Nínú fọ́nrán kán lórí ayélujára ni a ti ri ọkùnrin báálé ilé kan, tó fi ìkorò-ọkàn kígbe pé owó tí wọn ngbà l’oṣù kò tó láti ra àpò irẹ̀sì kan.
Kí ló fà á tí gbogbo nkan fi rí báyìí, nípasẹ̀ bí ọ̀rọ̀ yí ṣe ta bà wá ní Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) tìtorí ìjẹgàba Nàìjíríà lórí ilẹ̀ wa? A ní ọ̀pọ̀ ohun ọrọ̀ ní Orílẹ̀-Èdè wa, D.R.Y. Ìyà oúnjẹ kò yẹ kí ó wà, gẹ́gẹ́bí a ṣe mọ̀.
Arákùnrin yíì sọ pé báwo ni àwọn ṣe máa wà láàyè báyìí nítorí ìnira yíì tí pọ̀ jù. Ó dójú ẹ̀.
Màmá wá ti sọ-ọ́, fún àwa ọmọ aládé nipa ohun tó ń bọ, pé kò ní ṣe-é dúró wò.
Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ sisẹ́ fún àwọn ọ̀jẹ̀lú tí wọ́n pe’ra wọn ní olóṣèlú Nàìjíríà ní Ilẹ̀ Yorùbá, ẹ ti wá rí ayé yín lóde báyìí, nítorí àìgbọrán si ìkilọ̀ láti ẹnu ìránṣẹ́ Olodumare, màmá wá, MOA.
Báálé ilé náà tún tẹ̀siwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, àwọn ìyàwó ilé ti wá di olóṣó láì sí ìtìjú mọ́. Ìwà burúkú àti àbùkù ni èyí jẹ́, nítorí àtijẹ, àti àtimu.
Síbẹ̀ síbẹ̀, a dúpẹ́ lọwọ Olódùmarè tí ó se àtilẹyin Màmá wá, tí wọ́n ṣe akínkanjú láti gbà wá kúrò nínú oko-ẹrú àwọn amunisìn aláwọ̀-ẹlẹ́dẹ̀ àti àwọn ọjẹ̀lú orílẹ̀ èdè agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà.
Àwa ọmọ Democratic Republic of the Yorúbá (D.R.Y) kú oríire o. A sì tún dúpẹ́ lọwọ Ẹ̀lẹ̀dà wá pé ó gbé olùgbàlà dìde fún wa.
Wọn tí bá wá gba Orílẹ̀-Èdè Olominira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y) ni ogúnjọ oṣù bélú, ẹgbàá ọdún ó lé méjì-lé-l’ogún, tí ìṣèjọba-ara-ẹni sì ti bẹ̀rẹ̀ ni pẹrẹu láti ọjọ́ Kejìlá, oṣù igbe, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rin-lé-lógún. Eyí ló máa fi òpin sí àìní, ìṣẹ́ àti ebi títí lailai pọngbá.
Bí ẹkún pẹ́ títí dalẹ́, ayọ̀ ń bọ̀ làárọ̀. Nítorí ìgbà ọ̀pọ̀ fẹ́rẹ̀ dé láìpẹ́. Ní kété tí àwọn ljọba Adele wa bá ti wọlé sínú oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa gbogbo, ni ilẹ̀kùn ìdẹ̀ra ṣí sí’lẹ̀ fún gbogbo ọmọ aládé.
Ebi, ìkorò-ọkàn, ìnira, ìwà ólósó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, yíò di àfìs’ẹyìn tí eégún ń fi aṣọ, àwa ọmọ aládé yíò wá bọ́ sí ìgbé-ayé ìrọ̀rùn, ọ̀pọ̀ ati àláfíà, láṣẹ Èdùmàrè.
A ń kìlọ̀ fún gbogbo ẹ̀yin tí ẹ pe’ra ‘yin ní gómìnà, tí ẹ ò kì nṣe gómìnà D.R.Y, tó ń jẹgàba lori ilẹ àwa Indigenous Yorùbá People (I.Y.P), Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), kí ẹ kúrò.
Ìwọ Sanwó-Olú, Ṣèyí Mákindé, Adélékè, Dàpọ̀ Abíọ́dún, Ayédatiwa, Oyèbánjí, Abdulrahman Abdulrazaq, àti Ododo, ẹ kúrò lórí ibi ìjẹgàba tí ẹ ò ní ẹ̀tọ́ sí – ẹ kúrò nínú ilé-iṣẹ́ ìjọba Democratic Republic of the Yoruba.