Ìgbàkúgbà tí olórí kan bá ti ń ṣe dáradára fún àwọn orílẹ̀-èdè rẹ̀ ní Áfríkà, ṣe ni àwọn òyìnbó amúnisìn máa ń ṣekúpa irúfẹ́ olórí bẹ́ẹ̀, tàbí kí wọ́n ba ìlú jẹ́ mọ́ọ lọ́wọ́.
Ọkùnrin aláwọ̀dúdú kan ni ó sọ ọ̀rọ̀ yí, ní orí ẹ̀rọ Ayélujára TikTok, ìkànnì @africaonepeace.
Ó wá dárúkọ̀ lára àwọn tí ó sọ pé àwọn amúnisìn ló ṣe okùnfà ikú wọn tàbí tí wọ́n ba ọrọ̀-ajé ìlú náà jẹ́ mọ́ọ lórí.
Lára àwọn tí ó dárúkọ wọn ni Muamar Gadaffi ìlú Libya, Thomas Sankara ìlú Burkina Faso, Kwame Nkrumah ìlú Ghana, Julius Nyerere ìlú Tanzania, Samora Machel Ìlú Mozambique, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ọkùnrin náà sọ pé ní kété tí olórí kan bá ti fẹ́ yọ ẹ̀wọ̀n ìmúnisìn kúrò ní ọrùn orílẹ̀-èdè rẹ̀, òyìnbó-amúnisìn tí ó jẹgàba lórí ìlú náà tẹ́lẹ̀, èyí tí ò sì ntẹ̀síwájú láti gbà ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí ṣe ìmúnisìn náà, tí ó wá ti sọ ara rẹ̀ di ọlọ́pa lórí ìṣèlú orílẹ̀-èdè náà, á wá bí wọ́n ṣe màa mú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò ní orí ìlú náà.
Ojú wa ti là báyi, ọmọ-ìbílẹ̀ Yorùbá, a sì dúpẹ́ pé níbi ti a dé yí, Màmá wa, Ìránṣẹ́ Olódùmarè, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá, fi yé wa ìdí tí a kò gbọ́dọ̀ tún gba ẹnikẹ́ni láàyè láti mú wa sínú oko-ẹrú kankan! A ti bọ́! Ipá wọn, kò leè ká wa mọ́!