Tí a bá nsọ pé ètò-amúnisìn ni ibi tí wọ́n npè ní nàìjíríà; tí a bá nsọ pé ìkà ni wọ́n, tí a bá nsọ pé ìparun ọmọ Yorùbá ni wọ́n nwá, a mọ bó ṣe nlọ o, a sì mọ ìdí tí a fi sọ bẹ́ẹ̀!
Ti Yorùbá ló kàn wá o, ìdí nìyẹn tí ìgbékalẹ̀ wa lórí ọ̀rọ̀ yí dá lé ọmọ Yorùbá.
Ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ni ibi tí a gbọ́ pé ọ̀rọ̀ yí ti ṣẹlẹ̀ o, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn náà sọ pé ọdún mẹ́rinlá sẹ́yìn, èyíinì, ẹgbàá ọdún ó lé mẹ́wa, nígbà tí a ṣì wà pẹ̀lú wọn ní ètò-amúnisìn tó njẹ́ “nàìjíríà” ni ó ti ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n ilẹ̀ Yorùbá ni, àwọn nàìjíríà tí ọ̀rọ̀ náà ti abẹ́ àkóso wọn ṣẹlẹ̀, àwọn náà ló ṣì njẹgàba lórí ilẹ̀ wa, D.R.Y, báyi, tí wàhálà tí ọ̀ràn náà dá sílẹ̀ nígbà náà lọ́hun sì pàpà wà nílẹ̀ títí di ìsiìyí tí ìròyín tí a gbọ́ nípa rẹ̀ fi jáde, báyi, gẹ́gẹ́bí fọ́nrán tí a rí lórí ayélujára ní yàjóyàjó báyi ṣe sọ.
Ọ̀dọ́mọkùnrin kan ni o! Àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì nsọ Yorùbá lẹ́nu nínú fọ́nrán náà tí a rí. Wọn ò kì nṣe olówó; wọn ò kì nṣe bọ̀rọ̀kìní; wọ́n ṣe aláìní dé’bi pé nígbàtí ọmọ wọn ọ̀ún tiraka tó jáde fásitì, wọn ò tilẹ̀ rí owó lọ́ ṣe ayẹyẹ ìjáde-gboyè (graduation) ní fásitì náà.
Ẹ̀kọ́ ìwòsàn, tí a tún máa npè ní ẹ̀kọ́ oníṣègùn (Medicine) ni ọmọkùnrin náà kọ́.
Ní àdúgbò wọn, níjọ́ náà lọ́hun, gẹ́gẹ́bí wọ́n ṣe sọ nínú fọ́nrán yí, ni ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti ṣẹlẹ̀ o, tí wọ́n sì wá fi ẹ̀sùn kan ọmọkùnrin náà pé ó jí ẹdìyẹ!
Nígbàtí ọlọ́pa nàìjíríà dé’bẹ̀, ọmọkùnrin yí sọ pé òun ò mọ nkankan nípa ẹdìyẹ; àwọn ara-àdúgbò sọ pé kó tilẹ̀ sá kúrò ní’bẹ̀ ná, ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin yí sọ pé òun ò lè máa sá níwọ̀n-ìgbà tí ọkàn òun mọ́, tí òun ò mọ nkankan nípa adìyẹ. Bí ọlọ́pa ṣe múu lọ mànìyẹn o!
Ohun tí ó wá ṣe’ni ní kàyéfì ni pé, gẹ́gẹ́bí a ṣe gbọ́ nínú fọ́nrán náà, nígbàtí adájọ́ nàìjíríà máa dá ẹjọ́ náà, ẹjọ́ ikú ní wọ́n dá fún ọ̀dọ́mọkùnrin yí o! Báwo ni ẹ̀sùn jíjí-adìyẹ, yálà ó jẹ́ òtítọ́ tàbí kìí ṣe òtítọ́, báwo ló ṣe jẹ mọ́ ìdájọ́-ikú? Ṣé kò kúkú sí oríṣiríṣi nkan tí kò lè ṣàì ṣẹlẹ̀ ní ìlú agbésùnmọ̀mí nàìjíríà!
Ọdún mẹ́rinlá nìyí o! – tí ọmọkùnrin yí ti wà ní ọgbà-ẹ̀wọ̀n ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, tí ó nretí ijọ́ tí wọn máa wá pe òun láti lọ fi okùn-ikú sí òun lọ́rùn, tí wọ́n máa yẹ’gi fun, látàrí ẹ̀sùn jíjí adìyẹ tí ó sọ pé òun ò tilẹ̀ mọ̀ nípa ẹ̀!
Ọmọ Yorùbá, ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ọ̀rọ̀ ré o! Ohun kan ni àwa mọ̀, ìyẹn ni pé, ní kété tí ìṣàkóso-adelé wa bá ti wọlé sínú sẹkitéríàtì báyi, ní àìpẹ́ ní àìjìnà pẹ̀lú agbára Èdùmarè, Ẹlẹ́da Ìran Yorùbá, lára ohun àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ṣe, yàtọ̀ sí mímú kí onjẹ kí ó wà káàkiri D.R.Y, lára ohun àkọ́kọ́ ni títú gbogbo ẹlẹ́wọ̀n àti àwọn tí ó wà ní àtìmọ́lé, sílẹ̀, káàkiri gbogbo ìpínlẹ̀ méjèèje Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y).
Gẹ́gẹ́bí ìyá wa, Olùgbàlà tí Olódùmarè rán sí ìran Yorùbá, Modúpẹ́ Onítirí-Abíọ́lá (Olóyè Ìyá-Ààfin) ṣe sọ, kò sí nkan tó kan D.R.Y pẹ̀lú báwo ni wọ́n ṣe dé ẹ̀wọ̀n tàbí àtìmọ́lé; gbogbo wọn, pátá, pátá ni D.R.Y máà tú sílẹ̀ ní kété lẹ́yìn tí ìṣàkóso wa bá ti wọlé sí sẹkitéríátì wa gbogbo.
Màmá wá sọ pé, àwọn tí ó bá jẹ́ I.Y.P (ọmọ ìbílẹ̀ Yorùbá) ti D.R.Y nínú wọn, ètò ti wà nílẹ̀ fún àwọn yẹn.
Ṣùgbọ́n, ṣé àwọn ajẹgàba wọ̀nyí, ti ṣetán àtubọ̀tán ìjẹgàba wọn? Wọ́n ṣetán wọn ò ṣetán, ó ndúró dè wọ́n!
Gbogbo ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá (Indigenous Yoruba People, I.Y.P), ti Democratic Republic of the Yoruba (D.R.Y), ọjọ́ náà fẹ́rẹ̀ dé o! Ọjọ́ àjọyọ̀ wa, fún Ìgbàlà nlá tí Olódùmarè fún wa, tí a fi bọ́ lóko-ẹrú. Gẹ́gẹ́bí màmá wa ṣe sọ, àwọn ìṣàkóso-adelé wa á ti wà nínú oríkò-ilé-iṣẹ́ ìṣàkóso wa gbogbo, nígbàtí a bá nṣe àjọyọ̀ wa. A kú ojú l’ọnà.