Kò sí àní àní pé Bill Gates lo ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé ìtajà ìgbàlódé ńlá ńlá tí wọ́n ti ń ta àwọn awúrúju adìẹ káàkiri àgbáyé.

A ríi èyí kà nínú ìròyìn kan lórí ayélujára X, wípé Amerika ti f’ọwọ́ sí ṣíṣe adìẹ àtọwọ́dá láti yàrá ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. 

❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP). (ÌKÉDE… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)
Lab grown chicken just gets approved in the US

Èrèdí èyí ni pé, wọn ń fẹ́ láti gbé lùkù lùkú jáde, tí ó máa gbilẹ̀ láti ara àwọn ohun ọ̀sìn abìyẹ́, pàtàkì jùlọ, adìẹ, èyí tí wọ́n máa fi ṣe àwáwí láti lè fi àwọn abìyẹ́ tí ó jẹ́ ojúlówó tí kò ṣàìsàn ṣ’òfò nípa pípa’rọ́ pé àwọn ni wọ́n ní àìsàn lùkú lùkú, kí wọ́n bàa lè ní ànfàní láti gbé abẹ́rẹ́ kalẹ̀ fún ará ìlú láti máa gbáà, pé àwọn ń fi ṣe àjẹsára fún ará ìlú gẹ́gẹ́ bíi ti ìgbà Covid-19.

Ǹjẹ́ a ti’lẹ̀ mọ ìdí tí Bill Gates àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́ 

rẹ̀ fi ń gba gbogbo ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí wọ̀nyí tí ó fí ń dààmú gbogbo àgbáyé bayìí? Ṣé ó ti gbàgbé pé Ọlọ́run tí Ó dá wọn ni O dá gbogbo ènìyàn tí ó kù ní àgbáyé ni? Tí wọ́n fi ń bá Olódùmarè figagbága?. 

Ìdí ni pé, wọn ti pinnu láti dín iye ènìyàn tí ó wà ní gbogbo àgbáyé kù sí ìlàjì. 

Ṣùgbọ́n, kí Bill Gates àti  àwọn tí wọ́n jọ ń ṣe iṣẹ́ ibi wọ̀nyí lọ mọ̀ pé, àwọn máa pàdé Ọlọ́run ní ẹsẹ̀ kò gbèjì, níbi tí wọn kò ti ní ríbi yà sí, tí wọ́n sì máa bá ìparun wọn pàdé láì pẹ́. 

Ìkìlọ rèé o fún gbogbo àwa ọmọ Orílẹ̀-èdè Olómìnira Tiwantiwa Tí Yorùbá, pé kí oníkálukú wa mọ ibi tí a ó ti máa ra ohun tí a bá máa jẹ́ sínú wa, àti kí á máa kíyèsí oúnjẹ tí a máa jẹ o, nítorí ewu ti wà lóde o.

Ṣùgbọ́ ti àwa I.Y.P yàtọ̀ nítorí gẹ́gẹ́bi ọ̀rọ̀ màmá wa, ìránṣẹ́ Olódùmarè fún òmìnira àwa ọmọ Yorùbá Olóyè Modúpẹ́ọlá Onitiri-Abiọla, ní orílẹ̀-èdè wa, Democratic Republic of the Yorùbá, a ó pèsè ohun tí a nílò, a ó sí lo ohun tí a bá pèsè, èyí túmọ̀ sí pé àwọn oúnjẹ ayédèrú yìí kó ní rí ààyè níluu wá, ohunkóhun tí ó bá fẹ́ wọlé sí Orílẹ̀-èdè wa máa la àyẹ̀wò fínífíní kọjá, nítorí ọmọ aládé kìí jẹ ìjẹkújẹ.

Democratic republic of the Yoruba ominira new update | Yoruba Nation | Newest Nation in Africa, World