Olórí Àjọ Ìwòsan ní Àgbáyé ti sọ̀rọ̀ síta nípa àjàkálẹ̀ ààrùn mpox, èyí tí wọ́n sọ pé ó ti ntàn síta kọjá orílẹ̀-èdè Congo, tí wọ́n dẹ̀ nrò pé bóyá ó túbọ̀ lè máa tàn káàkiri Áfríkà àti kọjá Áfríkà pàápàá.
Ó ní òun ti pinnu láti gbé ìgbìmọ̀ kan dìde tí ó máa gba òun ní’yànjú bóyá ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ohun tí ó gba àmójútó èyí tí gbogbo àgbáyé máa da ọwọ́ papọ̀ láti ko ojú rẹ̀.
Orí ẹ̀rọ ayélujára ni a ti rí ìròhìn yí. L’apá kan, àwa gẹ́gẹ́bí ọmọ Ìbílẹ̀ Yorùbá, mọ rírì ìwòsàn tó péye. Lọ́nà kéjì, ẹ̀wẹ̀, ohun tí ó ti ṣe èèyàn lẹ́ẹ̀kan rí, tí kò sì mú rere wá fún ẹni ọ̀ún, ó di dandan kí á ṣọ́ra fún irúfẹ́ ohun bẹ́ẹ̀.
Dájúdájú, a mọ̀ pe ìjọba Orílẹ̀-Èdè wa, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, máa ṣe ìlànà fún wa nípa ohunkóhun tí ó jẹ mọ́ ti ìlera-ara; nítorí èyí, ẹ má ṣe jẹ́ kí á bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohunkóhun tìtorí pé wọ́n sọ bẹ́ẹ̀ láti ìta wa. Ohun tí Orílẹ̀-Èdè D.R.Y bá ti sọ, òun ni kí a tẹ̀lé.
Ìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì ni pé, Olódùmarè nìkan ló mọ kíni kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà gan-an.
Bí wọ́n ṣe sọ̀rọ̀ HIV níjọsí nìyẹn; àsẹ̀yìn wá, àsẹ̀yìn bọ̀, tí a wá ríi pé ìpalára aláwọ̀dúdú ni wọ́n nwá; bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n gbé EBOLA dé, tí wọ́n pariwo ẹ̀ títí; a dúpẹ́ pé Ẹlẹ́da wa kó wa yọ.
Ìgbà tó yá ni wọ́n tún bọ́ sorí Covid, tí ó sì jẹ́ pé lórí kí ìparun ó dé bá àwọn èèyàn, ní pàtàkì, aláwọ̀dúdú, ni; ṣùgbọ́n Olódùmarè kó wa yọ. À ò lè gbára lé ohunkóhun tí wọ́n bá nsọ!
Ta ló mọ̀ bóyá àwọn aṣekúpani tí wọ́n nwá ibi fún aláwọ̀dúdú ni ó tún wà ní’dí ọ̀rọ̀ mpox yí? Nítorí náà, ọmọ Yorùbá, ẹ má ṣe sáré lọ máa ṣe ohunkóhun láì jẹ́ pé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ni ó gbé ọ̀rọ̀ jáde fún wa, ohun tí a máa ṣe.