Àwọn ọmọ-ẹgbẹ́-òṣèlú REPUBLICAN ní Amẹ́ríkà, tí wọ́n jẹ́ Ọmọ-ẹgbẹ́ Ìgbìmọ̀-aṣòfin ti sọ̀rọ̀ sí’ta, wọ́n ní ájọ-àgbáyé, lápá kan, àti àjọ ètò-Ìwòsàn ní Àgbáyé (W.H.O), lápá kan, fẹ́ kó gbogbo àgbáyé sí abẹ́ ìṣèjọba kan ṣoṣo, wọ́n ní àwọn ò sì ní gbà.
Wọ́n sọ bí ìjọba-Joe-Biden, àti Kamala Harris, igbá-kejì rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ olóṣèlú ti “Democrat” ṣe ń pàdí-àpò-pọ̀ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ibi wọ̀nyí.
Wọ́n sọ pé àwọn “alágbayé” ló wà ní’dí ọ̀rọ̀ yí àwọn t’ó jẹ́ pé wọ́n fẹ́ wó agbára ìṣèjọba-ara-ẹni ìlú Amẹ́ríkà, tí wọ́n sì fẹ́ kí China ó ṣe àkọlù sí ìṣèjọba-ara-ẹni Amẹ́ríkà.
Wọ́n ní, bí wọ́n ṣe ṣe ní’jọ́ yẹn l’ọhún náà nìyẹn, tí àwọn alágbayé wọ̀nyí ní ìlú Amẹ́ríkà pàdí àpò pọ̀ pẹ̀lú China, láti da àrùn covid-19 sí’ta, tó sì jẹ́ pé títí di òní, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n dènà gbogbo ìgbésẹ̀ tí Amẹ́ríkà ń gbé, láti wá’dí kúlẹ̀-kúlẹ̀ ohun tó fa covid 19.
Gẹ́gẹ́bí àwọn aṣojúṣ’òfin ọmọ-ẹgbẹ́ Republican wọ̀nyí ní ìlú Amẹ́ríkà ṣe sọ, laìpẹ́ yí ni àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé àbá kan kalẹ̀ nínú ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣ’òfin wọn, tí àwọn sì nl’erò pé ilé-aṣòfin-àgbà wọn á ṣe bákan-náà, pé kí Amẹ́ríkà yọ ara rẹ̀ kúrò nínú àjọ-ìwòsàn àgbáyé (W.H.O), àti pé kì í ṣe kí ó yọ ara rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n, kó má ṣe fi ẹyọ dọ́là kan t’ó kéré jù, ṣ’ọwọ́ sí W.H.O mọ́, gẹ́gẹ́bí ìtọrẹ-àánú fún àwọn aláyébàjẹ́ náà.
Wọ́n sì ń retí pé kí àwọn ilé-aṣòfin àgbà wọn náà gbé irú àbá àti òfin yí kalẹ̀, kí ó lè di òfin ìmúṣẹ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́rikà. Ìdí ni pé W.H.O ti wá fẹ́ sọ ara rẹ̀ di ìjọba lórí gbogbo àgbáyé, tí kò sì sí ẹnikan-kan ní ìlú Amẹ́ríkà tí ó dìbò yan ẹnikẹ́ni nínú wọn láti máa ṣ’àkóso ìlú Amẹ́ríkà.
Wọ́n ní, ṣe ni W.H.O, pẹ̀lú gbogbo ìgbéraga, ìkọjá-àyè tí wọ́n ń ṣe káàkiri àgbáyé, fẹ́ sọ ara wọn di ìjọba lórí àwọn ìjọbá tí àwọn ara-ilú yàn, àwọn ò sì ní gbà, kí irú èyí ṣẹlẹ̀ sí ìlú Amẹ́ríkà, nítorí orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni ni Amẹ́ríkà, àti pé, ìjọba Amẹ́ríkà nìkan ni ó ní àṣẹ lórí àwọn ará-ìlú Amẹ́ríkà, kìí ṣe W.H.O.
Kìí wá ṣe ìyẹn nìkan, wọ́n ní àwọn Àjọ-Àgbáyé pàápàá ti nkọjá àyè wọn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésẹ̀ tí ó jẹ́ pé láìsí àṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri àgbáyé fún’ra wọn, Àjọ-Àgbáyé á kàn fi ipá já wọ orílẹ̀-èdè k’orílẹ̀-èdè láti pàṣẹ ohun tí wọ́n máa ṣe tàbí má ṣe.
Wọ́n ní gbogbo ìgbésẹ̀ wọ̀nyí ti W.H.O àti Àjọ-Àgbáyé ń gbé kò ṣẹ̀yìn àwọn “alágbayé” , àwọn tí ọlọ́run kò yàn, tí wọ́n sọ ara wọn di olùṣàkóso àgbáyé pẹ̀lú ipá, tí wọ́n sì fẹ́ kó gbogbo àgbáyé sí abẹ́ òrùlé kan-náà, kí wọ́n lè gba agbára-ìṣèjọba-ara-ẹni kúrò lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ipá, kí àwọn wá máa ṣe olúdarí gbogbo àgbáyé gẹ́gẹ́bí ìjọba kan ṣoṣo.
Àwọn gẹ́gẹ́bí ọmọ-ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣ’òfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà, tí ó jẹ́ ti Ẹgbẹ́ òṣèlú Republican, kò ní fàyè gba ìgbésẹ̀ yí.
Wọ́n wá sọ pé, ìlú China ti mú W.H.O s’ábẹ́, àwọn ò dẹ̀ ní gbà kí ó wá jẹ́ pé China tí kò ní ìfẹ́ Amẹ́ríkà á wá máà tipasẹ̀ W.H.O ṣe alákoso Amẹ́ríkà!
Ọ̀rọ̀ ré o! ọmọ ìbílẹ̀ Yorùba (Indigenous Yoruba People, I.Y.P) ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y). Ọ̀rọ̀ yí kò rújú rárá, ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ni pé, àwọn “alágbayé” yí, gẹ́gẹ́bí a ṣe mọ̀ l’ati ìgbà tí ojú wa ti bẹ̀rẹ̀ sí là wọ́n fẹ́ ní gbogbo àgbáyé ní ìkáwọ́ wọn!
Àwọn ní wọ́n á sọ pé wàhálà kan ti wà (tí a ò mọ̀ nkankan nípa rẹ̀; àwọn nìkan ni wọ́n máa nrí oríṣiríṣi ìríkúri tí wọ́n máa nrí) wọ́n á sọ pé nǹkan báyi ni gbogbo-ayé gbọ́dọ̀ ṣe, tí kò sì ní sí ìjọba orílẹ̀-èdè kan-kan t’ó lè sọ pé “bíi ti báwo!” L’ó wá túmọ̀ sí pé wọ́n ti gba agbára ìṣèjọba-ara-ẹni kúrò lọ́wọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè, àwọn ni wọ́n á wá máa pàṣẹ lórí gbogbo àgbáyé.
Èyí jẹ́ ÈÈWỌ̀ pátápátá gbáà fún Ìran Yorúbá! Gẹ́gẹ́bí ìyá wa, Màmá Ìran Yorùbá, Olùgbàlà tí Ọlọ́run Olódùmarè rán sí wa, Ìyá-Ààfin Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá ṣe máa ń sọ pé a ò ní kúrò nínú oko-ẹrú kan bọ́ sí òmíràn, àti pé lẹ́yìn Ọlọ́run Olódùmarè, Yorùbá ni Àkọ́kọ́; Àjọ-Àgbáyé kọ́ ni ìjọba. W.H.O kò ní agbára lórí ìjọba wa.
Ẹ jẹ́ kí á rántí ohun tí Màmá wa ti sọ pé, kí àwọn Ọ̀dọ́ Ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (I.Y.P) dìde, kí wọ́n ri pé àwọn dáàbò bo ìṣèjọba-ara-ẹni Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (D.R.Y).