọn ńgbé lé àwọn ọ̀dọ́ yìí lọ́wọ́ láti ba ayé wọn jẹ́ kí wọ́n lè máa  jíṣẹ́ búburú fún àwọn àgbà ìkà náà.

Ṣugbọn a tí fòpin sí búburú yìí ní ilẹ Yorùbá nípa òmìnira Democratic Republic of the Yorùbá ní ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbẹ̀wáọdúnóléméjìlélógún àti bẹ̀rẹ̀ ìjọba wa nípa ìbúra fún Olórí Adelé wa ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbẹ̀wáọdúnólémẹ́rìnlélógún tí wọ́n sì tí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti ọjọ́ náà. Ìgbé ayé ọ̀tun sì tí dé fún àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè Yorùbá.

Ẹ̀yin ọ̀dọ̀ ilẹ̀ Yorùbá ló lè ṣé, nítorí ọ̀dọ́ ni agbárá ìlú, ẹ dìde láti gbaruku ti àwọn ìjọba Adelé wa kí ògo yín lè tètè búyọ.