Ọkùnrin Ìgbò kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Emeka Madu, pẹ̀lú àwọn ọmọ Ìgbò ẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́rin, ní ìlú Ìkọ̀tún ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) wa yí, ni a rí fọ́nrán bí ó ṣe nṣe àwọn oògùn nínú ilé àlàpà, tí òògùn náà sì l’ewu.
Ìyẹn tilẹ̀ kọ́ ni wàhálà, bí kò ṣe ti àwọn tí a ò bẹ̀ ní’ṣẹ́, ìyẹn àwọn ọlọ́pa Nàìjíríà, tí wọ́n nṣe kùrùkẹrẹ sọ òyìnbó òfò níbẹ̀. Ìgbéraga Nàìjíríà mà pọ̀ o!
A ní kí ẹ kúrò lórí ilẹ̀ wa, ẹ nsọ òyìnbó tó túbọ̀ máa kó bá yín. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀sín yín ṣe máa pọ̀ tó ní àìpẹ́ yí. Nàìjíríà, kúrò lórí ilẹ̀ wa, a ò bẹ̀ yín ní’ṣẹ́!
Ọgbọ́n, Ìmọ̀ àti Òye àwọn Babanlá wa, pẹ̀lú ewé àti egbò tí Ọlọ́rún jogún fún ilẹ̀ wa, ṣì wà síbẹ̀ fún ìmúláradá àwa ìran ọmọ aládé. Ìjọba Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá kò ní f’àyè gba ìlúk’ilú tàbí ẹnikẹ́ni láti ṣ’àkóso òògùn tàbí oúnjẹ àwa Indigenous Yorùbá People (I.Y.P).
Adúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarè fún àtìlẹyìn rẹ̀ fún Màmá wa, Olóyè Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá, fún àṣeyọrí iṣẹ́ Orilẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y).
Gbogbo àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), ẹ jẹ́ kí a fi ọkàn wa balẹ̀, Ọlọ́run Olódùmarè ti gba ilẹ̀ wa fún wa.