Ajá tí yóó sọnù kìí gbọ́ fèrè ọdẹ ni ọ̀rọ̀ ìjọba ajẹgàba nàìjíríà, tí Sanwó-Olú nṣojú fún ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).

Ìròyìn tí a tún gbọ́ báyìí ni pé wọ́n ti bu ọwọ́ lu àkànṣe iṣẹ́ olóṣù mẹ́fà kan, oní bílíọ̀nù méjìlélógójì náírà, tí wọ́n gbé fún àwọn agbaṣẹ́ṣe kan tí wọ́n gbé wá láti orílẹ̀ èdè China tí wọ́n jọ npà’dí àpò pọ̀ ja ara ìlú lólè, láti tún afárá Òkè-Odò Kẹ́ta (Third Mainland Bridge) tó bàjẹ́ ṣe àti ojú ọ̀nà Adeniji sí Falọmọ, ní Ìpínlẹ̀ Èkó tí ó jẹ́ ilẹ̀ Democratic Republic of the Yoruba, tí kìí ṣe ará apaná ọ̀go nàìjíríà mọ́.

Sanwó-Olú, kò sí àkókò fún ọ mọ́, àwọn ìgbésẹ̀ tó ń gbé yí ti bọ́s’órí fún ọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ò ń tàpá sí òfin àgbáyé.

Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yorùbá D.R.Y) ti kúrò lára ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà láti ogúnjọ́ oṣù Bélú ẹgbàáọdúnóléméjìlélógún, bẹ́ẹ̀ni a ti ṣe ìbúra-wọlé fún olórí ìjọba adelé wá, bàbá wa Mobọ́lájí Ọláwálé Akinọlá Ọmọkọrẹ, ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́rìnlélógún.

Nítorí náà, gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ti wà lábẹ́ àkóso ìjọba D.R.Y, a kìí se ara ìlú aríremáse nàìjíríà mọ́. 

O ń jẹ gàba lórí  ilẹ̀ Yorùbá lẹ́yìn tí a ti ní ìjọba tiwa. Mọ̀ dájú pé ohunkóhun tí o bá ṣe láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún lórí ilẹ̀ D.R.Y, o máa ro ẹjọ́ rẹ̀ níwájú àwọn tó ju àwọn bàbá ìsàlẹ̀ rẹ lọ.

Ìran Yorùbá ti bọ́ lọ́wọ́ amúnisìn, àwa ọmọ aládé ti di òmìnira.

Democratic Republic of the Yorùbá latest news updates 29/09/2024