Nígbà tí àwọn amúnisìn ti wá sí ilẹ̀ Yorùbá, tí wọ́n bá wa nínú ọlá àti ọlà, tí wọ́n rí àwọn ohun àrà mé-è-rírí tí Olódùmarè ṣe fún wa, ó yà wọ́n lẹ́nu wípé ṣe àwọn ìran kan wà tí Olódùmarè kẹ́ tó báyìí? Láti ìgbà náà ni wọ́n sì ti ń sa gbogbo ipá wọn láti gba àwọn ohun rere yí lọ́wọ́ wa.
Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ tí màmá wa Modupẹọla Onitiri-Abiọla kọ́ wa látẹ̀yìnwá wípé, èdè ni ìdánimọ̀ ẹni. Ṣùgbọ́n àwọn amúnisìn yí gba èdè abínibí wa èyí tó jẹ́ èdè Yorùbá, wọ́n fi èdè tiwọn rọ́pò. Wọ́n sọ èdè wa di èèwọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ àti ní ilé iṣẹ́, kódà òbí míràn kò lè sọ èdè Yorùbá sí àwọn ọmọ rẹ̀ mọ́ ní inú ilé.
Wọ́n gba àṣà wa, dé bi wípé tipátipá ni àwọn ọmọ fi ń kí àwọn òbí wọn. Ní àtijó ní ilẹ̀ Yorùbá tí ọmọbìnrin bá jí láàárọ̀ á kúnlẹ̀ kí òbí rẹ̀, nígbà tí ọmọkùnrin á dọ̀bálẹ̀.
Oúnjẹ ìbílẹ̀ wa ńkọ́, àwọn amúnisìn gba gbogbo rẹ̀ lọ́wọ́ wa, wọ́n fi oúnjẹ wọn tí kò ní àǹfààní kankan lára rọ́pò. Wọ́n ti pa gbogbo àṣà àti ìṣe Yorùbá run tán díẹ̀ lókù, Olódùmarè ló gbà wá, tó gbé màmá wa ìyá ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla dìde.
Odò tó bá gbàgbé orísun rẹ̀ píparun ló máa ń parun, kò sí ohun mìíràn tí àwọn amúnisìn yí ń fẹ́ ju pé kí ìran Yorùbá parun kí wọ́n leè wá máa kó àwọn àlùmọ́ọ́nì ilẹ̀ wa.
Ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú wípé àwa ọmọ Aládé jókòó, a fí ọwọ́ lẹ́rán, à ń wò, a ò fura. Ọ̀dọ́ mélòó ló tún fẹ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ mọ́, àwọn amúnisìn ti da ọpọlọ wọn rú, wọ́n ti rí iṣẹ́ àgbẹ̀ bí ohun ẹlẹ́gbin. Iṣẹ́ tí wọn yóò máa so okùn m’ọ́rùn bí ajá ọdẹ ni gbogbo wọn ń wá kiri.
Ọpẹ́lọpẹ́ Olódùmarè tó gbà wá lọ́wọ́ àwọn amúnisìn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ níbo ni ìran Yorùbá ìbá fi ojú sí. Àwọn amúnisìn ti gba góòlù lọ́wọ́ wa wọ́n gbé páńda lé wa lọ́wọ́.
Tí kìí bàa ṣe Olódùmarè tó wípé ní déédéé ìgbà yí àti ní déédéé àsìkò yí ni kí a padà sílè. Nítorí náà, gbogbo àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) ti orílẹ̀ èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá, D.R.Y), ẹ jẹ́ kí a ṣe ara wa lọ́kan, kí a lé àwọn ọ̀tá inú ilé tí àwọn amúnisìn ńlò kúrò lórí ilẹ̀ wa, kí a le máa jẹ ìgbádùn ire àti ayọ̀ tí Olódùmarè lo màmá wa MOA láti gbà padà fún wa.