Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ ajá t’ó fẹ́ sọnù ni ọ̀rọ̀ Nàìjíríà, kò níí gbọ́ fèrè ọdẹ!
Òwe Ìkìlọ̀ Yorùbá
A tún ti gbọ́ ìròyìn míràn tí ó fi hàn gbangba wípé Nàìjíríà ṣì pàpà nka ilẹ̀ Yorùbá mọ́ ìlú Nàìjíríà, l’ẹhìn ìgbà tí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ti di orílẹ̀-èdè aṣe’jọba-ara-ẹni!
Èyí ni ó jẹ yọ nínú ìròhìn kan tí a rí l’orí ẹ̀rọ ayélujá’ra ní ọjọ́ kárun-dín-l’ogún oṣù òkúdù (èyíinì, oṣù kẹ́fà) ọdún yí, nínú èyí tí Ọ̀gá àwọn ọmọ ogun Orílẹ̀ ní ìlú Nàìjíríà, èyíinì, Taoreed Lagbaja, sọ wípé ara iṣẹ́ tí àwọn ọmọ ológun Nàìjíríà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já’dé ní’bi ìkọ́ṣẹ́ ológun Nàìjíríà, wípé ara iṣẹ́ tí wọ́n máa ṣe ni kí wọ́n dáàbò bo ohun tí ó pè ní àwọn ohun-ìní Nàìjíríà tí ó wà ní ibi tí ó pè ní “South West,” tí èyí sì jẹ́ orúkọ àpèjúwe tí wọ́n npe ìpínlẹ̀ mẹ́fà l’ara ìpínlẹ̀ méje ti Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa tí Yorùbá, làì b’ọ̀wọ̀ fún jíjẹ́ tí Orílẹ̀-Èdè Yorùbá jẹ́ aṣè’jọba-ara-rẹ̀!
Ká Ìròyìn: Ìjọba Agbésùnmọ̀mí Nka Yorùbá Mọ́ Naìjíría! Hábà!
Bẹ́ẹ̀ náà ni Lagbaja sọ wípé, l’ara iṣẹ́ àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà tuntun yí ni wípé, wọ́n á d’ojú kọ ọ̀rọ̀ ìkọlù l’aàrin àwọn darandaran àti àwọn àgbẹ̀ ní ibi tí Nàíjíríà npè ní “North Central” ṣùgbọn tí wọ́n máa nka Ìpínlẹ̀ Ìṣejoba Ọ̀yọ́ (Old Oyọ́ Empire) mọ́, tí èyí kò sì rí bẹ́ẹ̀, nítorí l’ara Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá ni Ìṣè’jọba Ọ̀yọ́ wà!
Èyí jẹ́ ọ̀ràn mọ́ ọ̀ràn èyí tí ìlú Nàìjíríà ndá.