Kò rú’jú mọ́ o! Àgbáyé ti mọ̀ pé, Ọ̀tọ̀ ni Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, ọ̀tọ̀ ni ìlú Nàìjíríà! Méjèèjì kò papọ̀ rárá!

Ṣebí Nàijíríà ni ó ntan ara wọn jẹ pé ìpínlẹ̀ mẹ́rin-dín-l’ogójì ni àwọn ní; bẹ́ẹ̀ kẹ̀ dẹ̀ ré, ọ̀ràn ni wọ́n ndá lábẹ́ òfin àgbáyé nípá kíka Orílẹ̀-Èdè Olóìmìnira Tiwantiwa ti Yorùbá mọ́ ara ilẹ̀ Nàìjíríà, èyí tí wọ́n fi wá nsọ pé ìpínlẹ̀ mẹ́rin-dín-l’ogójì ni àwọn ní!

Wèrè wọn sọ pé ìpínlẹ̀ mẹ́rin-dín-l’ogójì ni àwọn ní, bẹ́ẹ̀ kẹ̀ dẹ̀ ré ìjòyè méjì-dín’l’aádọ́ta ní wọ́n ní!

Ìlú Amẹ́ríkà pàápàá, tí ayé mọ̀ sí ìlú tí ó pẹ̀lú àwọn t’ó lówó jùlọ, tí wọ́n sì ní àádọ́ta ìpínlẹ̀, ìjòyè mẹ́ẹd’ogún péré ni wọ́n ní!

❗PÀJÁWÌRÌ FÚN ÀÀBÒ❗KÁÀKIRI GBOGBO ÌPÍNLẸ̀ YORÙBÁ TÍTÍ DÉ OLD Ọ̀YỌ́ EMPIRE, Ẹ MÁA YA FỌ́TÒ FÚLÀNÍ, OLỌ́PA, OLÓṢÈLÚ, SÓJÀ, TÍ Ẹ BÁ FURA SÍ ÌRÌN ÀTI ÌṢESÍ WỌN NÍ AGBÈGBÈ YÍN. KÍ Ẹ FI ṢỌWỌ́ SÍ BÀBÁ ÌJÌNLẸ̀ +905367341665 (WHATSAPP). (ÌKÉDE… Pín Sórí Àgbàgbé X (Twitter)

Ṣùgbọ́n àwọn akótilétà ìlú Nàìjíríà kàn ṣáà máa nfi owó ṣòfò ni! Ṣé kò kúkú kàn wá, ṣùgbọ́n ó dẹ̀ tún kàn wá; ọ̀nà tí ó fi kàn wá ni ti àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Ọmọ Yorùbá, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ ìlú ìbọ̀dè, ìlú ìnira, ìlú jẹgúdújẹrá, ìlú àbòsí, ìlú ibi, Nàìjíríà, ní wọ́n nfẹ́; bóyá wọ́n ṣì lè gbọ́’ràn, ni a ṣe nsọ èyí, kí wọ́n kúrò l’ẹhìn àdàmọ̀dì ìlú tí kò l’ọjọ́ ọ̀la!

Nínú àwọn ìjòyè méjì-dín-l’ọgọ́ta tí àpà ìlú Nàìjíríà yàn sípò wọ̀nyí, mọ́kàn-lé-l’ogójì nínú wọn ni ẹ̀sùn olè jíjà wà lóri wọn o, ṣùgbọ́n tí olóríburúkú Nàìjíríà pàpà jẹ́ kí wọ́n wà lórí ìpò!

Àfi bíi pé ẹgbẹ́ ni àwọn olóṣèlú Nàìjíríà ọ̀ún nṣe ni – ràn-mí-lọ́wọ́ kí nràn-ẹ́-lọ́wọ́ – nítorí a ṣàkíyèsí pé, nínú àwọn ìjòyè ìjọba-àpapọ̀ Nàìjíríà wọ̀nyí, àwọn mẹ́san ni wọ́n ti fi ìgbà kan jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ rí, ṣùgbọ́n tí ìbò kò gbé wọn wọlé ní ẹ̀ẹ̀kéjì, tí wọ́n ti wá di ìjòyè ìjọba bàyi; bẹ́ẹ̀ kẹ̀ dẹ̀ ré, àwọn mọ́kànlá ni gómìnà Nàìjíríà tí ó fìdí rẹmi nínú ète wọn láti di gómìnà lẹ́ẹ̀kejì – èyí tí ó túmọ̀ sí pé mẹ́san nínú gómìnà wọn mọ́kànláá tó fìdí rẹ’mi ni wọ́n ti sọ di ìjòyè ìjọba àpapọ̀ wọn!

Ṣé wọ́n nfi ipò ìjòyè ìjọba-àpapọ̀ wọn ṣe “gbà-má-bínú” fún àwọn tó bá ti kùnà láti di gómìnà lẹ́ẹ̀keji ni? Ó dáa, ó ṣìṣẹ̀ wá nyé wa báyi!

The democratic republic of the yoruba is a new sovereign nation from april 12th 2024

Ìkan lára àwọn gómìnà àná wọ̀nyí, tí wọ́n kò fi sí ipò ìjoyè, wọ́n fi ṣe alága ẹgbẹ́ òṣèlú tí ó wà lórí àlééfà lọ́wọ́lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ dẹ̀ nìí, ọkùnrin ọ̀ún ni fọ́tò rẹ̀ wa nígboro ayé ní’bí tí ó ti ngba rìbá! Lóotọ́ àti ní òdodo, Nàìjíríà jẹ́ ìlú àwọn olè, fún àwọn olè, nípasẹ̀ kí olè ó fi’ni sí’pò.

Gẹ́gẹ́bí a ṣe máa nsọ, ṣé èyí kò kúkú kàn wá bíì bá nṣe ti àwọn dàdàndatọ́ kan tí wọ́n pe’ra wọn ní ọmọ Yorùbá, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ pe, orí “Nàìjíríà kan” – ọ̀rọ̀ aláìnírònú – ni wọ́n dúró lé! Ijọ́ wo lẹ fẹ́ gbọ́n o!

Ẹ jẹ́ mọ̀ pé ọkọ̀ ìrìnnà mẹ́rin-mẹ́rin ni ìjọba Nàìjíríà rà fún ẹnikọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè méjì-dín-l’ọgọ́ta wọ̀nyí?! Èyí jẹ́ igba ọkọ̀ ó dín mẹ́jọ! – látàri pé a fi’ni j’oyè l’abẹ́ ìjọba àpapọ̀ amúnisìn wọn – bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará ìlú wọ̀n kò r’ayé wá, ìyà njẹ wọ́n, wọn ò lè rán ọmọ ní’lé-ìwé t’ó dára, kò sí títì t’ó dára láti gbà, ọ̀wọ́n-gogo ni oun gbógbó, wọn ò jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ wọn k’ó gbé’rí; ẹni t’ó bá fẹ́ dá ilé-iṣẹ́ ṣíṣe sí’lẹ̀, àfi kí wọ́n kó oríṣiríṣi ìdènà s’ọnà fún, ṣùgbọ́n wọ́n lè ra ọkọ̀ bọ̀gìnnì igba-ó-dín-mẹ́jọ fún olóṣèlú tí kò pé àádọta! Irú ìlú wèrè báyi ni ẹ̀yin kan tí ẹ pe’ra yín ní Yorùbá sọ pé ẹ máa takú tì! Hábà! Òpònú gidi niyín o! Ẹ ò ní ọpọlọ rárá, aláìní’fẹ́ ará-ìlú dẹ̀ ni ‘yín bákannáà; dájúdájú ẹ ò lè rí ire nígbẹ̀hìn ayé yín!

Àwọn ìjòyè méjì-dín-l’ọgọ́ta ìlú àwọn ayíradà yí, ẹ jẹ́ mọ̀ pé ọmọ-ọ̀dọ̀ tàbí òṣìṣẹ́ mẹ́ẹ̀dógún-mẹ́ẹ̀dógún ni ìlú àpà t’ó njẹ́ Nàìjíríà yí nsan owó rẹ̀ fún ẹnikọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọ̀jẹ̀lú ìjòyè wọ̀nyí – èyí tí ó túmọ̀ sí okòó-lé-ní-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rín ọmọ-ọ̀dọ̀ tàbí òṣìṣẹ́ tí àwọn ìjòyè tí kò tó àádọ́ta yí lè gbà, tí ìjọba wọn yíò sì máa san’wó wọn sọ́wọ́ àwọn ìjòyè ọ̀ún! Ṣé wọ́n fi òfò ṣíṣe ṣ’epè fún Nàìjíríà ọ̀ún ni?

Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ pe’ra yín ní Yorùbá, tí ó sì jẹ́ pé Nàìjíríà ìlú òfò yẹn ni ó wù yín, tí ẹ wá ntako Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá, lóotọ́ ìlú tí ó bá wù yín ni ẹ lè f’ara mọ́, ṣùgbọ́n ìbá dára kí ẹ f’ara mọ́ Nàìjíríà yín láì ṣe àtakò Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Tiwantiwa ti Yorùbá; àtakò D.R.Y tí ẹ nṣe yẹn, ìyẹn ni inú mbí wa sí yín sí, ẹ dẹ̀ máa ṣ’òfò t’ọmọ t’ọmọ ni.

Bí ẹ ṣe ní ìfẹ́ sí kí ara kí ó má tu ọmọ Yorùbá, ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ pé irú ìyà tí ó njẹ wọ́n ní Nàìjíríà ni kí ó máa jẹ ìran ọmọ aládé náà, bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè á jẹ́ kí ìnira àti ìyà àti ọ̀wọ́n-gógó ohun rere gbogbo, kí ó bá ìdílé tí yín – èyíinì, àwọn àrọ́mọ-dọ́mọ tí ó ti ara yín jáde wá, títí dé òpin ayé.

Nígbàtí kò sí ààbò t’ó pé’ye fún ará-ìlú wọn ní Nàìjíríà ọ̀ún, nṣe ni ìjọba wọn fún ẹ̀nikọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè-ìjọba wọn wọ̀nyí ní ẹ̀ṣọ́-aláàbò márun-márun – háà! Ṣé àwọn nìkan l’ó njẹ́ ìlú Nàìjíríà, ìlú òfò yín ni? Èyí dẹ̀ ni ẹ̀yin kan tí ẹ pe’ra yín ní Yorùbá fẹ́ kí ìran ọmọ-aládé ó máa bá lọ?!

Ayé yín ò níí dáa; bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ohun tí ẹ bá dáwọ́ lé, láti òní lọ, máa máa polúkúrúmuṣu; ẹ́ẹ̀ ní rí bá ti ṣé, ẹ́ẹ̀ níí r’ọnà gbe gbà ní rere; gbogbo ohun tí ó ti ara yín jáde, ni ìyà máa jẹ kú!