Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí ìran Yorùbá, Màmá wa, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin), fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí àwọn agbesùnmọ̀mí, àwọn aninilára, tí wọ́n nṣojú fún ètò-amúnisìn tí wọ́n npè ní Nàìjíríà, tí wọ́n njẹgàba sorí ilẹ̀ wa, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), tí wọ́n nṣe wọ́nran-wọ̀nran; Màmá fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí wọn ní àìpẹ́ yí, nígbàtí wọ́n nbá àwa ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti D.R.Y, sọ̀rọ̀.
Ẹ̀yin agbésùnmọ̀mí wọ̀nyí, ẹ pe ara yín ní gómìnà; Màmá sọ pé ẹ ò mọ nkan tí ẹ nṣe o! Màmá ní, ẹ nba ọjọ́-ọ̀la ìdílé yín jẹ́; àti ọjọ́-ọ̀la àwọn ọmọ-ọmọ yín; àti gbogbo nkan tí ẹ ní; ẹ nbàá jẹ́! Gbogbo nkan tí ẹ njí, tí ẹ nkó, tí ẹ rò pé kò sí bí ẹ ò ṣe jẹ́, MOA sọ pé ó ní àsìkò, àti pé àsìkò yín kò sì pẹ́ rárá.
MOA sọ pé, ẹ̀yin ajẹgàba wọ̀nyí, kílódé tí ẹ ò ro àròjinlẹ̀? Kílódé tí ẹ nro èní nìkan, tí ẹ ò ro ọ̀la. Kílódé tí ẹ ò fi ti ẹlòmíì kọ́gbọ́n? – àwọn tí wọn ò ro ọ̀la, lána, kílódé tí ẹ ò rántí pé báyi-báyi mà ni ìgbẹ̀yìn wọn-ọ̀n.
Màmá sọ pé, kò sí ọ̀rọ̀ lọ́rọ̀ yín o! – kí ẹ yára gbọ́! Màmá wá sọ fún àwa I.Y.P ti D.R.Y, pé, Ọlọ́run tí ó nrin ìrìn yí, ó ní’dí tó ṣe nṣeé bí ó ti nṣeé yí o! Ọlọ́run ló ni ìgbà àti àsìkò, Òun ló sì mọ àkókò tí ó dára jù. Òun ló mọ ọ̀nà tí Ó máa gbe gbà; Òun ló mọ bí ó ṣe máa ṣé, tí kò níí ní ìnira, tó jẹ́ ìrọ̀rùn. A ti bèrè fún ìrọ̀rùn; a ti bèrè fún Àlááfíà.
Nígbàtí àwọn amúnisìn, tí wọ́n to ètò-ìmúnisìn wọn tí wọ́n pè ní Nàìjíríà, ṣé àwọn ajẹgàba wọ̀nyí wà níbẹ̀ nígbà náà ni? ṣùgbọ́n Ọlọ́run rí gbogbo nkan tí wọ́n ṣe nígbà náà lọ́hun.
Màmá wá sọ fún ẹ̀yin tí ẹ pera yín ní gómìnà, tí ẹ ò kì nṣe gómìnà D.R.Y, ṣùgbọ́n tó jẹ́ ajẹgàba Nàìjíríà ni ẹ nṣiṣẹ́ fún; wọ́n ní, tó bá wù yín, kí ẹ fi sùúrù kúrò ní’bi tí ẹ jẹgàba sí yẹn (a sì ti sọ fún yín, ọ̀nà láti fi sùúrù kúrò); wọ́n ní tí ó bá sì wù yín, kí ẹ jẹ́ kí ọwọ́ líle kó mú yín kúrò; ṣùgbọ́n ohun tí ó dájú ni pé, ÀSÌKÒ YÍN KÒ PẸ́ MỌ́.