Wọn ò kì nṣe Olódùmarè, ṣùgbọ́n wọ́n nhùwà bíi pé àwọn ni ó dá ayé! Àwọn ènìyàn máa npè wọ́n ní “Alágbayé” (globalists) nítorí pé àwọn ẹni ibi wọ̀nyí fẹ́ kí gbogbo àgbáyé ó wà lábẹ́ òrùlé kan ṣoṣo, kí ó sì jẹ́ pé àwọn ni ó máa máa ṣe àkóso òrùlé náà!

Ẹ̀mí àṣìtáánì ló ngbénú wọn. Ọ̀dájú ni wọ́n; wọn ò ní ẹran ènìyàn lára wọn; òyìnbó ni wọ́n, ṣùgbọ́ wọ́n ní àwọn aláwọ̀dúdú tí ó nmú iṣẹ́ wọn rinlẹ̀ ní Áfríkà, tí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn dúdú wọ̀nyí sì jẹ́ olórí-orílẹ̀-èdè.

Àwọn ọ̀dájú wọ̀nyí kórira Olódùmarè, ète wọn sì ni pé kí wọ́n ba ayé yí jẹ́ mọ́ Elédùmarè lọ́wọ́! Àṣìtáánì bàbá wọn ni wọ́n nṣiṣẹ́ fún, kò sì sí ibi kan ní àgbáyé yí tí kìí ṣe àti ọ̀dọ̀ wọn lóti ṣàn wá.

Wọ́n kórira ènìyàn dúdú bí ẹni tó kórira ìgbẹ́, àti ẹ̀gbin. Inú nbí wọn sí ènìyàn dúdú, inú nbí wọn sí Olódùmarè. Ọmọ ìparun ni wọ́n. Wọn ò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, wọn ò bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀dá.

Wọ́n kórira Áfríkà; bíi kí Áfríkà ó parun pátápátá ló nṣe wọ́n; ṣùgbọ́n kí gbogbo ilẹ̀ Áfríkà kí ó jẹ́ tiwọn, wọ́n á dẹ̀ ṣe ohunkóhun tí wọ́n bá lè ṣe, láti ri pé èyí wáyé!

Ṣùgbọ́n Ẹlẹ́da wa kò sùn, kìkìdá kí àwa ti máa tẹ̀le ni, a ó sì rí ẹ̀hìn wọn.

Bill Gates nìkan kọ́ o! Wọ́n kàn nlo Bill Gates ni. Wọ́n ní oríṣiríṣi àjọ tí wọ́n nlò láti fi ṣe iṣẹ́ ibi ní àgbáyé.

Ní fọ́nrán kan tí a rí ní àìpẹ́ yí, ọkùnrin Kenya kan sọ pé, àwọn aláyébàjẹ́ yí, ohun méjì ni wọ́n nlépa, kí àwọn lè ṣàkóso ayé, tìpá-tìkúùkù.

Ṣé a mọ̀ pé ebi kìí wọ inú kí ọ̀ràn míì ó tún wọ’bẹ̀.

Democratic Republic of the Yoruba say no to GMO foods and seeds
Ìròyìn Òmìnira Olojoojumọ – Bèrè fún ẹ̀da títí rẹ!

Nítorí èyí, ọ̀nà láti gba GBOGBO ilẹ̀ ní Áfríkà, kúrò lọ́wọ́ onílẹ̀, àti kí ènìyàn má lè dá’ko láì gba àṣe òntẹ̀ wọn, ni wọ́n nwá kiri.

Báwo ni wọ́n ṣe nṣe eléyi? Nípasẹ̀ àwọn tó pera wọn ní ààrẹ àti olórí ìlú káàkiri Áfríkà ni. Ìdí nìyí, tí a níláti ri dájú pé gbogbo ara ni a fi tẹ̀lé Àlàkalẹ̀ fún Ìran Yorùbá, àti Ọmọ-Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) pẹ̀lú Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) èyí tí Olódùmarè ti gbé lè Màmá wa lọ́wọ́, Ìránṣẹ́ Rẹ̀, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, kí á lè ri dájú pé àwọn “alágbayé” kankan kò rí ẹ̀yìn wa mú balẹ̀!

Àwọn “alágbayé” (globalists) yí, àti àwọn oríṣiríṣi àjọ-ẹgbẹ́ tí wọ́n ti dá sílẹ̀, ni wọ́n nlo àwọn olórí-orílẹ̀-èdè ní Áfríkà láti máa fi ìyà jẹ àwọn ènìyàn wọn.

Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ, ní ìlú Kenya, ọkùnrin yí ṣàlàyé pé àwọn “alágbayé” wọ̀nyí ti ríi pé, kí àwọn tó lè ṣe àkóso ìgbé-ayé àwọn ènìyàn, wọ́n ní láti kọ́kọ́ dín iye àwọn ènìyàn náà kù!

Nítorí èrò tó pọ̀ máa ṣòro láti fi tipá ṣe àkóso ìgbé-ayé wọn! Nípa èyí, àwọn ẹni ibi amúnisìn wọ̀nyi, ri pé ohun àkọ́kọ́ tí àwọn ní láti ṣe ni kí àwọn dín iye ọmọ-ènìyàn kù.

Ọ̀nà àti ṣe eléyi, lákọkọ́, sì ni kí onjẹ kí ó máṣe tó fún aráyé. Ẹni tí ó bá ní àkóso onjẹ tí àwọn èèyàn lè rí jẹ, ó ti ní àkóso ìgbésí-ayé àwọn ènìyàn náà níkawọ́ nìyẹn.

Ọkùnrin náà wá sọ pé, ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé àwọn àgbékalẹ̀ tí ìjọba Kenya ti ngbé kalẹ̀ láti bí ọdún mẹ́wa sí òní yí, èyí tó pọ̀jù nínú wọn jẹ́ àgbékalẹ̀ tí ó mú oko-dídá ṣòro fún àwọn àgbẹ̀ lọ́kan-ò-jọkan, tí á wá jẹ́ àwọn oríṣiríṣi àjọ àwọn ẹgbẹ́ tí àwọn “alágbayé” wọ̀nyí ti dá sílẹ̀, nìkan, ni ó máa máa ṣe àkóso ohun tí ènìyàn njẹ sẹ́nu! Hàà.

Ó tún tún-un sọ, ó ní, kókó ohun tí wọ́n nlépa ni kí ọ̀rọ̀ onjẹ-jíjẹ ọmọ-ènìyàn, àti ọ̀rọ̀ oko dídá, kí ó wà ní ìkáwọ́ wọn! Tí ó bá ti wà ní Ìkáwọ́ wọn, lóbátán! Ìgbésí-ayé ọmọ-ènìyàn ti wà ní ìkáwọ́ wọn nìyẹn!

Tìtorí eléyi, ó ní àwọn ẹni ibi wọ̀nyí ti ṣeé débi tó jẹ́ pé, èyí tó pọ̀jù nínú onjẹ tí wọ́n njẹ lóni ní Kenya, onjẹ GMO ni! Bí wọ́n dẹ̀ ṣe nṣe iṣẹ́ ibi wọn káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè nìwọ̀nyẹn.

Ó ní àwọn ìrúgbìn GMO wọ̀nyí, ìkáwọ́ àwọn ẹgbẹ́ àti àjọ tí àwọn “alágbayé” wọ̀nyí ti dá sílẹ̀, ni wọ́n wà, àwọn ni wọ́n nṣe àkóso àwọn ìrúgbìn GMO wọ̀nyí.

Ó tilẹ̀ dárúkọ lára àwọn ẹgbẹ́ àti àjọ náà – àwọn bíi, MONSANTO; CARGIL, àti DUPONT. Àwọn ni wọ́n ni gbogbo irúgbìn ayédèrú tó gba ìgboro kan wọ̀nyí.

The Democratic Republic of the Yoruba Official Information Portal

O ní ìjọba wọn ní Kenya, gẹ́gẹ́bí apẹrẹ, ti gbé òfin síta tó jẹ́ pé irúgbìn ikú tí àwọn aṣekúpani ilé-iṣẹ́ wọ̀nyí nṣe, nìkan ni wọ́n fi àyè gbà kí ẹnikẹ́ni kí ó gbìn ní ìlú Kenya, àti pé tí wọ́n bá rí òun pé òun fún àgbẹ̀ bíi tòun ní irúgbìn àdáyébá, ọ̀ràn ni òun dá lábẹ́ òfin Kenya.

À bẹ́ò ri !? Èyí túmọ̀ sí pé, àwọn òyìnbó amúnisìn wọ̀nyí, nwọlé sí àwọn orílẹ̀-èdè lára nípasẹ̀ àwọn olórí orílẹ̀-èdè náa fúnra wọn!

Àwọn olórí orílẹ̀-èdè náà á wá máa ṣe àwọn òfin ní ìlú wọn, àwọn òfin tí ó fún àwọn “alágbayé” (globalists) wọ̀nyí láti ṣàkóso àti láti máa darí irúfẹ́ àwọn onjẹ tí àwọn ará-ìlú náà lè jẹ; ìrúfẹ́ irúgbìn tí wọ́n le gbìn!

Àwọn orílẹ̀-èdè náà ti rọ́ràn nìyẹn! Wọ́n fẹ́, wọ́n kọ̀, GMO ni wọ́n máa máa jẹ, òun náà ni wọ́n máa máa gbìn! 

GMO kò dẹ̀ ṣeé tún-gbìn! Èyí túmọ̀ sí pé, lọ́dún tó mbọ̀, tàbí nígbàkúgbà tóo bá tún fẹ́ gbin irúgbìn, o níláti padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ilé-iṣẹ́ “alágbayé” wọ̀nyí; iye gọbọi tí ọwọ́ àwọn èèyàn ò ká ni wọ́n dẹ̀ nta àwọn irúgbìn náà ní Kenya báyi!

Ibi tí gbogbo eléyi doríkọ nií pé, ará ìlú kò níí lè dáko mọ́; àwọn ilé-iṣẹ́ globalists wọ̀nyí ni wọ́n á wá kúkú máa dáko ilẹ̀ ará ìlú; lóbátán: ọ́tá ará-ìlú ló wà nídi àrò! Ẹ jọ̀ọ́, irúfẹ́ onjẹ wo ló máa gbé fún ará-ìlú jẹ?

Kìí tún wá ṣe ohun ọ̀gbìn oko nìkan ni o! Àti ẹran ọ̀sìn pàápàá.

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ti gbé òfin kan síta ní Kenya, báyi, gẹ́gẹ́bí ọkùnrin náà ṣe sọ, tí ó fi dandan le pé kò sí ohun tó njẹ́ ilẹ̀ mi leléyi; wọ́n máa máa sanwó lọ́dọọdún ni; ẹni tí kò bá ti lè sanwó, ó pàdánù ilẹ̀ rẹ̀ nìyẹn!

Látàrí pé àwọn àṣìtáánì òyìnbó amúnisìn wọ̀nyí ṣáà fẹ́ kó ènìyàn dúdú kúrò nlẹ̀, kí àwọn gba ayé kan! Bẹ́ẹ̀ náà ni wọn ò ro ire sí ara wọn náà o! Ṣùgbọ́n ti aláwọ̀dúdú yẹn jẹ wọ́n lógún ní pàtàkì.

Kí á má wulẹ̀ jẹ́ kí itọ́ ó gbẹ lẹ́nu torí àti ṣe àlàyé ìwà wèrè, ìwà ìkà, ìwà àìníbẹ̀rù-Ọlọ́run àwọn òyìnbó wọ̀nyí, oun tí ó ṣe pàtàkì fún ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y) ni pé, kí á máṣe ya òpè o! Kí á mọ̀ pé kìí ṣe gbogbo ènìyàn tí a nrí lágbayé yí ni ènìyàn gidi o!

Àwọn amúnisin gbobalists wọ̀nyí fẹ́ ṣàkóso àgbáyé tìpá-tìkúùkù pẹ̀lú gbogbo ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí, a ò dẹ̀ gbọdọ̀ fún wọn ní àyè, bí ó ti wù kó kéré mọ!