Ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sanusi Ango Gyaza ẹnití ó ti f’ìgbà kan jẹ́ alága ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ní ìjọba ìbílẹ̀ Kankia ní ìlú agbésùnmọ̀mí Nàíjíríà, tí ó sì tún jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún gómìnà Ìpínlẹ̀ Katsina wọn lọ́hun, ni a gbọ́ pé àwọn agbésùnmọ̀mí ṣe ìkọlù sí ilé rẹ̀ tí wọ́n sì ṣ’ekú pa ọkùnrin ọ̀hún àti ìyàwó rẹ̀ kan nígbà tí wọ́n sì tún gbé ìyàwó rẹ̀ míràn lọ.
Ṣèbí láìpẹ́ yìí náà ni a tún gbọ́ pé, ó lé ní ogún akẹ́kọ̀ọ́ onímọ̀ ìṣègùn tí wọ́n jí gbé ní ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá yí ní ìpínlẹ̀ Benue ìlú Nàìjíríà ọ̀ún bákannáà, nígbà tí wọ́n ń rin ìrìn àjò lọ sí ìlú míràn ní Nàìjíríà, Enugu, fún àpéjọpọ̀ ọlọ́dọọdún kan gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ onímọ̀ ìṣègùn.
Àwọn ajínigbé ọ̀hún ni a gbọ́ pé wọ́n ti ń béèrè fún àádọ́ta mílíọ̀nù owó ìlú wọn báyìí fún ìtúsílẹ̀ wọn.
Kò sí ohun tí ó kàn wá nípa ọ̀rọ̀ ìlú agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà tí kìí bá ṣe jíjẹgàba tí wọ́n jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa, ṣùgbọ́n tí Olódùmarè máa dojú tì wọ́n láìpẹ́ àti láìjìnnà, nítorí Olódùmarè ló ń bá wa rin ìrìn-àjò yí, ó sì ti fi gbogbo ẹ̀yin gómìnà, ẹ̀yin ọba alátẹnujẹ àti ẹ̀yin àgbà ìyà ilẹ̀ Yorùbá lé wa lọ́wọ́.
Ṣèbí láti dẹ́kun irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi bí eléyìí wà lára ànfààní tí a máa jẹ, lérèdí pípadà tí a ti padà sí orísun wa, èyí tí màmá wa, Ìyá-Ààfin Modupẹọla Onitiri-Abiọla, ṣe dìde láti gba ìran Yorùbá lọ́wọ́ ìdààmú, ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kan ṣe orí kunkun tí ẹ ń gba àbọ̀dè ti ìran yín nítorí ìwà ìmọt’ara-ẹni-nìkan tiyín, àti nítorí ipò tí Olódùmarè kò yàn yín sí, ṣùgbọ́n tí ẹ gbé ara yín sí bẹ̀ láti leè máa gbógun ti àwa ọmọ Yorùbá, pàápàá ẹ̀yin àgbà òfò tí ẹ pe ara yín lọ́ba ní ilẹ̀ Yorùbá. Olódùmarè ti pa gbogbo yín run, ẹ ò tún gbérí mọ́ ní ìlẹ̀ Yorùbá.
Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ń sọ pé òmìnira Yorùbá kò ní ṣe ojú yín, ẹ̀yìn yín lo máa ṣe, Orílẹ̀-Èdè Yorùbá ti dá dúró o, gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè aṣèjọba-ara-ẹni.
Ẹlẹ́dàá gbogbo àwọn ọmọ Yorùbá tó dẹ̀ ti kú, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Kejìlá oṣù Igbe ẹgbàáọdúnólémẹ́rìnlélógún ti a ti ṣe ìbúra-wọlé fún Olórí-Ìjọba-Adelé wá, kò ní jẹ́ kí gbogbo yín ó ní ìsinmi. Ayé tí bínú sí yín, ọ̀run bínú sí yín, àwọn alálẹ̀ Yorùbá pàápàá bínú sí gbogbo yín.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwa Indigenous Yorùbá People(IYP) ti Democratic Republic of the Yorùbá (D.R.Y), ibi tí a ń lọ ni kí a kọjú sí, nítorí pé kò sí àní-àní nínú ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yí rárá.
Orílẹ̀ Èdè Yorùbá ti dúró. Ní kété tí àwọn olè tí ó ń jẹ gàba lórí ilẹ̀ wa wọ̀nyí bá ti kúrò, tí àwọn adelé wa sì ti wọlé sí oríkò ilé-iṣẹ́ ìjọba wa, ní ìpínlẹ̀ wa kọ̀ọ̀kan, ìrọ̀rùn ti dé fún wa nìyẹn, nítorí pé ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, àlàkalẹ̀ ètò ààbò tí ó péye ti wà, tí kò sì ní sí àyè fún agbésùnmọ̀mí kankan ní orílẹ̀-èdè wa.