Ọmọ ìlú Agbésùnmọ̀mí Nàìjíríà kan ni a rí fídíò rẹ̀ o, tí ó nbéèrè lọ́wọ́ ìjọba wọn pé kí ó wá ṣe àlàyé, ohun tí kò yé àwọn: tórí ìjọba sọ pé ilé-iṣẹ́ ìfọ’po tí ó wà ní ìlú Warri kò ṣiṣẹ́!
Ṣùgbọ́n, ọkùnrin tó sọ̀rọ̀ náa sọ pé àwọn ṣe àkíyèsí pé t’ó bá ti di bíi aago-méjìlá òru, àwọn ọkọ̀ agbé’po máa nlọ sí ilé-iṣẹ́ ìfọ’po náà; tí ó bá sì ti wá di bí aago méjì-sí-mẹ́ta ààjìn, àwọn ọkọ̀ náà á wá jáde kúrò ní’bẹ̀!
Ó ní òun ò sọ pé ohunkóhun nṣẹlẹ̀, ṣe ni òun kàn fẹ́ kí ìjọba ó ṣe àlàyé fún àwọn o! – ilé-iṣẹ́ ìfọ’po tẹ́ẹ ní kò ṣiṣẹ́, kíni àwọn ọkọ̀ elépo lọ nṣe níbẹ̀ lójoojúmọ́, tí wọ́n á wọlé l’aárin òru ní bíi aago méjìlá, tí wọ́n sì njáde kúrò níbẹ̀ tó bá ti di aago méjì sí mẹ́ta ààjìn? Ó ní ìbéèrè l’òun béèrè o!
Àwa náa ní ká sọọ́ ni o! pé ohun tí a gbọ́ tí ọmọ ìlú akótilétà nàìjíríà kan sọ nìyẹn o! Àwa ọmọ Yorùbá ò ńkúkú ṣe ara apaná ògo nàìjíríà mọ́, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá (Democratic Republic of the Yoruba, D.R.Y) ni wá; ilẹ̀ wa ò sí l’ara Nàìjíríà mọ́, ṣíbẹ̀ nàìjíríà nhùwà ọ̀daràn, wọn nfi ipá jẹgàba lórí ilẹ̀ wa, bíi pé wọn ò mọ̀ pé D.R.Y ti kúrò lára wọn láti ogúnjọ́ oṣù bélú ẹgbàá ọdún ó lé méjìlélógún, a sì ti bẹ̀rẹ̀ ìjọba wa láti ọjọ́ kéjìlá oṣù ìgbe, ẹgbàá-ọdún ó lé mẹ́rin-lé-l’ogún yí; jíjẹgàba tí wọn bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí a tí kúrò nínú nàìjíríà, òun ni ìròyìn náà ṣe jẹ́ èyí tí a f’ẹnu kan: apanilẹ́kún nàìjíríà, jáde kúrò lórí ilẹ̀ D.R.Y! Gbé ìwà agbésùmọ̀mí rẹ kúrò lórí ilẹ̀ wa!