Ọ̀rọ̀ agbaṣẹ́ṣe jẹ́ èyí tí ó ṣe pàtàkì ní orílẹ̀-èdè.
Ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y), kò sí àyè fún ìwà ìbàjẹ́ kankan.
Fún àpẹẹrẹ, tí agbaṣẹ́ṣe bá gba iṣẹ́ pópónà tàbí ilé-kíkọ́, gẹ́gẹ́ bí màmá wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ọlá Onítirí-Abíọ́lá, ti fi yé wa pé gbogbo ohun tí ó níí ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ náà ni yóò wà ní ìta gẹ́gẹ́bíi orúkọ agbaṣẹ́ṣe, nọ́mbà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀, àkókò tí iṣẹ́ náà yóò parí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Gbogbo ará ìlú, pàápàá àwọn tí ó bá jẹ́ pé agbègbè wọn ni iṣẹ́ yí ti ń wá’yé, ni ó ní ànfààní láti pe agbaṣẹ́ṣe tí ohunkóhun bá rú wọn lójú nípa bí iṣẹ́ náà ṣe nlọ. Agbaṣẹ́ṣe kò dẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣàì dá wọn lóhùn, pẹ̀lú ohùn ọmọlúàbí sì ni, nítorí pé Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yorùbá People, I.Y.P) gan-an gan ni Ìjọba, tí àwọn tí a yàn sípò jẹ́ aṣojú fún.
Èyí túmọ̀ sí pé, iṣẹ́ tí a gbé fún agbaṣẹ́ṣe ti di iṣẹ́ tí gbogbo ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá máa bojútó, tí kò ní sí pé agbaṣẹ́ṣe kankan máa yàn wá jẹ.
Agbaṣẹ́ṣe tí kò bá parí iṣẹ́ ní àkókò tí ó ṣàdéhùn pẹ̀lú àwa ọmọ Yorùbá, yóò san owó ní ijọ́ kọ̀ọ̀kan tí iṣẹ́ náà bá fi pẹ́, fún ìjọba D.R.Y.
Bẹ́ẹ̀ náà ni agbaṣẹ́ṣe tí ó kó àwọn òṣìṣẹ́ lọ síbi iṣẹ́ níláti ṣe ètò adójútòfò fún àwọn òṣìṣẹ́ náà, ní àkókò iṣẹ́ ọ̀ún.
Pàtàkì ọ̀rọ̀ yí ni láti leè jẹ́ kí a mọ̀ pé àwa ará ìlú (ojúlówó ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá) ní àṣẹ láti ṣe àmójútó àti àyẹ̀wò fún gbogbo ohun tí agbaṣẹ́ṣe bá nṣe ní orílẹ̀-èdè D.R.Y, kí ó má báà sí ìyànjẹ tàbí ìwà ìbàjẹ́ kankan.