Awọn dókítà mẹ́jọ kan tí wọ́n jẹ́ ògúná gbòńgbò nínú ìtọ́jú àrùn jẹjẹrẹ ní wọ́n tí rí òkú wọn nínú ọkọ̀ òfurufú tí ó jábọ́ tí ó sì pa gbogbo awon ènìyàn méjìlélọ́gọ́ta tí ó wà ninu rẹ̀.
Àwọn dókítà yí ló ti ṣe ìpinnu láti tú àṣírí ipa tí abẹ́rẹ́ àjẹsára covid 19 kó nínú àrùn jẹjẹrẹ tí ó ń tàn kiri àgbáyé báyìí, Ibi àpéjọpọ̀ àgbáyé lórí ọ̀rọ̀ ipa abẹ́rẹ́ àjẹsára ati àrùn jẹjẹrẹ náà ní Sao Paulo ni wọ̀n ńlọ láti lọ sọrọ̀ nípa àbájáde ìwádìí wọn tí ó tú àṣírí pé èròjà mRNA àti abẹ́rẹ́ àjẹsára covid 19 yìí ló fa àrùn jẹjẹrẹ tí ó ńtàn kiri agbaye, bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn nlánlá nlo gbogbo ọ̀nà láti bo òtítọ́ náà mọ́lẹ̀.
Èyi wa fi hàn gbangba pé ó ṣeéṣe kí ejó lọ́wọ́ ńnú lórí ìṣèlẹ̀ jàm̀bá ọkọ̀ òfurufú tí ó fa ikú àwọn dókítà yìí.
Ara àwọn ètò búburú Bill Gates àti àwọn alágbára kan làgbáyé nínú àwọn aláwọ́ funfun, tó ńbáa sisẹ́ pọ̀ lórí ọ̀rọ covid 19 àti abẹ́rẹ́ àjẹsára ní láti ṣe ikú pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ èniyàn pàápàá àwa Áfríkà ṣùgbọ́n tí Olódùmarè jẹ́ kó já jó wọn lọ́wọ́.
Àwa ọmọ Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá níláti ṣọra gan nítorí èrò àwọn aláwọ̀ funfun yí kò dára rárá.
A dúpẹ́ pé màmá wa alálùbáríkà, Olóyè Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla, nínú àlàkalẹ̀ ìṣèjọba fun Democratic Republic of the Yorùbá, ti ṣètò ìlera tó dájú fún wa, tí yíò sì jẹ́ kí ààbò tó dájú wà fún wa lọ́wọ́ àwọn òògùn àti abẹ́rẹ́ àwọn ìkà ênìyàn tó lè fẹ́ lo ọ̀nà àjàkálẹ̀ àrùn tàbí ayédèrú òògùn àti abẹ́rẹ́ láti ṣe ibi fún wa.
Lára àwọn ètò yìí ní ṣíṣe àyẹ̀wò fínífíní fun gbogbo àwọn òògùn tó bá fẹ́ wọlé sí Orílẹ̀-Èdè D.R.Y, àti pé ìwádìí yíò wà fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ lílo ewé àti egbò wa fún ìtọjú àti ìwòsàn fún gbogbo àrùn àti àìlera.