Maxwell ni orúkọ ọkùnrin náà, ní ìlú Zimbabwe, ẹni tí Olódùmarè jogún làákàyè fún ní ti ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ẹ̀rọ. Ìròhìn lórí ayélujára fi tó wa létí pé Maxwell ti ṣe oríṣiríṣi nkan bí ẹ̀rọ tó ngbé agbára iná mọ̀nọ̀mọ́ná jáde láì lo wáyà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n nísiìyí, Maxwell wà ní ìlé-ìwòsàn, tìtorí àwọn tí ó kórira rẹ̀ fún-un ní májèlé jẹ!
Kí ọ̀rọ̀ náà tó ṣẹlẹ̀ ni wọ́n ti nhalẹ̀ mọ pé kó dẹ́kun ohun tí ó nṣe, nítorí pé àwọn oríṣiríṣi nkan ìdàgbàsókè tí ó ngbé síta máa gba ìjẹ lọ́wọ́ wọn, àti pé wọ́n npe àwọn ẹni ibi wọ̀nyí ní ‘Awo Àmúṣagbára’ (Energy Mafia) ní ìlú Zimbabwe!
Èyí dàbí irúfẹ́ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ ní Ìlú tí a ti kúrò.
Èdùmàrè ti gbé àlàkalẹ̀ ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) fún Ìyá wa, Ìránṣẹ́ Rẹ̀, Màmá, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, nípa èyí tí ìrọ̀rùn máa dé bá gbogbo Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), tí kò ní sí pé ẹnikan máa wà lẹ́hìn, tí á fi máa lépa ẹ̀mí ẹni tó nbẹ níwájú!