• ỌLỌ́RUN ỌBA, TÓ NI AYÉ, TÓ DÁ OHUN GBOGBO, TÍ Ó DÁ ILẸ̀ YORÙBÁ, TÍ Ó ṢE WÁ NÍ ỌMỌ YORÙBÁ, TÓ FÚN WA NÍ Ẹ̀JẸ̀ YORÙBÁ, TÓ NÍ KÍ Á MÁA JẸ́ ORÚKỌ YORÙBÁ, ỌBA T’Ó DÁ’WA WÁYÉ, TÓ MỌ WÁ, TÓO NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ GAN-AN GAN L’O FẸ́ JẸ́ K’Á WÀ; ÌWỌ ỌBA TÓ DÁ AKỌ, TÓ DÁ ABO, JỌ̀WỌ́, DÌDE, KÍ Ó GBA ORÍKÒ-ILÉ-IṢẸ́-ÌJỌBA WA FÚN WA! ṢE É NÍ KÍÁKÍÁ, OLÓDÙMARÈ, KÍ Ó MÁṢE PẸ́. JỌ̀WỌ́, OLÓDÙMARÈ, GBÉ ÀWỌN ÌJỌBA-ADELÉ WA, TÍ WỌ́N JẸ́ AṢOJÚ-ÌJỌBA WA, TORÍ ÀWA ỌMỌ ÌBÍLẸ̀ YORÙBÁ NI ÌJỌBA, GBÉ WỌN WỌ INÚ ORÍKÒ-ILÉ-IṢẸ́ ÌJỌBA WA, KÍ WỌ́N LÈ BẸ̀RẸ̀ GBOGBO ÈTÒ TÍ O GBÉ LÉ MÀMÁ WA, MODÚPẸ́ ONÍTIRÍ-ABÍỌ́LÁ LỌ́WỌ́, FÚN ÌRAN YORÙBÁ, KÍ ÈTÒ NÁÀ Ó LE BẸ̀RẸ̀ NÍ KÍÁKÍÁ.

  • GBOGBO NKAN T’Ó BÁ MÁA GBÀ; TÍ ÌJÌ BÁ MÁA JÀ, KÓ JÀ; TÍ AFẸ́FẸ́ BÁ MÁA FẸ́, KÓ FẸ́, KÍ O BÁ WA GBÉ ÌJỌBA-ADELÉ WA WỌ ORÍKÒ ILÉ-IṢẸ́ ÌJỌBA WA, KÓ MÁṢE PẸ́ MỌ́, KÍ WỌ́N LE MÚ ÌDÍ ÀLÀKALẸ̀ TÍ O GBÉ LÉ MÀMÁ WA LỌ́WỌ́, MU’LẸ̀, NÍ GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ WA MÉJÈÈJE.

  • A BÁ Ọ DÁ MÁJẸ̀MÚ, LÓNI, OLÓDÙMARÈ, PÉ GBOGBO ÀLÀKALẸ̀ TÍ O GBÉ FÚN ỌMỌ YORÙBÁ NI A MÁA DÚRÓ LÉ LÓRÍ TÍTÍ LÁÍLÁÍ. A Ò NÍ YẸSẸ̀ KÚRÒ NÍBẸ̀, ÒUN NI ÌRAN YORÙBÁ YÍÒ LÒ TÍTÍ LÁÍ, FÚN AYÉRAYÉ. A Ò NÍ LO OHUN MÍRÀN TÍ Ó YÀTỌ̀ SÍ ÀLÀKALẸ̀ NÁÀ. ORÍ ÀLÀKALẸ̀ YÍ NI A MÁA GBÉ ÌJỌBA ILẸ̀ YORÙBÁ LÉ, TÍTÍ LÁÍ ! A Ò NÍÍ YẸ ẸSẸ̀ !

  • TÍ A BÁ WÁ RÍ ẸNIKẸ́NI, NÍBIKÍBI, TÍ Ó BÁ SỌ PÉ ÒUN FẸ́ LỌ MÚ ÒMÍRÀN WÁ, KÍ ẸNI NÁÀ KÍ Ó PARUN, TỌMỌTỌMỌ.

  • DÌDE, OLÓDÙMARÈ, KÍ Ó RAN ÌRAN YORÙBÁ LỌ́WỌ́, BÍ A BÁ TI NLO ÀLÀKALẸ̀ NÁÀ, KÍ EKU Ó MÁA DÚN BÍ EKU; KÍ ẸYẸ Ó MÁA KÉ BÍ ẸYẸ; KÍ ỌMỌ-ÈNÌYÀN Ó MÁA F’ỌHÙN BÍ ỌMỌ-ÈNÌYÀN; KÍ Ó MÁA JẸ́ FÚN WA ! KÍ Á RI ṢE, KÍ Ọ̀NÀ MÁA LÀ ! ÌṢERERE KÍ Ó MÁA ṢẸLẸ̀ NÍ’LẸ̀ YORÙBÁ; RERE-RERE NÍ KÍ OJÚ WA MÁA RÍ; KÍ OJÚ WA MÁṢE RÍ IBI MỌ́ NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ. KÍ GBOGBO ADELÉ WA Ó WỌ ORÍKÒ ILÉ-IṢẸ́ NÍ GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ WA MÉJÈÈJE NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ, LÁTI BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ NÍBẸ̀.

  • GBOGBO ÀWỌN Ọ̀TÁ, Ọ̀TÁ INÚ-ILÉ, Ọ̀TÁ ÒDE, TÍ WỌ́N NÍ ÀWỌN FẸ́ GBÀBỌ̀DÈ, TÀBÍ WỌ́N FẸ́ MÚ ÀLÀKALẸ̀ MÍRÀN WÁ, TÀBÍ WỌ́N FẸ́ WA ỌMỌ YORÙBÁ LỌ S’OKO ẸRÚ, KÍ WỌ́N PARUN, KÍ WỌ́N ṢÈGBÉ, TỌMỌ-TỌMỌ, TI’DÍLÉ-TI’DÍLÉ; PA WỌ́N RUN.

  • ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ, TÍ Ó JÓKO SÍ ÀYÈ GBOGBO ÀWỌN ADELÉ WA, NÍ GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ WA, OLÓDÙMARÈ, ṢÍ WỌN NÍDI, PA WỌ́N RẸ́ KÚRÒ LÓRÍ ILẸ̀ ALÀÀYÈ.

  • GBOGBO OHUN TÍ Ó JẸ́ TI ỌMỌ YORÙBÁ, TÍTÍ KAN GBOGBO IBODÈ WA, OLÓDÙMARÈ, GBA GBOGBO Ẹ̀ FÚN ÌJỌBA ADELÉ WA TÍ WỌ́N BÁ TI WỌ’NÚ ORÍKÒ-ILÉ-IṢẸ́ ÌJỌBA WA GBOGBO. ṢE É NÍ ÌRỌ̀RÙN FÚN ÀWỌN ÌJỌBA-ADELÉ WA, OLÓDÙMARÈ. GBA GBOGBO RẸ̀ PADÀ FÚN ÌRAN YORÙBÁ. A MỌ̀ PÉ ÌWỌ OLÓDÙMARÈ LO FI ÀLÀKALẸ̀ YÍ RÁN MÀMÁ WA, MODÚPẸ́ ONÍTIRÍ-ABÍỌ́LÁ SÍ ÀWA ỌMỌ YORÙBÁ; NÍTORÍ ÈYÍ, ORÍ ÀLÀKALẸ̀ NÁÀ NI A MÁA TI ṢE ÌJỌBA WA. ORÍ ILẸ̀ YORÙBÁ NI ÀLÀKALÈ NÁÀ MÁA DÚRÓ LÉ; ÌBẸ̀ NÁÀ NI ÌJỌBA WA MÁA DÚRÓ LÉ.

  • ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ, FÚN ÀWỌN ÌJỌBA WA NÍ AGBÁRA KÍ WỌ́N LE ṢÉ PẸ̀LÚ ÌRỌ̀RÙN, KÍ WỌ́N MÁ SÌ YẸSẸ̀, KÍ WỌ́N MÁṢE YẸ MÁJẸ̀MÚ ÀLÀKALẸ̀ YÍ, TÍ A BÁ Ọ DÁ, LÁÍLÁÍ.

  • OLÓDÙMARÈ, ÌWỌ LO KỌ ÀLÀKALẸ̀ YÍ, TÍ O SÌ DÌÍDÌ GBE FÚN ỌMỌ YORÙBÁ. KÒ SÍ Ẹ̀DÁ TÍ Ó LE GBÀÁ LỌ́WỌ́ ỌMỌ YORÙBÁ LÁÍ. ÈDÁK’ẸDÁ TÓ BÁ SỌ PÉ ÀWỌN FẸ́ GBA ÀLÀKALẸ̀ YÍ, KÍ WỌ́N PARUN, KÍ WỌ́N ṢÈGBÉ. A À TÚN ṢE ẸRÚ MỌ́. AJÈJÌ KÒ GBÚDỌ̀ RÁYÈ LÁARÍN WA MỌ́. GBOGBO ÀWỌN Ọ̀TÁ TÍ WỌ́N NDÈNÀ, TÍ WỌ́N NÍ KÒ NÍ ṢE É ṢE, TÍ WỌ́N NÍ ÀWỌN FẸ́ WO BÍ ADELÉ ṢE MÁA WỌLÉ, OLÓDÙMARÈ, JÁ OKÙN Ẹ̀MÍ WỌN, FÀ WỌ́N TU, PẸ̀LÚ GBÒNGBÒ. ỌBA TÍ Ó FI IṢẸ́ RÁN MOA SÍ ÌRAN YORÙBÁ, ṢE ÈYÍ