Màmá wa ìyá ìran Yorùbá, Olùgbàlà àwa ọmọ Aládé, ìyá ààfin Modúpẹ́ọlá Onítìrí-Abíọ́lá sọ nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá sọ láìpẹ́ yí wípé ibikíbi tí a bá ti rí àwọn tó ń já ìwé fún àwọn tó ń ta ọjà ní orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y) kí a máa ya àwòrán wọn.
Bí ìyà ńlá bá gbéni ṣánlẹ̀, kékeré a sì máa g’orí ẹni. Oríṣiríṣi ìwà ìkà ni àwọn ajẹgàba Nàìjíríà ńhù lórí ilẹ̀ wa, tí wọ́n sì mọ̀ wípé wọn ò ní ẹ̀tọ́ láti wà lórí ilẹ̀ D.R.Y, láti Ogúnjọ́ oṣù bélú ẹgba ọdún ólé méjìlélógún, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò bọ̀wọ̀ fún òfin àgbáyé.
Ẹ jẹ́ kí á fi ọwọ́ sọwọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn adele wa, nítorí ní orílẹ̀ èdè D.R.Y gbogbo I.Y.P ni ó ṣe pàtàkì.
Lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá ni àkọ́kọ́, èyí jẹ́ ohun tí màmá wa Olóyè Ìyá Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla MOA ma nsọ nígbà gbogbo, láti rán wa létí pé ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ní ó ṣe pàtàkì jù lọ ní orílẹ̀ ẹ̀dè wa. Eṣinṣin ìyà kò ní bà lé ọmọ Aládé kankan níbikíbi ní àgbáyé.
Nítorí ọmọ Yorùbá ṣe pàtàkì, kò sí àyè fún ẹnìkankan láti tẹ ẹ̀tọ̀ ọmọ orílẹ̀ èdè Yorùbá mọ́lẹ.
A fẹ́ kí gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) lọ fi ọkàn wa bálẹ̀, ìgbé ayé ìrọ̀rùn ni gbogbo wa máa gbé ní orílẹ̀ èdè wa.
Kò sí ìnira fún wa mọ́, àlàkalẹ̀ ètò ìṣàkóso tí Olódùmarè gbé fún Màmá wa MOA, fún àwa ọmọ Yorùbá ni. Fún ìrọ̀rùn àti ìfọ̀kànbalẹ̀ sì ni, kìí ṣe láti fi ara ni àwa ọmọ Yorùbá.
Àwọn alákòóso orílẹ̀ èdè D.R.Y náà kò sì ní fi ọwọ́ sí ohunkóhun tó leè fa ìnira fún wa, nítorí pé, wọ́n wá láti ṣiṣẹ́ sin àwa ọmọ Yorùbá ni, kìí ṣe láti máa j’ayé fàmílétèntutọ́ kí ìyà sì máa jẹ́ àwọn ará ìlú, kò ní ṣẹlẹ̀ láéláé, nítorí pé lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá ni àkọ́kọ́.
Ní àkótán, ọ̀wọ̀ yíó wà fún àwa I.Y.P ní gbogbo àgbáyé, àǹfààní Orílẹ̀ Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá pọ̀, àkààkàtán ni.