Àtunbọ̀tán ìwà ìkà àti ìjẹgàba àwọn amúnisìn ṣi kù lára àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ilẹ̀ Yorùbá nítorí pé, wọ́n ti jogún ìwà ọ̀dájú yìí lára àwọn amúnisìn, tí wọ́n tan àwọn bàbá nla wa jẹ.

Lẹ́hìn ọ̀rẹyìn ni àwọn amúnisìn rò wípé, óṣeṣe fún wọn láti gba ìlẹ̀ àwa ọmọ Yorùbà fún ara wọn, tí wọ́n si pàdí àpòpọ̀ mọ́ àwọn àjòjì láti gba ilẹ̀ wa, látàri bi wọn ṣe ń gbèrò àti pa wá lórí ilẹ̀ wa.

Nípasẹ̀ èròngbà wọnyìí ni àwọn amúnisìn fi iṣẹ́ dé tòrutòru rán àwọn Fulani tó jẹ́ àjòjì bákannáà lórí ilẹ̀ wa láti ma fikú pa àwa ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá díẹ̀díẹ̀ ní oríṣiríṣi ọ̀nà.

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn Fulani tó jẹ́ ohun èlò ìjẹgàba fún àwọn amúnisìn lórí ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá kò dẹ́kún àti máa fi Màálù jẹ oko lórí ilẹ̀ wa. Haa! ìyà oúnjẹ ni wọn tún nlò látí dojú ìjà kọ ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá pẹ̀lú títi bodè tó wà láarín orílẹ̀ èdè Yorùbá àti orílẹ̀ èdè Benin.

Màmá wa, ìyá àafin Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla (MOA) ní Olódùmarè lo láti gba ìran Yorùbá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aninilára amúnisìn, nítorí pé, Ó fún ìyá wa MOA ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti òye láti rí ojúrere gbà lọ́wọ́ àwọn àjọ àgbááyé, láti gbà ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) kúrò nínú wàhálà àwọn amúnisìn.

Nítorí náà, ọpẹ́ lóyẹ kí gbogbo ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá máa da lọ́wọ́ Olódùmarè àti Màmá wa MOA fún òmìnira tòótọ́ àti iṣèjọba-ara-ẹni tó péye fún gbogbo ìran Yorùbá.

Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y) ti dúró nítorí náà kò sí ohun tí amúnisìn àti àwọn irinṣẹ́ wọn leè ṣe si.

Ominira yoruba daily news | the newest nation in the world 2024